Lati ana, Ọjọbọ, Tọsidee, lẹgbẹ awọn oniroyin ipinlẹ Ogun, bẹrẹ ayẹyẹ ikẹyin fun alaga wọn, Ọgbẹni Samson Olusọji Amosu,ẹni to jade laye lọjọ Sannde, to kọja yii, ṣugbọn ti wọn sin lonii in.
Isin ranpẹ kan ni wọn kọkọ ṣe fun un nirọlẹ ana, ni Iwe Iroyin, niluu Abẹokuta, nibi ti wọn ti pejọ lati bu ẹyẹ fun akọni ọkunrin to dagbere faye naa.
Oludasilẹ ijọ Treasure House of God, Pasitọ Ṣẹyẹ Senfuye, lo fi ọrọ Ọlọrun bọ awọn eeyan lọjọ naa, to si gba wọn nimọran pe ki wọn ranti pe gbese niku jẹ, idi niyi teeyan fi gbọdọ wa ni imurasilẹ.
Bakan naa lawọn eeyan lo anfaani naa lati sọ nipa iru ẹni ti Oloogbe naa ṣe nigba to wa laye.
Ni nnkan bii aago mẹjọ aarọ yii ni wọn gbe oku alaga fawọn oniroyin ọhun wa si Iwe-Iroyin, fawọn ọmọ ẹgbẹ ẹ lati ri fun igba ikẹyin, ko to di pe wọn gbe e pada lọ sile ẹ ni Bode Olude fawọn ẹbi lati ri bakan naa.
Aago mọkanla owurọ, ni isin ikẹyin waye ni Ṣọọṣi Antioch Baptist, Convenant Assembly, to wa ni Surudara, Bode Olude,nibi ti ara ati ojulumọ ti peju pesẹ.
Lẹyin naa ni wọn da oku ẹ pada sile, nibi ti wọn ti sin oku ẹ, ti wọn fi eeru fun eeru, eepẹ fun eepẹ, ti wọn si dagbere pe o digboṣe.
No comments:
Post a Comment