Ọnarebu Sanyaolu Abayọmi, alaga fẹgbẹ oṣelu Action Alliance, iyẹn A A nipinlẹ Ogun ti sọ pe ẹgbẹ naa ti ṣetan lati gbajọba lọwọ APC lọdun 2023, nitori ẹgbẹ naa ti ku, nitori awọn wahala to n fojoojumọ ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa. Bẹẹ naa lo ni ko le saye fẹgbẹ oṣelu PDP naa mọ nitori awọn ti ku tipẹ ni tiwọn.
O sọrọ yii lakooko to n bawọn ọmọ ẹgbẹ naa sọrọ nibi
ipade ati ṣiṣe agbekalẹ awọn oloye ẹgbẹ ọhun lawọn ijọba ibilẹ,eyi to waye
niluu Ilaro.
O sọ pe ẹgbẹ naa jẹ tawọn ti mẹkunnu idi niyii to fi jẹ
pe gbogbo ọna lawọn yoo sa lati ri pe iṣẹ ati iya dopin laaarin awọn araalu
lakooko ti wọn gbajọba.
Lori ibo ijọba ibilẹ to n bọ lọna, Abayọmi sọ pe awọn ti
wa ni imurasilẹ gidi,nitori igbagbọ awọn ni pe ti eto naa ba bẹrẹ ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ
oṣelu APC ni yoo fẹẹ wa darapọ mọ ẹgbẹ Action Alliance.
O nitori awọn eeyan ko fẹẹ wọn mọ lorileede yii, akoko wọn
lo sọ pe awọn darandaran to n paayan wọlu.Gbogbo awọn eeyan wọn ni won ti fẹẹ
pa tan. Ẹgbẹ awọn si ti ṣeto pe bawọn ba gba ijọba, abo araalu ni nnkan akọkọ
to jẹ wọn logun.
O sọ pe awọn ti wọn ni ki wọn ṣeto ibo ijọba ibilẹ ọhun
awọn nigbagbọ, awọn ko nigbagbọ kọ lo jẹ awọn logun, bi awọn ba na wọn tinu tẹyin,
yoo ṣoro fun wọn lati ṣe ojooro. O ni ẹni to ko wọn sibẹ ara APC ni,ki wa ni
idaniloju pe wọn yoo ṣootọ, ara APC ni wọn.
Abayọmi ni bi wọn ṣe n yan igbimọ ti wọn lawọn tan naa ti
wọn, nitori toju tiyẹ laparo fi n riran. Ninu ọrọ ti Ọnarebu Dapọ Adeyẹmi, to jẹ
agba ẹgbẹ naa lo ti sọ pe oun naa sọ pe pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii ki ẹgbẹ oṣelu
APC ma palẹ ẹru wọn mọ.
No comments:
Post a Comment