Lọjọruu,Wẹsidee, nileeṣẹ
ọlọpaa ipinlẹ Ogun. ẹka to n to n ri si ọrọ to nii ṣe pẹlu bọmbu ṣayẹyẹ nla fun
meje ninu wọn to nigbega lati ipo kan si omin-in,eyi tileeṣe wọn patapata niluu
Abuja fọwọsi.
Ayẹyẹ naa to waye niluu Abẹokuta, lawọn ọlọpaa yooku ti fi iduunu
wọn han sawọn to gba igbega ọhun. Bẹẹ ni wọn tun lo anfaani yii lati ṣami fawọn
to gba igbega naa si ipo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ wa yii.
Lara awọn ti wọn gba igbega tuntun ọhun ni Olusegun Adebiyi, Razak Oyediran. Nigba to n sọrọ
nibi ayẹyẹ yii, Ọga ọlọpaa Taiwo Akingbehin, to jẹ ọga agba ni ẹka naa fi
idunnu ẹ han si ọga agba patapata lorileede yii, Abubakar Adamu fun bo ṣe fawọn
eeyan ọhun nigbega nitori akitiyan tawọn eeyan yii ti ko ninu iṣẹ ti wọn yan
laayo.
O ṣalaye pe ohun ti igbega
tumọ si ni ki eeyan tubọ ṣa ipa ẹ lori iṣẹ to ba n ṣe. O wa lo akoko naa lati
gbawọn ti wọn ni igbega nimọran lati mu igbega jẹ ohun rere fawọn ẹbi wọn nipa
lati ma ṣe huwa buruku lawujọ.
O ni oun fẹẹ jẹ ki wọn
mu iṣẹ wọn lọkunkundun ju bi wọn ṣe n ṣe lọ tẹlẹ nitori ọpọ igbega lo si wa
niwaju wọn.
Adebiyi, to gba ipo tuntun gẹgẹ bi ‘’Superintendent
of Police’’ (SP), lo jade nileewe yunifasiti Ambrose Ali, Ekpoma nibi to ti gba
imọ ijinlẹ lori imọ sayẹnsi Micro Biology ati oye masita ninu imọ iwa ọdaran
iyẹn Criminology and Security Studies.
Nigba to n sọrọ nipa
Adebiyi to ṣẹṣẹ gba ipo igbega yii, Akingbehin ṣalaye pe ọrọ ẹ ko jọ oun loju
nitori igbesẹ baba ẹ, toun ti fẹyinti ninu iṣẹ ọlọpaa loun naa tẹle. O ni ọdun
marundinlogoji ni Baba naa lo nidi iṣẹ ọlọpaa ko to fẹyinti.
No comments:
Post a Comment