Idunnu lo subu layọ fẹgbẹ awọn oniroyin ipinlẹ Ogun, lọjọruu, Wẹsidee, nigba ti ile-ẹjọ kan to wa niluu Ibadan da Ọgbẹni Samson Amosu lare gẹgẹ bi alaga fẹgbẹ awọn oniroyin nipinlẹ naa.
Bo tilẹ jẹ pe bawọn kan ṣe n dun
nu bẹẹ lawọn alatako ọkunrin naa ti wọn fidi rẹmi ninu ẹjọ bọ sibi kan, ti wọn
si n bara jẹ, beeyan ba si ti roju wọn yoo mọ pe ẹkun abẹnu ni wọn n sun
Ninu ẹjọ
ọhun ti nọmba ẹ jẹ NICN/IB/85/2019,Adajọ J D Peters ti fidi ẹ mulẹ pe ko si awtunwi
asan kankan rara ibo to gbe Samson Amosu wọle atawọn yooku ẹ, Kunle Olayẹni, igbakeji
alaga, Kunle Ewuoso,igbakeji ati Abiodun Taiwo, igbakeji alaga jẹ itẹwọgba labẹ
ofin ti ẹgbẹ naa la kalẹ.
Adajọ naa tun ṣalaye pe bi wọn ṣe wọgi le ibo to waye lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun yii, ko
bofinmu rara ti ko si lẹsẹ nilẹ pẹlu.
Ẹbẹ meje tawọn olupẹjọ bẹbẹ fun ninu mẹjọ ni Adajọ naa gba wọle
bẹẹ lo tun ni kawọn olujẹjọ san ẹgbẹrun lọna igba naira fun olupẹjọ.
Sọji Amosu atawọn eeyan ẹ mẹta lo gbe aarẹ ẹgbẹ naa Chris
Isiguzo, akọwe ẹgbẹ, Shuaib Leman, atawọn mejila mii in lọ sile ẹjọ lori bi wọn
ṣe fagile ibo ti wọn fi gbe wọn wọle.
No comments:
Post a Comment