Lojumọ to mọ lonii, bi wọn ba n sọrọ awọn to lẹnu nibẹ ninu oṣelu nipinlẹ Ogun, Ṣẹgun Ṣowumi jẹ ọkan lara awọn, nitori wọn gba pe ko kii figba kan bọkan ninu. Ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni, o si jẹ agbẹnusọ fun oludije ipo aarẹ ninu ibo to kọja, iyẹn Atiku Abubakar.
Laipẹ yii lo gba oniroyin wa lalejo sile ẹ, niluu Abẹokuta, nibi to ti sọ
nipa bi nnkan ṣe n lọ si laaarin ilu, paapaa julọ wahala Fulani darandaran atawọn
Yoruba, ohun to ba wa sọ ree.
Wahala to n ṣẹlẹ
lori ọrọ Yoruba atawọn Fulani darandaran.
Akọkọ naa ẹ jẹ ki n sọ fun yin pe emi o, ko gba pe ka maa
forukọ ẹya pe awọn to n da whala silẹ laaarin ilu.Bi a ba maa sọ pe Akimu ṣe
nnkan, ka darukọ ẹ pe oun lo ṣe e, ka ma sọ pe
Yoruba ṣe nnkan.
Bi darandaran ba ṣe nnkan, ka ni awọn lo ṣe, ko wa dara
ki a maa pariwo Fulani.Idi ti mo fi n sọ bẹẹ re, ti ọtẹ ba fẹẹ bẹrẹ iṣẹ o maa n
dabi ere.
Ṣugbọn to ba ya agbara gbogbo wa ko nii ka mọ.Ẹyin ẹ wo
lakooko yii, ibi taa ba ilu yii de. Loootọ ni gbogbo wa mọ pe ipenija wa fun
ilu lori eto aabo.
Ipenija to si wa nita, ọna abayọri ni ki gbogbo wa jokoo,
ka wa ọna bi a ṣe maa se atunto lori ọrọ idaboobo ilu, eyi taa ti n pariwo ẹ
tipẹ.Ka ni a ti wa wọrọkọ ṣada ni, o ṣee ṣe ko jẹ pe ọlọpaa ilu, ọlọpaa ibilẹ
ati ọlọpaa ijọba apapọ, kawọn mẹtẹẹta jọ maa ṣiṣẹ pọ.
O ṣee ṣe ko jẹ pe gbogbo nnkan taa fi n da wahala silẹ
maa ribẹ mọ.Nigba tawọn darandaran ba ko ẹran sinu oko, ti wọn lọ jẹ nnkan ọgbin
oloko, ki gbogbo iranu taa n gbọ yẹn, taa o si fọwọ si maa ṣẹlẹ,
Igba ti wọn yoo wa maa sọ, Yoruba a pariwo pe fulani ni,
Fulani ni,, awọn ẹni ẹlẹni to ti n gbe ibi, ti wọn ti n ṣiṣẹ wọn awọn lẹ maa
ko,tawọn naa ba wa ni o daa, Yoruba ti kọlu awọn eeyan wọn,ti wọn ba sọ pe awọn
fẹẹ kọlu Yoruba, ṣe Yoruba to n ṣe ijanba ni wọn maa kọlu.
Gbogbo nnkan bayii ni ko jẹ ki n gba ki a maa forukọ ẹya
pe awọn to n da wahala silẹ. Ẹni to ba n dalu ru, ko yẹ ki a maa forukọ ẹya pe e.Nnkan
taa ma ri nidi ẹ, o maa le gan ni ni o.
Iyẹn lọ bẹẹ, Ẹlẹẹkeji ni pe a o gbọdọ maa tan ara wa jẹ
niluu yii.Awa nikan kọ la n jẹ ẹran ni gbogbo agbaye,gbogbo ibi tawọn eeyan wa
laye, ni wọn ti n jẹ ẹja, ti wọn jẹ ẹran.
