Onimọ-ẹrọ, Nọimọt Salakọ,
igbakeji gomina nipinlẹ Ogun, ti gba gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, tipinlẹ naa
lamọran lati yago fun ohun to le da wahala silẹ lakooko itorukọ silẹ ẹgbẹ yii
to n lọ lọwọ.
Obinrin ọhun sọrọ yii lakooko toun naa forukọ silẹ ni wọọdu
kẹta, GRA, Ọta, nijọba ibilẹ Ado- Odo- Ọta, o sọ fawọn eeyan pe ki wọn sọra fawọn
nnkan to le da eto iforukọsilẹ ẹgbẹ naa ru.
O sọ pe lara ojuṣe ọmọ ẹgbẹ naa ni lati ri pe wọn pe ọpọ
awọn eeyan jade lati wa forukọ wọn silẹ ninu ẹgbẹ yii. O ni gbogbo ẹtọ to wa
nidii oṣelu kii ṣe fawọn to wa nijọba nikan, ṣugbọn fun gbogbo awọn eeyan lati
jọ jẹ mudunmudun ẹ.
Igbakeji Gomina ni ọna
kan pataki ti wọn le fi ṣe eyi ni pe ki wọn forukọ silẹ lati jọ jẹ ọmọ ẹgbẹ
ninu eto ti wọn n ṣe yi, O ni inu oun dun lati sọ pe Ogun West jẹ anfaani nla
ninu iṣejọba to n lọ lọwọ, eyi ti Ọmọọba Dapọ Abiọdun jẹ olori fun.
O
wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ APC ni lagbegbe naa lati rii pe wọn jade, wọn si kopa ninu
eto to sọ pe yoo pari lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu yii.
No comments:
Post a Comment