Bejeroku Oke-Agbo gbe igbimọ ilọsiwaju ati abo kalẹ niluu Ijẹbu Igbo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 20 February 2021

Bejeroku Oke-Agbo gbe igbimọ ilọsiwaju ati abo kalẹ niluu Ijẹbu Igbo

 


Bejeroku ti Oke-Agbo, niluu Ijẹbu Igbo,Ọba Stephen Adeleke Adekọya ti gbe igbimọ oriṣi meji kalẹ fun ilọsiwaju ati abo kalẹ fun ilu naa. Ninu atẹjade ti Ọba naa fi sita lo ti sọ pe igbimọ akọkọ ni yoo jẹ ẹlẹni mẹẹdogun, nigba ti igbimọ keji yoo si jẹ ẹlẹni mẹjọ.

Igbimọ akọkọ yii lo sọ pe yoo maa ri si bi nnkan ṣe n lọ si niluu ọhun, ti yoo si tun wa ọna bi idagbasoke yoo ṣe de ba ilu Oke-Agbo. Nigba to ni igbimọ keji to jẹ ẹlẹni mẹjọ yoo maa ṣiṣẹ lori abo, ọgbin, awọn oko ọba atawọn nnkan to ba nii ṣe pẹlu ala.

Awọn igbimọ to jẹ ti akọkọ, ẹlẹni mẹẹdogun yii ti wọn pe ni igbimọ Bejeroku ni Ọba ilu ọhun, Ọba Stephen Adeleke Adekọya ti jẹ alaga wọn,nigba ti Ọmọọba Ṣowumi Solu jẹ akọwe. Awọn yooku ni Oloye Adetọla Ogunade,Oloye S A Osiyọye, Oloye Kayọde Azeez.

Awọn to tun wa nibẹ ni Oloye S O Odufowora,Oloye Dele Abiọdun,Oloye Babatunde Ipaye, Ọtunba Felix Babatunde Asegbe,Ọnarebu Osifẹsọ Olukorede, Oloye Oloritun Pitan, Ọgbẹni Ọlaṣile Adedoyin, Oloye Baṣiru Salau, Oloye Oloritun Jide Aileru ati Ọmọọba Atanda Okunọwọ,

Awọn igbimọ ti yoo maa ri si ti eto abo ni Ọgbẹni S Dina to jẹ alaga wọn, Ọgagun Atanda Okunnọwọ nigba keji ẹ, nigba ti Ọmọọba Wale Awonuga si jẹ akọwe. Awọn yooku ni Ahmed Aboki to jẹ aṣoju fijilante nibẹ, aṣoju awọn ọlọpaa, aṣoju awọnagbofinro,aṣoju awọn alaabo ilu iyẹn siifu,ati aṣoju awọn So Safe Corps.

Igbimọ ti yoo maa ri si ti ọgbin ni Oloye Yinka Odusẹyẹ jẹ alaga, Oloye Augustine Talabi si jẹ igbakeji,nigba ti  Ọmọọba Adelaja Ọlaṣeni Sulaiman, Ọmọọba Falẹyẹ Osagie Yọmi  aṣoju meji lati igbimọ awọn Baalẹ jẹ igbimọ.

 Kabiyesi wa mu da gbogbo awọn araalu loju pe pẹlu idasilẹ awọn igbimọ yii, o daju pe awọn ohun idagbasoke ati abo to peye yoo wa niluu naa.

 

No comments:

Post a Comment

Pages