A o si wa gbọdọ wa fẹran ẹran, ko to wa di pe ẹran yoo ma
ṣe ọga lori eeyan. O yẹ ka ti mọ daju pe irinajo ka maa da ẹran kaakiri, ko
sibi ti wọn ti n ṣe mọ lagbaye.
Gbogbo awọn ilu to ti nilọsiwaju ni wọn ti mu ẹran wọn
sibi ti wọn ti sin wọn. Ti wọn si ti n wa ounjẹ fun wọn. Gbogbo agbaye kọkọ bẹrẹ
ki wọn maa da ẹran. Ṣugbọn awọn to ku ti kuro nidi ẹ.
Awa o gbọdọ sọ pe kinni kan ṣe ẹlẹdẹ ni pakọ, a o le yii
pada.Nitori pe ko si bi a ṣe fẹẹ ṣalaye pe a ko mọ ẹni to ni ẹran.A ti to lati
maa sọ fawọn to sin ẹran niluu wa, a ni lati mọ wọn.
Wọn ni lati gbaṣẹ lọwọ ijọba, a si ni lati sami si awọn ẹran
wọn lara.Ijọba ipinlẹ nilẹ Yoruba, wọn ko mọ nnkan ti wọn n ṣe, nnkan ti ọrọ wọn
kan, wọn ko mọ.
O ti le ni ọdun kan bayii ti wọn sọ pe awọn fẹẹ da Amọtẹkun
silẹ,lẹyin ti wọn ti pariwo yẹn, kin ni nnkan taa ri, taa fi le sọ pe eto abo
Amọtẹkun yẹn rin daadaa.
Ṣe Eko la ti ri ni abi ipinlẹ Ogun,nnkan ti wọn sọ pe awọn
gbe kalẹ ki gbogbo ilẹ Yoruba, ki wọn jọ dalẹ, ki wọn mọ bi wọn yoo ṣe gba
eeyan si, ti wọn yoo ra nnkan ti wọn yoo fi ṣiṣẹ fun wọn.
Niṣe ni wọn sọ di yẹyẹ ni awọn ibi to yẹ ki wọn gba ti gbaju
mọ.Ijọba apapọ naa ko tun ran iṣẹ yii lọwọ. O ti n to bi ọdun mẹta sẹyin, tinu
mi ko tii n dun.
Bi awọn eeyan ṣe n fi ọrọ kobakugbe, to le da nnkan ru ba
awọn ẹya.Tijọba si laju silẹ, to n wo wọn niran. Ti onikaluku sọ ara ẹ di
ajijangbara niluu to ni ọba ati ijoye.
Ṣugbọn amukun wọn ni ẹru ẹ wọ, o ni ilẹ lẹ n wo, ẹ o wo
oke.Aarẹ funra wọn, wọn ko ṣe daadaa to lori ọrọ yii, nitori o jẹ ki n ranti
nigba ti Oluṣẹgun Ọbasanjọ gbajọba lọdun 1999.
Ọwọ agbara lo fi mu awọn OPC nigba ti wọn ṣe bo ṣe wu wọn.Ki
wọn le mọ pe oun ko si nidii iru nnkan bẹẹ yẹn.Ṣugbọn ṣe ni Buhari fọwọ pa awọn
eleyii lori, lati ọjọ ti wọn ti sọ pe awọn darandaran ṣe gba, wọn ṣe awo, ko si
ọjọ kan ri taa gbọ pe wọn mu wọn ri.
Eyi to buru jai nibẹ ni pe bi gbogbo wọn ṣe n sọrọ
too,kii ṣe bẹẹ lo ṣe jẹ kijọba lọ. Bi a ko ba tete wa nnkan ṣe si ara ko le rọ
okun, ko le rọ ẹyẹ.
