Apapọ awọn Hausa lorileede yii ṣabẹwo si ọfiisi ọlọkada ROMO tuntun l'Abẹokuta - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 16 November 2021

Apapọ awọn Hausa lorileede yii ṣabẹwo si ọfiisi ọlọkada ROMO tuntun l'Abẹokuta
Loni in, ọjọ Iṣẹgun, ni apapọ awọn Hausa, lorileede yii ṣabẹwo si ọfiisi ẹgbẹ awọn ọlọkada ROMO tuntun to wa lọna Ayetoro, niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun.

Nibi abẹwo ọhun ni alaga ẹgbẹ fẹgbẹ ọlọkada ROMO, nipinlẹ Ogun, Oloye Rasak Oluṣọla Ṣotayọ, tọpọ mọ si Ṣolebọ, ti gba wọn lalejo. Ninu ọrọ Alaaji Sokoto Samaja Gabari, to ṣaaju awọn Hausa naa lo ti kọkọ dupẹ lọwọ Ọlọrun, to si bawọn ẹgbẹ ọhun yọ fun ti ọfiisi tuntun yii.

O ṣapejuwe Ṣolebọ, alaga awọn ọlọkada naa gẹgẹ bi akanda eeyan lawujọ, ti ko fi ti ẹya ṣe iṣẹ ẹ, to si tun ko gbogbo awọn Hausa naa mọra bi ọmọọya.

O sọ pe ọpọ awọn eeyan oun ti wọn jẹ ọlọkada ni wọn kan sara si ọkunrin naa, o wa gba niyanju lati ma ṣe boju wẹyin ninu gbogbo nnkan to ba n ṣe, bẹẹ lo tun ṣeleri pe gbogbo awọn Hausa lawọn fun un ni atilẹyin gidi.

Ṣokoto ni aṣeyọri nla ni ọfiisi tuntun naa jẹ fẹgbẹ ROMO,nipinlẹ Ogun ati lorileede yii lapapọ. O wa gbadura fun ọpọ aṣeyọri. Ninu ọrọ Ṣolebọ, o dupẹ lọwọ awọn Hausa naa fun ẹmi ifẹ ti wọn fi han, o wa ṣeleri pe gbogbo ọna loun yoo maa sa ki ifẹ ati alaafia le wa laarin gbogbo wọn.

No comments:

Post a Comment

Pages