Lalẹ ana, ọjọ Iṣẹgun, Tusudee, ni Ọtunba Gbenga Daniel, gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, fẹgbẹ oṣelu PDP silẹ, to si lọ darapọ mọ ẹgbẹ APC.
Nibi ayẹyẹ naa to waye nile ẹ to wa ni Asọludẹrọ, Ṣagamu, ni Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun atawọn akẹgbẹ ẹ Rotimi Akeredolu, tipinlẹ Ondo, Atiku Bagudu, Kebbi, Abdullahi Ganduje, Kano, ati Abubakar Sanni Bello, tipinlẹ Niger, ti kii kaabọ sinu ẹgbẹ naa,
Bello to jẹ alaga igbimọ iforukọsilẹ ẹgbẹ naa lo fun Daniel ni igbalẹ gẹgẹ bi ami pe o ti dọmọ ẹgbẹ oṣelu yii. O fikun ọrọ ẹ pe alaga igbimọ fidihẹ ẹgbẹ naa Mai Mala Buni, ati Bagudu yoo mu Daniel lọ ba Aarẹ Muhammadu Buhari laipẹ.
Bagudu to jẹ alaga fawọn gomina APC ṣapejuwe Daniel gẹgẹ bi oloṣelu to ni imọ ati oye oṣelu daadaa, o ni pẹlu bi ọkunrin yii ṣe darapọ mọ wọn yoo tun jẹ ko goke si ni. O wa ni inu ẹgbẹ oṣelu naa dun lati gbaa wọle
Akeredolu sọ ni tiẹ pe bigba ti Daniel pada wale loun ka idarapọmọ ẹgbẹ naa si nitori awọn ti jọ wa tipẹ, o wa gba gbogbo awọn to wa ninu ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun nimọran lati jọ ṣiṣẹ pọ.
Nigba to n sọrọ Daniel sọ pe idi toun fi darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC lakooko yii jẹ nnkan toun ro daadaa koun to ṣe.
O ni lero toun awọn aṣaaju ni lati jọ papọ ki wọn jọ ṣiṣẹ pọ lati le dojukọ awọn ipenija lohun kan.
Lalẹ ana, ọjọ Iṣẹgun,
Tusudee, ni Ọtunba Gbenga Daniel, gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, fẹgbẹ oṣelu PDP
silẹ, to si lọ darapọ mọ ẹgbẹ APC.
O ni lero toun awọn aṣaaju ni lati jọ papọ
ki wọn jọ ṣiṣẹ pọ lati le dojukọ awọn ipenija lohun kan.
No comments:
Post a Comment