Wọn ni wọn fẹẹ forukọ Gomina Ọṣun da wahala ọrọ ọlọba de silẹ ni Ikirun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 21 November 2021

Wọn ni wọn fẹẹ forukọ Gomina Ọṣun da wahala ọrọ ọlọba de silẹ ni Ikirun.




   Titi di akoko ta a n kọ iroyin yii lọwọ ni nnkan ko fi rọrun niluu Ikirun, nipinlẹ Ọṣun nitori wahala lati yan ori ade tuntun, bẹẹ lawọn araalu si ti bẹrẹ si nii fehonu wọn han.

Ohun to n da awuyewuye eyi ti wọn lo n lọ lọwọ ni wọn pe ni iditẹ lati gbajọba laafin, ṣe ni wọn lawọn kan ya wọ afin naa, ti wọn si ko awọn afọbajẹ ni papa mọra, ti  lo orukọ Gomina ipinlẹ naa lati pọn ọn ni dandan fun wọn, orukọ ẹni ti wọn fẹẹ ko gori ipo ọhun, to si lodi si ifẹ awọn araalu.

Iwadii fi ye wa pe idile Gbolẹru lo yẹ ko fa ọmọ oye silẹ gẹgẹ bi ọba ilu, ṣugbọn wọn ko le fa ọmọ oye kalẹ, idi niyi ti wọn fi ni ile-ẹjọ ṣe pa a ni aṣẹ pe ki idile mii in ti wọn jọ n jẹ ọba, ko fa eeyan silẹ.

Wọn ni iyalẹnu lo jẹ fawọn pe oloṣelu kan,  ti wọn loun naa ni ọmọ oye toun naa fẹẹ lo funra ẹ, to nigbagbọ pe oun sunmọ Gomina Oyetọla ko awọn afọbajẹ naa lọ si ootẹli, nireti pe Gomina fẹẹ ri wọn.

A tun gbọ pe ṣe ni ọkunrin yii fun wọn ni orukọ ọmọ oye, to parọ fun wọn pe lati ọdọ Gomina lo ti wa pe  oun ni ki wọn fa a kalẹ gẹgẹ bi ọba niluu naa.

Ohun to n bi awọn araalu ninu ni pe ẹni ti ọkunrin yii fa a kalẹ yii, ko sẹni to mọ laarin ilu, bẹẹ ni wọn ni ko tun laju. Wọn tun fẹsun kan oloṣelu naa pe o fawọn afọbajẹ naa ni miliọnu meji abọ naira pe Gomina ni koun fun wọn.

Wọn ni titi di akoko yii,wọn ko tii fawọn afọbajẹ naa silẹ ati pe wọn lẹni tawọn araalu n fẹ ni Dokita Ọlasunkanmi Ismail Adeyẹmi. Idi niyi ti wọn fi ni ehonu lọ lọwọ pe awọn ko fẹẹ ọba ti yoo tun da ilu pada sẹyin.

Bẹẹ la tun gbọ pe Gomina ti sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹ, ki ẹnikẹni ma ṣe forukọ oun da ilu ru. Amọ sa, ọrọ naa ko tii loju tu.

No comments:

Post a Comment

Pages