Gbogbo eto lo ti fẹẹ to fun ayẹyẹ ifinijoye ti Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ fẹẹ fi Balogun Ira Gbagura, Oloye Nurudeen Ọlalẹyẹ, jẹ gẹgẹ bii Alawo Erin tilẹ Ẹgba.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, lọjọ Abamẹta, Satide, Ogunjọ, oṣu yii ni ayẹyẹ ifinijoye ọhun yoo waye ni afin Alake tilẹ Ẹgba, to wa ni Ake, niluu Abẹokuta.Nibẹ ni wọn yoo ti jawe oye le Alawo Erin ilẹ Ẹgba akọkọ.
Ohun ta a gbọ ni pe oye Alawo Erin yii ki i ṣe oye lasan laaarin ilu ati pe awọn akinkaju eeyan ni wọn maa fi jẹ oye ọhun. O si ti wa tipẹ amọ igba akọkọ ree ti wọn yoo jẹ iru ẹ nilẹ Ẹgba.
Iwadii fi ye wa pe awọn ipa ribiribi ti ọkunrin naa ti ko nilẹ Ẹgba ati bo tun ṣe jẹ akinkanju to si ni igboya lo jẹ ki wọn fi agba oṣelu yii je oye ọhun. Titi di akoko yii, Oloye tuntun yii ni alaga igbimọ awọn oniṣegun to yatọ si tawọn oloyinbo ti wọn wa labẹ ijọba ipinlẹ Ogun.
Bẹẹ ni wọn lo tun kopa to jọju laifi ti ẹsin ṣe niluu Abẹokuta ati ipinlẹ Ogun lapapọ.
No comments:
Post a Comment