Fun itẹsiwaju imuraslẹ ipolongo lati ṣatilẹyin fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, lati di aarẹ orileede yii nini ibo to n bọ lọdun 2023. Ẹgbẹ erongba fun Aṣiwaju nilẹ Yoruba, iyẹn South West Agenda for Asiwaju 2023, SWAGA’23, ti bẹrẹ ti tan imọlẹ erongba ọhun sawọn igberiko nipinlẹ Ọṣun.
Ẹgbẹ ọhun ti wọn ti kọkọ ṣefilọlẹ kaakiri ilẹ Yoruba nibi ti wọn ti ba awọn ọba alaye, awọn agba oṣelu ti wọn n pe fun atilẹyin pe ki aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC, naa ko jade dupo aarẹ lọdun 2023.
Bo tilẹ jẹ pe Sẹnatọ Dayọ Adeyẹye, alaga apapọ fẹgbẹ naa ti sọ nigba kan pe pẹlu atilẹyin awọn to wa nilẹ Yoruba, o ti daniloju pe ibo miliọnu mejila, ti wa nilẹ fun Tinubu. Wọn oluwoye wa gba igbesẹ lati tan ihinrere ẹgbẹ naa sawọn igberiko, gẹgẹ bi ọna to dara.
Idi niyii tawọn SWAGA’23, tipinlẹ Ọṣun,fi ṣefilọlẹ ẹgbẹ naa lawọn igberiko, eyi ti Ọnarebu Ayọ Omidiran, to jẹ alaga wọn, gbalejo ẹ pẹlu ifọwọsowọpọ awọn eeyan ẹ bii Ọnarebu Tilewa Ṣijuade, Ọnarebu Ọlabọọpo Olubukọla, Ọnarebu Gafar Amere ati awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin pẹlu Ọnarebu Bayọ Olodo, to jẹ aṣoju-sofin, to n ṣoju agbegbe Irewole, niluu Abuja.
Lara awọn ibi ti wọn ti gba wọn lalejo ni ijọba ibilẹ Ayedaade, ijọba ibilẹ Isokan ati ijọba ibilẹ Irewole. Nigba to n ki wọn kaabọ, Ọnarebu Ayọ Omidiran, rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ to wa nijọba ibilẹ, ki wọn ri ara wọn gẹgẹ bi aṣoju fun Tinubu, lawọn wọọdu ti wọn ti wa, ki wọn si bẹrẹ si ni polongo fawọn eeyan kaakiri.
Nigba to ṣefilọlẹ ẹgbẹ naa lawọn ijọba ibilẹ, Sẹnetọ Dayọ Adeyẹye, rọ wọn lati ri pe erongba ki Aṣiwaju Tinubu, di aarẹ di imuṣẹ lọdun 2023.
Lara awọn to wa nibẹ lọjọ naa ni Sẹnetọ Adesọji Akanbi, to jẹ igbakeji alaga lapapọ, Ọnarebu Ifedayọ Abegunde, alaga SWAGA’23, ni Ondo, Ọnarebu Oye Ojo, Ọnarebu Bọsun Ọladele akọwe ẹgbẹ wọn, Ọnarebu Ọlọruntọba Oke, Akapo, Ọnarebu Julius Oloro,Ọnarebu Taiwo Akintọla,Ọnarebu Gbenga Ojoawo,Ọnarebu Ọlamide Oni atiỌnarebu Niyi Ọlabiyi.
Bẹẹ la gbọ pe ifilọlẹ lawọn ijọba ibilẹ lawọn ipinlẹ yooku yoo tun tẹsiwaju.
No comments:
Post a Comment