Ija Yoruba ni Sunday Igboho ja, a gbọdọ ṣatilẹyin fun un- Ọba Iṣelu ni Yewa - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 4 February 2021

Ija Yoruba ni Sunday Igboho ja, a gbọdọ ṣatilẹyin fun un- Ọba Iṣelu ni Yewa

 Ọkan lara Ọba ilẹ Yewa, tawọn Fulani darandaran n pa awọn eeyan wọn nipakupa, ti wọn ji wọn gbe, ti wọn si tun fipa bawọn obinrin wọn sun, Ọba Akintunde Akinyẹmi, to jẹ Iṣelu tiluu Iselu,  ti sọ pe ija awọn iran Yoruba ni ajijagbara nni Sunday Adeyẹmọ tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho n gbe, o si yẹ kawọn ọba alaye gbogbo ṣatilẹyin fun.

Ọba alaye yii sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ lori bi Sunday Igboho, ṣe wa si ilẹ Yewa, nitori bawọn Fulani darandaran ọhun ṣe n ṣe awọn eeyan to n gbe ni agbegbe ọhun lati bi ọdun meloo sẹyin.

O sọ pe ọdun yii lo pe ọdun kẹrindinlogun toun tijọba niluu naa ṣugbọn tawọn Fulani ọhun ko jẹ ki wọn gbadun paapaa julọ awọn agbẹ, bo tilẹ jẹ pe o sọ pe kii ṣe gbogbo awọn Fulani o, o ni awọn to ti n bawọn gbe nipinlẹ Ogun, awọn yẹn ko fa wahala ṣugbọn awọn ti wọn wa lati orileede Niger,ti wọn pe ni Bororo lo n da wahala silẹ.

Ọba Iṣelu ṣe apẹẹrẹ pe obinrin kan wa niluu oun tawọn Bororo yii ba sun loju ọkọ ẹ lẹnu ọjọ mẹta yii pẹlu ibọn ni ọwọ wọn. O ni o ti wa di ẹdun ọkan tawọn araalu ti wọn ko fẹẹ ṣe suuru mọ, awọn ọba ko si mọ ipẹ tawọn yoo ṣe faraalu mọ.

O tun ṣalaye pe ‘’ O yẹ kijọba tete gbe igbesẹ ki wọn fopin si, ṣe ẹ mọ pe ijọba taa wa yii mo ro pe boya wọn si n ro ọna taa fẹẹ gbe gbaa ni.Sẹ ẹ mọ pe ọrọ Fulani, ọrọ to gba suuru ni, nigba ti Akeredolu sọ tiẹ o fẹẹ di wahala.Ẹni to ba mọ iru eeyan ti Gomina jẹ, kii ṣe ẹni to tete maa n gbe igbesẹ, o maa n ro lọ sọtun atosi, emi nigbagbọ pe ibi tọrọ de, wọn gbọdọ ṣe nnkan si’’

O fikun ọrọ ẹ pe Sunday igboho de ọdọ awọn ni Iṣelu lakooko to fi wa si Yewa, tawọn si jọ sọrọ, ko to di pe o kuro lọdọ oun.O ni gbogbo nnkan to n so ni ija ajijagbara fun gbogbo ọmọ Yoruba. O ni kii ṣe ọkunrin yii nikan lo n ja ija ọhun.

Lara awọn to sọ pe wọn tun ja ni Gani Adams to jẹ Aarẹ ọna kankafo, o ni o ti ja ija yẹn tẹle. O ni Sunday Igboho ti gbakoso lati bẹrẹ ibi to baa de,o ni oun wa pẹlu gbogbo awọn to n ja fun ẹtọ Yoruba.Gbogbo ara loun fi wa ba wọn lo, nitori awọn ii ṣe ẹru Fulani.

O ni idi ni pe ni gbogbo agbegbe oun tawọn Fulani yii ba ti bẹrẹ wahala wọn,awọn ọmọleewe kii lọ ileewe wọn,bo ṣe ni wọn pa ọmọde ni wọn pa agba, ti wọn n gba oko, gbogbo agbado awọn agbẹ awọn ni wọn ti jẹ tan, wọn a ni ki maalu awọn le ni okun.

Ọba naa sọ pe ‘’Nnkan to n ṣẹlẹ yii ko ṣe farada mọ, bigba ti alejo ba n ko onile lẹru ni,idọti nla  ni, nigba tijọba ko si tii ji ti wọn sun lọwọ,igbra ẹni silẹ, wa ninu ofin Naijiria, onikaluku ni lati duro ja fun ẹmi ẹ, atawọn dukia taa ni, nitori idi eyi, emi fi taratara ba Sunday Igboho lọ.’’

Lori awọn ọba alaye ilẹ Yoruba kan ti wọn ni wọn ko ṣatilẹyin lori ohun ti Sunday Igboho ṣe, Oba Iṣelu tun sọ pe ‘’ Ilẹ lo maa n beere lọwọ ọdalẹ,ilẹ lo maa n dajọ ọdalẹ,ẹni to ba tori owo to ba dalẹ Yoruba, ilẹ lo maa dajọ, nitori ilẹ latijẹ, ibẹ naa latimu, atọba, atijoye ataraalu ilu la n tẹ, ilẹ ni yoo dajọ.ẹni to ba dalẹ Yoruba ilẹ a mu, ẹ jẹ kawọn to n ṣe rere maa ṣe lọ, awọn to n ṣe ibi ko maa ṣe niso,ọjọ kan bayii, ilẹ a mọ, a ri oju gbogbo aṣebi’’

O ni oun ti gbadura fun Sunday Igboho pe ko si nnkan to maa ṣee, nitori kii ṣe apo ara ẹ lo n ja fun, ominira ilẹ Yoruba ka maa di ẹru lo n ja fun, a o gbọdọ di ẹru eewọ ni.

O wa pari ọrọ ẹ pe oun naa fọwọ si pe ki awọn Fulani ti ko dara, ti wọn paayan, ti wọn ba oko oloko jẹ, ti wọn fipa ba awọn obinrin sun fi ilẹ Yoruba silẹ.  

 

 

No comments:

Post a Comment

Pages