Mọlẹbi to ji awọn eeyan gbe si Ṣagamu ti ha o - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 9 March 2021

Mọlẹbi to ji awọn eeyan gbe si Ṣagamu ti ha o

 


Kayeefi lọrọ awọn mọlẹbi kan tọwọ tẹ fẹsun ajinigbe niluu Ṣagamu si n jẹ fawọn eeyan,tawọn tọwọ tẹ ọhun si ti n ka boroboro ni teṣan awọn ọlọpaa.

 

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn lo ti pẹ ti ariwo awọn ajinigbe fi pọ niluu Ṣagamu atawọn agbegbe ẹ lọdun to kọja, eyi lo si faa, ti Kọmissana awọn ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Edward Awolọwọ Ajogun, fi paṣẹ fun awọn ọga ọlọpaa ni gbogbo ayika ọhun lati ri pe wọn mu awọn ti wọn ṣiṣẹ ibi yii.

 

Loju ẹsẹ ni ọga ọlọpaa ẹkun Ṣagamu, CSP Okiki Agunbiade, pẹlu iranlọwọ awọn alaabo ilu labẹ Akarigbo ni Rẹmọ fi bẹrẹ igbesẹ ati iwadii lati mọ awọn to wa nidi ẹ.

 

Iwadii wọn yii lo jẹ ki ọwọ tẹ Oweniwe Okpara, lati ipinlẹ Delta atawọn ọmọ ẹ mẹta, Samson Okpara, Bright Okpara ati Eze Okpara ati  Christian Ishaha to gba wọn sọdọ. 

 

Ibi kan wọn n pe ni Ajaka, ni Ṣagamu, lọwọ ti tẹ awọn afurasi yii lori awọn ipa ti wọn ti ko lori jiji awọn eeyan mẹjọ gbe lawọn agbegbe kan niluu naa.

 

Lara iwadii awọn ọlọpaa ni wọn ti gbọ pe awọn mẹta mii in ninu mọlẹbi wọn, Godwin Okpara, Godspower Okpara ati Mathew Okpara ni ogbologbo ajinigbe nigba ti Samson, Bright ati Eze Okpara ṣiṣẹ lori awọn ti wọn ba fẹẹ ji gbe.

 

Awọn ọlọpaa tun tẹ siwaju pe lara awọn ti awọn afurasi ọhun ti ji gbe ni Okechukwu Onwubiko, Ọmọtayọ Ṣobọwale,Lamidi Akeem,Arabinrin Arẹoye Olufunkẹ, ati awọn mii in.. 

 

Wọn ni bawọn ogbologbo ajinigbe yii ṣe gbọ pe ọwọ ti tẹ baba wọn atawọn aburo wọn ni Godwin, Godspower ati Mathew Okpara ba sa lọ sipinlẹ Delta pẹlu mọto ti wọn fi ṣiṣẹ ibi atawọn ohun ija oloro ti wọn n lo.

 

Awọn ọlọpaa naa sọ pe pẹlu ifowosowọpọ awọn olopaa Delta lọwọ ti tẹ wọn. Wọn tiẹ ni oko ti baba wọn n lo tẹlẹ ni Ayepe-ijẹbu, ni wọn sọ di agọ ibi ti wọn n tọju awọn ti wọn ba ji gbe si.

 

Ni bayii, kọmisanna fawọn ọlọpaa ọhun ti wa fi idunnu ẹ han si iṣẹ tawọn ọmọ ẹ yii ṣe, o wa paṣẹ pe ki iwadii tẹsiwaju ati pe awọn afurasi yii yoo foju bale-ẹjọ laipẹ.

 

No comments:

Post a Comment

Pages