Ilu Ado Awaye fẹẹ gbalejo Aarẹ Mohammad Buhari fayajọ ọdun odo Iyake - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 12 November 2021

Ilu Ado Awaye fẹẹ gbalejo Aarẹ Mohammad Buhari fayajọ ọdun odo Iyake



 Ọba, Ẹni- ọwọ, Olugbile Ademọla Fọlakẹmi, Makuledoye 11,Asọludẹrọ, Alado tiluu Ado Awaye, ti sọ pe gbogbo eto lo ti n lọ lọwọ fun gbigba aarẹ orileede yii, Mohammad Buhari, sibi ayẹyẹ ayajọ ọdun Iyake, eyi ti wọn yoo ṣe lọjọ kẹrin, oṣu to n bọ niluu naa.

O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ, o ni  imurasilẹ ti n lọ lọwọ bayii ati pe Gomina Ṣeyi Makinde, tipinlẹ Ọyọ, ni yoo ṣaaju awọn Gomina ẹgbẹ ẹ yooku wa. Bakan naa lawọn ọba Alade, to fi mọ Alaafin tiluu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi, kẹta naa yoo wa lori ijokoo.

O sọ pe odo ọhun ti wa tipẹ to si jẹ eyi to lagbara, ti ko siru  ẹ nilẹ Afrika, bo tilẹ jẹ awọn oyinbo ṣe ọkan latọwọda ni orileede Colorando, ṣugbọn eleyii yatọ gedegbe, nitori tawọn oyinbo gan an funra wọn maa n wa fi ibẹ ṣr irinajo igbafẹ.

Ọba Olugbile tun sọ pe ‘A ti maa n ṣe ọdun tipẹ niluu yii, ṣugbọn nnkan ta a maa n pe ni ọdun Oodua, lawọn baba wa maa n ṣe e, ṣugbọn nigba ta a de, ta a ri pe orukọ Iyake, yii ti di gbajugbaja kaakiri gbogbo agbaye, ni a ṣe ronu pe ohun to dara ni ki a maa pe lorukọ ti gbogbo aye mọ’’

O tun ṣalaye pe ‘’ Ohun to ṣẹlẹ ni pe odo yẹn, meji iru ẹ ni wọn sọ pe o wa ni gbogbo agbaye, ti ki i gbẹ.Ọkan wa ni Colorando, niluu awọn alawọ funfun, ikeji wa ni Ado-Awaye nibi. Amọ eyi to wa ni Colorando, atọwọṣe ni, awọn oyinbo lo gbe kalẹ fun ara wọn, ṣugbọn eleyii lawọn itan sọ pe o jẹ ojulowo, ti ki i ṣe arọọda ni gbogbo agbaye ti ki i gbẹ.

Eleyii to wa ni Colorando yii mu ọpọlọpọ owo wa fun orileede yẹn lawa naa fi wa ro pe bi aba ṣe ajọdun yii yoo ṣi awujọ wa niye pe ohun ti awa naa ni yii to le tun mu ọrọ aje wa gbooro soke ni ka nawo lori ileeṣẹ igbafẹ yii,iru ẹ akọkọ ni gbogbo agbaye’’.

 Nigba to n sọ bi odo Iyake naa ṣe waye, Kabiyesi sọ pe ‘’Bi awọn baba wa ṣe sọ fun wa, iya yẹn wọn ni ko bimọ, niluu to wa n gbe o jẹ ẹnikan to ko awọn ọmọ mọra, to maa n ṣalejo wọn. Ẹyin naa mọ nilẹ Yoruba, bo ti wu ki obinrin dara to, bi ko ba bimọ wahala ni, wọn fọmọ bu, iyẹn lo jẹ ko binu kuro ninu ilu yẹn tawọn ọmọ kekekee naa tẹle.

‘’Ni wọn lo ba lọ si oke yẹn, ninu ibinu o yi si odo yẹn, lawọn ọmọ yẹn ba pada lọ sile, o si jẹ ẹnikan to maa sunkun nitori airọmọbi ẹ,Lawọn ọmọ yẹn ba sọ pe iya to maa n ke yẹn, o ti ri ara ẹ sinu odo kan o.

Lawọn ọmọ yii ba mu wọn debẹ pe ibi ti Iya to maa n ke ri ara ẹ si niyii, iya to maa n ke lodi ìyáké, latigba naa gbogbo awọn to ba ti wa kigbe ba a lọna kan si omii-in, ti wọn fi ẹdun ọkan wọn wa sibẹ,, ọma ni wọn wa ni, ti wọn ba bẹ Ọlọrun atawọn alalẹ,Ọlọrun si n gbọ adura wọn’’.

No comments:

Post a Comment

Pages