Beeyan ba de adugbo Ijeun Titun, nibi ti gbajumọ oṣere onifuji nni, to jade laye lana an, Alaaji Taofeek Adeyinka, tọpọ awọn ololufẹ ẹ mọ si Tobacco yoo mọ pe adanu nla niku ọkunrin naa jẹ.
Ibeere tọpọ awọn eeyan naa n beere lọwọ ara wọn ni pe ṣe
loootọ ni gomina fẹgbẹ awọn onifuji, nipinlẹ Ogun, jade laye. Ko si yẹ ko ma ri bẹ nitori awọn
eeyan ti wọn ri gbẹyin sọ pe ko si nnkan to ṣee tẹlẹ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, gbogbo eto lawọn onifuji ti la silẹ fun
ti adura ọjọ naa ati lati ṣẹyẹ ikẹyin fun ọkunrin naa to dagbere faye lọjọruu,
Wesidee, to kọja ti wọn sin si oku ẹ lọjọ keji nile ẹ to wa ni Ijeun Titun,
niluu Abẹokuta.
Kayefi lọrọ iku ẹ si n jẹ fawọn eeyan ẹ nitori wọn ni ko
si nnkan to ṣe ọkunrin naa tẹlẹ, wọn ni ko ṣe aisan rara, ọpọ tọrọ iku yii ya lẹnu
ni wọn sọ pe a fi bi ala lo ri loju awọn.
Gbogbo aarọ ọjọ naa lawọn ti wọn jọ gbe so pe awọn rii,
koda wọn lo ki irun aago mẹrin irọlẹ ọjọ naa, a fi bi wọn ṣe lọrọ yii ni nnkan
bi aago mẹfa abọ irọlẹ, ti wọn lo ṣubu lojiji niwaju ile ẹ.
Bawọn eeyan ṣe sare sii ti wọn gbee dide, ni wọn sare gbe
lọ si ọṣibitu ṣugbon o ṣe ni laanu pe ko to de ọsibitu FMC Idi –Aba, ọga onifuji
yii ti jade laye.
Aago mẹwaa aarọ ọjọ keji ni wọn sin nilana musulumi. Ọpọ
awọn to wa nibẹ ni wọn ṣapejuwe Gomina awọn onifuji yii gẹgẹ bi eeyan jẹjẹ, to
si maa n fẹ ilọsiwaju ọmọnikeji ẹ.
Lalẹ ọjọ to ku naa ni Alaaji Ṣẹfiu Alao atawọn irawọ
onifuji de ọdọ awọn mọlẹbi, to si n jẹ kayefi sun wọn.
Lọjọbọ, Tọsidee,
ọsẹ yii ni wọn yoo ṣadura ọjọ mẹjọ oku gbajumọ onifuji, to tun jẹ gomina fẹgbẹ
awọn onifuji nipinlẹ Ogun, Alaaji Taofeek Adeyinka, tọpọ awọn eeyan ẹ mọ si
Tobacco.
No comments:
Post a Comment