Olusọla Adewusi, Ajagungbade ilu Itori, to jẹ alakoso ẹgbẹ ọdọ ilẹ Yoruba, iyẹn YYF, ti rọ gbogbo awọn Fulani darandaran ti wọn fi maaluu wọn da wahala silẹ lawọn ilẹ Yoruba, ti wọn pawọn eeyan nipakupa, ti wọn si tun ji awọn eeyan gbe lati dẹkun iwa yii, nitori bi ẹni pe wọn fẹẹ fi da wahala silẹ ni.
Ọkunrin yii sọrọ ninu atẹjade to fi sita, o ni gbogbo iwa
tawọn Fulani darandaran yii n hu lati bi ọdun meloo kan sẹyin nilẹ Yoruba, kii ṣe
nnkan to bojumu, ki wọn ya tete kọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ.
Ajagungbade naa tun fikun ninu ọrọ ẹ pe ibanujẹ lo jẹ fawọn
tawọn ba gbọ bawọn Funlani yii ṣe n fi maaluu wọn ba ere oko wọn jẹ nilẹ
Yoruba, ti wọn ko si bikita rara.
O ni nipinlẹ Ogun nibi, iwa buruku lawọn Fulani yii n hu
lawọn ibi kan, aimọye agbẹ ni wọn ti gbẹmi ẹ ninu oko, aimoyẹ wọn ni ti ji gbe,
o wa ni akoko ti wa to lati jawọ ninu awọn iwa buruu yii.
Bakan naa lo tun lo akoko yii lati kilọ fawọn ọdọ ilẹ
Yoruba lati ye ṣe idajọ ọwọ ara wọn fawọn Fulani tọwọ wọn ba tẹ,o ni ki wọn bọwọ
fun ofin, ki wọn maa sa fawọn nnkan to le da wahala silẹ.
Ajagungbade sọ pe loootọ ati lododo ko si ọmọ Yoruba ti
nnkan ti Fulani ṣe tẹẹ lọrun, amọ sa, awọn ọdọ ni lati ṣe suuru, ki ẹni to ti jare
tẹlẹ ma ba wa jẹbi.
O wa gboriyin fun Gomina Dapọ Abiọdun fun ilakaka ẹ
lati rii pe eto abo fẹsẹ rinlẹ nipinlẹ Ogun,pẹlu idaniloju pe gbogbo nnkan yoo
maa lọ bo ṣe yẹ ati bo ṣe tọ.
Bakan naa lo tun ki awọn alaabo ilu lọkan-ọ-jọkan fun awọn
akitiyan wọn nipa abo awọn araalu, ki wọn ma ṣe dakẹ lati dẹkun iwa ibi tawọn
Fulani n hu nilẹ Yoruba.
No comments:
Post a Comment