Ẹnu ni Gani Adams fi ta Yoruba titi di oni, Ọlọrun lo gbe Sunday Igboho dide.- Rasak Arogundade - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 26 January 2021

Ẹnu ni Gani Adams fi ta Yoruba titi di oni, Ọlọrun lo gbe Sunday Igboho dide.- Rasak Arogundade

 


Lojumọ to mọ loni in, ko sẹni ti ko mọ ọkunrin ajijagbara ninu ẹgbẹ OPC, ti wọn n pe ni Rasak Arogundade, tọpọ mọ si Saddam, ẹyin Gani Adams, to ti di Aarẹ ọna Kankafo lo wa tẹlẹ, ko to di pe o pinya pẹlu ọkunrin naa, to si jẹ aarẹ fẹgbẹ OPC New Era.

Laipẹ yii lo gba oniroyin wa, JOHNSON AKINPẸLU, lalejo ni ọfiisi ẹ, nibi to ti sọ idi to fi wa lẹyin Sunday Igboho atawọn nnkan to da wahala silẹ laaarin oun ati Gani Adams. Ohun to ba wa sọ ree.

Ipa tẹgbẹ OPC ko lori wahala ti Fulani da silẹ nilẹ Yoruba.

A tI kopa oriṣiriṣi,bi ẹ ko ba gbagbe, ko to di pe Fulani bẹrẹ si nii pawọn nipakupa, ko to di pe wọn bẹrẹ si nii ji eeyan gbe, ni awa OPC ti n pariwo tipẹtipẹ, la ti n sọ igbesẹ tawọn eeyan yii n gbe lati ṣe nilẹ Yoruba.

Bi mi o ba ni ṣe aṣiṣe lati ọdun 1999, ni a ti n pariwo. Ṣugbọn ko ye ọpọ awọn eeyan, ohun ti wọn n ro ni pe OPC, a fẹẹ da ẹlẹyamẹya silẹ, wọn ni a mọn ọn mọ fẹẹ da ogun silẹ ni.

Bi ẹ ba wa wo nnkan to n ṣẹlẹ lakooko yii, ariwo taa n pa lati bi ogun ọdun ṣẹṣẹ wa n ye awọn ọmọ Yoruba ni.Lara iya taa jẹ nigba naa lọhun ni ti Aarẹ wa nigba naa, Oluṣẹgun Ọbasanjọ, to sọ pe OPC fẹẹ ma da ija ẹlẹyamẹya silẹ. A  fẹ maa daluru, igba naa lo fi ni adaluru ni wa, ni wọn fi paṣẹ nigba naa lọhun pe ibikibi ti wọn ba ti ri wa, ki wọn maa pa wa.

Aimọye ọmọ wa ni wọn ko lọ si ọgba ẹwọn, aimọye ni wọn pa danu nigba naa lọhun.Inu mi wa dun lonii pe Baba funra ẹ ri pe gbogbo ọrọ ti OPC n sọ nigba naa lọhun, ootọ ni.

Idi niyii tawa OPC ṣe sun sẹgbẹ kan naa pe kinni yii, maa ye ọpọ awọn eeyan. Yoruba maa n sọ pe oponu eeyan lo n gbeja ilu, nitori nigba taa fẹẹ ma gbeja ilu nigba naa, wọn mu wa gẹgẹ bi oponu.

Ẹyin Sunday Igboho ni mo wa lori ijangbara lati bọ lọwọ awọn Fulani

Gẹgẹ bi igbesẹ ti Sunday Igboho wa gbe bayii, inu mi dun pupọ. Ṣe ẹ ri igbagbe lo ṣe awa kan, kii ṣe gbogbo Aafa lo maa tan kalẹ Islam, kii ṣe gbogbo pasitọ naa lo maa tan kalẹ kristẹẹni.

Ọpọ awa taa jẹ ajijagbara la maa tan ilẹ Yoruba tan, Sunday Igboho, kii ṣe ko si ninu ajijagbara, oniṣowo nla ni. Ṣugbọn Ọlọrun ti wa sọ pe itara agidi to ni, to tun wa jẹ ọmọ Yoruba atata, ila lo wa ẹẹkẹ yẹn, iru emi ti omo jokoo, mi o kọla si ẹẹkẹ.

Wọn le maa beeere pe ọmọ ilu wo ni mi, ko sẹni to le beeere pe ọmọ ilu bo ni Sunday Igboho.Ila Ọyọ lo wa loju ẹ. A o ranti pe igba ti ija Afonja yoo bẹrẹ nigba naa, Igboho lo ti bẹrẹ Sunday yii lo wa tun jẹ ọmọ Igboho.

Anu ṣe mi bijọba kan ba sọ pe awọn fẹẹ koju ẹ, awọn alaalẹ lo gbe Igboho dide o, awọn ogun ti baba baba ẹ ja ku, ni wọn tun fẹẹ tara ẹ ja bayii o.