Nigba ti ẹ ba sọ pe ẹ o fẹẹ awọn Hausa to n gbe niluu yin
mọ, awọn ọmọ yin to n gbe ibẹ kọ, kin ni ẹ fẹ jẹ ki wọn ṣe fun wọn .A n sọ pe
akoko ti to ki ẹ pe awọn ilu jọ, ki wọn jokoo ki wọn sọrọ bi a ṣe fẹẹ maa gbe
ni itunbi inu bi,iyẹn atunto, ki onikaluku tiẹ sọ tiẹ, ka le mọ nnkan to n da
wahala silẹ.
Mo fẹ ki ẹ mọ pe to ba ya agbara ofin ko ni kaa mọ nigba
tawọn to n daran ba pọju niluu.Ibi tiṣẹ ku si ju ni bi a ṣe maa jere ọkan awọn
wa fun ilu, lati jẹ ki wọn mọ pe ko si anfaani kankan ninu gbogbo irinajo yii.
Awọn to yẹ ki o jẹ olori ilu to yẹ ki wọn sọrọ sibi to yẹ,
nitori ọjọ ọla oṣelu wọn ko nii jẹ ki wọn soootọ ọrọ. Ni temi, bi mo ṣe wa
bayii, ọkan mi bajẹ pupọpupọ ni.
Nitori mi o lero pe wọn mọ pe arun to ṣe ọya, gbogbo ọlọya
lo n ṣe.Mi o mọ idi tawọn mẹkunnu si mẹkunnu yoo maa bara wọn ja.Njẹ ẹyin gbọ
pe olowo Hausa ati Yoruba duro sibi kan, wọn n ja.
Awọn eeyan wa ti wọn si n kọ iroyin, ti wọn ko kọ, ti wọn
ko nimọ lori iṣẹ naa ti wọn yoo kan gbe sori ẹrọ ayelujara, a fẹẹ sọ iroyin, a
fẹẹ mu inu awọn araalu dun iyẹn ti yatọ si pe a fẹẹ da wahala silẹ.
A dara ki ẹyn to n kọ iroyin jẹ ki ori awọn araalu ko pe,
ki wọn sọ ewe agbejẹ mọwọ jagajaga jatijati ti pọju, iṣuna ilu gan-an ko tii
gun rege, awọn to jẹ kijọba maa gba, asiko ti to lati ṣe atunṣe ilu.
Lẹyin ko si ọpọlọ kankan nibẹ bi a ba sọ pe a ko ni tun
eto abo ọlọpaa, awọn ati ibilẹ, ipinlẹ wọn gbọdọ wa lẹgbẹ ara wọn lati maa ṣiṣẹ
pọ ni.
Ninu itan wa lorileede yii, tijọba Buhari lo buru jai, a
fi ki Ọlọrun ọba ko gba wa. Awa eeyan ilu a ko gbọdọ jẹ ki nnkan to ti kan tun
wa danu. A fi ki a rọju kaa bara wa sọrọ Fulani kii ṣe ọta Yoruba, Yoruba naa
kii ṣe ọta Fulani, aigbọra ẹni ye nibi tọrọ wa.
Ọna wa tijọba le gba yanju ẹ nilana ọgbin, ẹni ti maalu
ba jẹran, o yẹ ki wọn ni ki wọn wa lati fun wọn lowo nnkan ti wọn bajẹ nipasẹ bẹẹ
ko ni si wahala awọn eeyan ko si ni maa binu.
Ko sibi taa ti fẹẹ gba yin wọn, ọrọ iṣuna ilu a ko le yin
wọn nibẹ, ọrọ abo bakan naa, a ko le yin wọn nibẹ.Ọrọ itajẹsilẹ, ka wa ni
alaafia, a ko le yin wọn nibẹ.
A tun gbọ pe awọn darandaran janduku ti wọn ba mu wọn, awọn
kan tun gba wọn silẹ ni. Ọjọ wo ni a fẹẹ ṣe iyẹn da, ṣe ẹni to ran wọn niṣẹ naa
lo ni ki wọn maa fi tipa ba obinrin sun, sebi okoowo ni wọn fi ẹran wọn ṣe bawo
wa ni wọn tun ṣe fẹẹ donile mọ onilu nilẹ. A ko le wa dẹni to maa wa tẹriba fun
ẹran o, ko jọ rara.
