Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun, ti sọ pe akoko ti wa
to bayii lati yanju wahala to n waye laarin awọn agbẹ atawọn darandaran, ti wọn
yoo si wa abayọri si.
Ọkunrin yii sọrọ nibi ipade kan ti wọn ṣe fawọn fọrọ naa
kan iyẹn awọn agbe atawọn darandaran
nibi tawọn mejeeji ti ni aṣoju nibẹ, eyi to waye ni Ọbas Complex, Oke-Mosan Abẹokuta.
Nibẹ lo ti sọ pe iyalẹnu lo jẹ foun pe bawo lawọn eeyan
ti wọn ti jọ n gbe lọjọ pipẹ ṣe wa dẹni to n bara wọn ja.
Nibi ipade ọhun lawọn Gomina mẹrin lati ilẹ Hausa ti wa
nibẹ, awọn Gomina ọhun ni Gomina
tipinlẹ Kano, Dokita Abdulahi Ganduje, Abubakar Sanni, lati ipinlẹ Niger, Alaaji
Bello Mattawale, tipinlẹ Zamfara.
Awọn yooku ni Gomina
ipinlẹ Kebbi, Atiku Abubakar Bagudu nigba ti Arakunrin
Rotimi Akeredolu lati ipinlẹ Ondo naa wa nibẹ lọjọ naa.
Abiọdun sọ pe o ṣe jẹ
pe awọn eeyan ti wọn jọ n gbe lati bi ọdun meloo sẹyin ni wọn wa di ọta ara wọn
bayii,idi niyii tawọn fi gbọdọ wa abayọri si nnkan to n da wahala silẹ ọhun.
O wa mu dawọn eeyan
loju pe gbogbo ọna loun yoo sa lati ri pe eto abo to peye wa fun gbogbo olugbe
ipinlẹ Ogun, bẹẹ lo ni oun ko jẹ gomina ẹya kan nipinlẹ naa bi ko ṣe fawọn to n
gbe nibẹ.
Gomina tun sọ pe
gbogbo wọn lapapọ lo ni lati jọ fọwọsowọpọ lati rii pe iwa ọdaran dinku lawujọ.
O wa lo akoko naa lati sọ pe oun ko wa lati dẹbi wahala nnkan to n ṣẹlẹ yii lori
ẹnikẹni bi ko ṣe lati wa ọna bi alaafia yoo ṣejọba
NInu ọrọ ti Gomina
tipinlẹ Kano, Dokita Abdulahi Ganduje, dẹbi nnkan to n ṣẹlẹ laarin awọn agbẹ
atawọn darandaran lori aini imọ ẹkọ to, ati oṣi to wa laarin wọn,o wa pe ipe pe
ki wọn fopin si lati maa da ẹran lati apa north si South
Gomina Abubakar Sanni Bello,
lati Niger, pe ipe lati tete wa ọna abayọri si wahala to n ṣẹlẹ yii, ko ma baa
tun yọju lọjọ iwaju.
Arakunrin Rotimi
Akeredolu, tipinlẹ Ondo, sọ ni tiẹ pe o yẹ ki wọn wa ọna to jẹ pe awọn
darandaran yoo duro si ipinlẹ wọn, ti wọn yoo si faye gba awọn to ba fẹ ra maalu
lati wa ba wọn nibi ti wọn ba wa.
Nibi ipade ọhun lawọn
ọba alaye naa ti wa nibẹ. Bẹẹ lawọn Miyetti Allah naa ti ni aṣoju.
No comments:
Post a Comment