Ọnarebu Remmy Hassan, to jẹ Oludamọran pataki fun Gominna ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, lori ọrọ ibanisọrọ ati iroyin, ti sọ pe lojumọ to mọ lonii, nibi ti ijọba to wa lode yii ti ba iṣẹ ọna de jẹ eyi to lapẹẹrẹ rere, bo tilẹ jẹ pe adiẹ n laagun, iyẹ ni ko jẹ.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n oniroyin wa sọrọ ni ọfiisi ẹ, o sọ pe ni gbogbo ijọba ibilẹ ogun to wa nipinlẹ ọhun, ijọba ibilẹ meji nikan lo jẹ pe awọn ko tii ṣiṣẹ debẹ amọ to jẹ pe lagbara Ọlọrun, awọn yoo ṣe nnkan to yẹ.
Lara awọn ọna to sọ pe awọn ti ṣiṣẹ de e ni ijọba ibilẹ Abẹokuta South ni awọn iṣẹ akanṣe tijọba yii jogun ba lọwọ ijọba ana, tawọn rii pe o jẹ awọn eeyan logun gan-an ni bi afara Kutọ, Adatan, ṣe lawọn tẹsiwaju nibi ti wọn ba a de, ti wọn si ti pari Kutọ to ṣe e gba iobi diẹ to ku ni lati ori afara de ile ijọba, eyi to ni wọn ki nii pẹ pari ẹ.
Bẹẹ lo tun sọ pe awọn tun ṣe ọna Kemta, Elite,, Somọrin si Gbọnagun, bẹẹ lawọn tun ti ṣe Fajol, Ni Ariwa Abẹokuta, ọna Lafẹnwa si Rounder, to sọ pe ko fẹẹ jẹ kawọn eeyan agbegbe ọhun gba pe ọmọ ipinlẹ naa ni wọn, nitori idojukọ ọna wọn to ba jẹ yii, tẹlẹ nnkan tawọn fẹẹ ṣe ni pe ijọba to ko gba sile ba a de ibi kan, awọn fẹẹ pari ẹ, ṣugbọn ọda owo to n da wọn, to si fẹẹ mi idojukọ wa.
O ni bawọn ṣe n ṣe ọna meji lọọ tẹlẹ ti ko si fẹẹ apẹẹrẹ pe wọn ko ṣe nnkan kan nibẹ nijọba ṣe roo pe ko yẹ ki awọn fi omugọ ṣe nnkan to wa nilẹ, bo tilẹ jẹ pe apa kan lawọn le pari, gbogbo awọn to n gbe nibẹ yoo ri ọna gba, eyi to ku ko pari ko ju kilomita kan lọ.
Bẹẹ lawọn ṣe ni Ifọ, Agbado, Ado- Odo, iyẹn gan ni akọkọ tijọba yii kọkọ ṣe nigba to gbakoso Awọn ọna kan wa to jẹ pe awọn ṣe e kawọn eeyan le maa ri gba tawọn tun ṣe kaakiri. O ni bawọn ṣe ṣe lawọn agbegbe kan ni Ijẹbu naa ni.
Remmy Hassan tun sọ pe ‘ Ootọ to wa nidii ọrọ naa ni pe ko to di pe Ọmọọbọ Dapọ Abiọdun gbajọba, aima mojuto awọn ọna yii bo ti tọ ati bo ti yẹ, ati ikọsilẹ lori awọn iṣẹ akanṣe tijọba ana ba ṣe, tijọba mii in to tẹsiwaju, ti jẹ ki ọpọ nnkan bajẹ gan-an’’, to fi wa dabi ẹni pe omi ti fẹẹ pọju ọka’’.
O wa ni eyi tijọba ba ṣe naa, ki a ma ṣe fi oju oloore gun igi, ki awọn araalu maa sọ, ki wọn si tun sọ ibi ta a ba ku diẹ kaato si. O ni ko yẹ ki a maa bu ẹnu atẹ lu ijọba pe, wọn ko tiẹ ṣe nnkan, bẹẹ lo ni ọrọ ọna ṣe ri.
Ọkunrin yii sọ pe ‘’Nnkan to jẹ kawọn koju ipenija lori ọna ni pe o jẹ iṣẹ akanṣe ti o ṣoro lati da ni, idi niyii to fi jẹ pe gbogbo ẹ ọrun ijọba lo wa. Nitori bi wọn ko ba ṣe e , o maa n yọ nilẹ,awọn eyi to ku niṣe ni ọna abayọ wa lọtun losi fawọn eeyan wa iyẹn lo ṣe jẹ ki jọba naa roo pe ọna wo lawọn le gba pe awọn oniṣẹ adani,lati ba wa dowopọ, awọn ọna to latunṣe yii, a le gbe fun wọn, ki wọn lọ maa ṣe o, ki wọn maa gbowo bode, iyẹn lo ṣe jẹ ki ẹ maa ri diẹdiẹ ninu awọn igbesẹ yẹn.’’
O ni amọ ṣa o, awọn ọna to wa nipinpẹ Ogun, ọpọ ẹ lo jẹ tijọba apapọ, eeyan ko si le deede bọ sori ẹ, ko gbe fawọn oniṣẹ adani, nitori ijọba apapo yoo beere pe igba wọn lawọn jọ ṣadehun, eyi lo sọ pe o maa n mu ifasẹyin ti ko yẹ kawọn ko ni, sibẹ o ni ireti wa pe ede yoo ye ara wọn lati jọ sun gbogbo awọn nnkan amayedẹrun siwaju fawọn araalu..
.
No comments:
Post a Comment