Ilu Abẹokuta min titi lọjọ ti Nurudeen Ọlalẹyẹ gba ọpa aṣẹ Alawo Erin ilẹ Ẹgba akọkọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 20 November 2021

Ilu Abẹokuta min titi lọjọ ti Nurudeen Ọlalẹyẹ gba ọpa aṣẹ Alawo Erin ilẹ Ẹgba akọkọ
Ṣe ni ilu Abẹokuta min titi lọjọ Abamẹta, Satide, nigba ti Alake tilẹ Ẹgba, fi Balogun Ira, Gbagura jẹ oye Alawo Erin tilẹ Ẹgba akọkọ, eyi ti wọn fi sami si ayẹyẹ ọdun kẹrindinlogun, ti Ọba naa gori itẹ awọn baba ẹ.

Nibi ayẹyẹ ọhun lawọn ọba alaye, awọn agba oloṣelu atawọn eeyan jakanjakan lawujọ ti pejupesẹ lati yẹ ọkunrin naa si, koda awọn ọdẹ naa ko gbẹyin, ti wọn si dabira lọjọ naa


Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn lawọn ipa akikanju ti ọkunrin naa ti ko sẹyin ati bo tun ṣe jẹ ẹlẹyinju aanu ni wọn ṣe foye ọhun daa lọla. Lẹyin to gbe ọpa aṣẹ ati iwe ẹri le e lọwọ tan, Alake tilẹ Ẹgba, gba Oloye tuntun naa nimọran lati lo oye tuntun naa lati le jẹ kawọn eeyan maa fi tiẹ ṣe awokọṣe rere.

Ko si fọwọsowọpọ pẹlu awọn oloye to ti ba niwaju fun idagbasoke ilẹ Ẹgba, nigba to n sọrọ, Alawo Erin tuntun nilẹ Ẹgba, dupẹ pupọ lọwọ Alake atawọn eeyan ilẹ Ẹgba lapapọ fun bi wọn ṣe ro ohun rere kan oun pẹlu ileri pe oun ko nii ja ilẹ Ẹgba ni tan an mọ.Nigba to n bawọn oniroyin sọrọ, o sọ pe gẹgẹ bi igbagbọ Yoruba, awọ erin jẹ eyi to lagbara bẹẹ naa ni erin naa funra ẹ, ti wọn ko si ṣe e fọwọ rọ sẹyin.

O ni bi awọ erin ṣe ṣe pataki ni awọn eeyan oun nilẹ Ẹgba naa ṣẹ mọ pe oun pataki, ti wọn fi fun oun loye ọhun. O ni ki i ṣe igba akọkọ ree toun fi kopa ninu idagbasoke ilẹ naa toun yoo si tubọ maa kopa.
O ṣalaye pe loootọ oye ọhun ni i ṣe pẹlu awọn ọlọdẹ fun aabo ilu, eyi to tumọ si pe oun yoo maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọdẹ. Lara awọn to wa nibẹ ni Ọba Agura, Olu itori, Olu Owode atawọn ọba alaye mii inn. Bẹẹ naa ni alaga fẹgbẹ oṣelu APC, Oloye Yẹmi Sanusi, Ọnarebu Tunji Ẹgbẹtokun,Alaaji Gboyega Nasir Isiaka, Bukọla Ọlọpade naa wa nibẹ lọjọ naa.


No comments:

Post a Comment

Pages