Lori ọrọ Sunday
Igboho to dide lati ja fawọn Yoruba.
Ṣe ni mo kan roo pe beeyan ba ro didun ifọn, yoo họra mọ
eegun,ibi ti aimojuto nnkan taa ko sawọn ijọba labẹ ku si niyẹn.Bi ko ba ṣe bẹẹ
ni bawo lo ṣe maa kan iru eeyan bi Sunday igboho yẹn, lati maa ni kawọn eeyan
kuro niluu.
Ibinu pe o fẹẹ ṣe ọmọ ọkọ naa ni. Nnkan bẹẹ ko le bi
nnkan re, nitori to ba ya,melo melo iru Sunday Igboho la le ko jade nilẹ Yoruba
o kunlẹ. Bi onikaluku ba bẹrẹ laduugbo ẹ, bawo ni agbara ijọba ṣe fẹẹ ka.
Ṣe ijọba taa gbe iṣẹ yẹn le lọwọ gan-an bi wọn ko ba sun
jatọ ni bawo lo ṣe fẹẹ kan araalu, lati maa ja ajagbara niluu to lọba, to
nijoye.Bẹẹ ṣe eeyan yoo wa niluu yoo si maa wo bi wọn ṣe n ṣe yẹn, ti yoo si
maa lọ bẹẹ.
Lori ọrọ yẹn o ṣe ni laaanu pe awọn ijọba apapọ ati
tipinlẹ jẹ ki ọrọ debi to de yẹn. Ṣugbọn o ba ni ko ba jẹ, mo rọ wọn ki
onikaluku pada si ọwọ aarọ wọn.
Ipade ti mo n ṣe
kaakiri ipinlẹ Ogun
Awọn eeyan kan n da mi laamu pe ki n jade nitori awọn ọrọ
tawọn maa n gbọ lẹnu mi atawọn eto bo ṣe yẹn ki nnkan ko ri, nnkan to daa ni, wọn
ni ki lo de tiwọ funra ẹ ko jade lati ṣe gomina wa.
Nnkan ti mo si maa n sọ ni pe ti mo ba mu amọran wa,ẹni
to wa nibẹ le loo, ki ilu ṣa ti dara ni.Ṣugbọn nigba ti ọrọ yii ko ni duro tawọn
eeyan yii ko ni dẹkun, ni mo ba sọ pe o dara, ka tiẹ bẹrẹ si ni bi wọn.
Mo sọ fun wọn pe to ba jẹ pe owo ni ẹ n wa, ẹyin eeyan ẹ
ko le wa si ọdọ mi o,nitori mi ko si ninu awọn to n ba yin ko adiẹ alẹ. Amọ to
ba jẹ pe akinkanju imọran ati oye, ti ẹ ba sọ pe ẹ ẹ maa ran mi o, maa sọ pe
Oluwa emi ree o, ran mi.Iyẹn la n ṣe, bi a ba ṣe debi kan, a o mọ ohun to maa ṣẹlẹ,
nitori ẹru ajanaku ni, ajọṣe, ajọpin, ajọto ni wọn fi ṣe ilu. Gbogbo ipinlẹ
Ogun ni mo n lọ.
Ẹgbẹ oṣelu PDP
ni mo wa titi di akoko yii.
Titi di ọla abẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ni mo wa. A si n bẹ Ọlọrun
ọba ko jẹ ki alaafia jọba ninu ẹgbẹ naa. A ma woo lọ bẹẹ nitori latigba ti wọn
ti da ẹgbẹ naa silẹ, mi o kuro nibẹ ri.Ko si ya mi lara lati kuro nibẹ ṣugbọn
to ba to akoko kan, a maa tun gbogbo ẹ ro naa ni. Ṣugbọn a ko le ba oṣelu debi
pe ti ẹgbẹ ko ba lọ siwaju, a o ni kuro nibẹ.
Good work Sir
ReplyDelete