Ohun to n gbenu Sunday Igboho, o ju nnkan tawọn kan le fojudi di, o ju nnkan ti Aarẹ ọna Kankafo le foju tẹmbẹlu. Ki Aarẹ ya lọ jokoo ara ẹ jẹ,ko gba fun Ọlọrun pe olugbala Yoruba lo de yii.

Ki o gba fun Ọlọrun pe ẹni ti Ọlọrun ba ti yan, o ti yan an ni,ibi ti Ọlọrun sọ pe o fẹẹ ba iṣẹ tiẹ de lo ti ba de yẹn. Aigbọran lo n daa laamu, ko si ni arojinlẹ.

Ẹnikan kii jẹ awade, gbogbo eeyan lo n jẹ jan an mọ, to ba sọ pe o ti rẹ ẹ, ẹlomii in a tẹwọgbaa, nigba to rẹ Mose ninu Bibeli Joṣua lo tẹwọ gbaa.

Igbagbọ mi ni pe gbogbo awa taa jẹ ajijagbara, a gbọdọ fọwọsowọpọ pẹlu Sunday Igboho, O ṣaaju ni, awa naa ni lati tẹle, ẹnikan sọ pe wọn ni Aarẹ ni Sunday igboho n pariwo o n ṣe laulau, ni temi, ọna to fẹẹ gba ṣe ajijagbara tiẹ niyẹn.Ohun taa n fẹẹ ni pe ki Yoruba ti bọ kuro loko inira.

Ki nnkan to waye lọdun 1816, laye Afọja ati Alimi, ko ma tun ṣẹlẹ.Bi ẹyin naa ba woo, gbogbo ilẹ Ibarapa, awọn Fulani lo n paṣẹ nibẹ. Mo gbọ pe nigba ti wọn ji Ọmọọba Igangan, wọn ni Ṣeriki lo jẹ alarina to dunadura laarin ọba naa atawọn to ji ọmọ naa gbe.

Bi wọn ba sọra ọjọ kan ni wọn yoo pa ọba ilu naa, ti wọn yoo yan Ṣeriki.Gbogbo nnkan ti Sunday n ṣe, ni mo satilẹyin ẹ, nitori ẹ ni mo ṣe sọ fawọn ọmọ mi to wa ni agbegbe naa pe ki wọn tu jade, ki wọn ṣatilẹyin fun un, bo ba si jẹ ogun, ki wọn maa ja niso.

Bi a ko ba sọra Imurasilẹ ogun leleyii oo

Gẹgẹ bi asọtẹlẹ awọn to raye, to ri ọrun, wọn sọ pe ko si nnkan to n jẹ Nigeria nigba to ba fi di ọdun 2023, wọn si sọ pe Buhari lo maa jọ aarẹ to gbẹyin, o ṣee ṣe ko jẹ pe nnkan to n ṣẹlẹ niyẹn.

Ẹ jẹ ki a maa murasilẹ, nitori Ọlọrun ọba kii ṣe ọba alabosi, nigba ti Alimi ba akoso Ilọrin lọdun 1816, gbogbo erongba wọn lati gba akoso gbogbo ilẹ Yoruba, awọn alaalẹ ti wọn ko gba fun nigba naa, wọn ko nii gba fun lọtẹ yii.

Ṣebi Yoruba wa ni North ọjọ wo lẹ gbọ pe wọn da wahala silẹ nibẹ, o ṣe wa jẹ awọn gan an ni wọn wa da wahala silẹ nibi bayii.Ki onikaluku duro silu ẹ. Awọn ti wọn wa lẹyin Sunday Igboho taa sọrọ rara, gẹgẹ bi emi naa, jagunjagun ni wa.

Wọn ko le ya bi ogun ṣe maa waye silẹ ki n sa sẹyin.Mo mọ pe ẹẹkan lọmọkunrin n ku, ẹni to wa ninu mọto o n ku,,ẹni to wa ninu ile ẹ naa ku, ambọsibọsi ẹni to lakikanju lori awọn eeyan ẹ.

Ẹni tawa n reti tẹlẹtẹlẹ ko ṣaaju wa iyẹn aarẹ ọna kankafo ko ṣee, wọn  ni mo n sọrọ tako o, bawo ni mo ṣe le sọrọ takoo.nitootọ bi ewe ba pẹ lara ọṣẹ o dọṣẹ ni.

Baba to bi Baba Gani Adams ilẹ Yoruba ni wọn ti tọ, baba to bi oun naa, ilẹ yii naa ni wọn ti tọ, awa ni sọ pe kii ṣe ọmọ Yoruba mọ.Amọ igbesẹ to n gbe o fẹẹ ma sọ pe a bi oun kii sọmọ Yoruba, emi o mọ ki wọn feeyan joye awodi, ko ma le gbe adiẹ.

Akinkanju niran aarẹ ọna kankafo, ko si si ninu itan wọn, wọn maa n ja fitafita fun iran Yoruba ni,o ṣee ṣe  wọn maa ku sogun ni, eyi ti Abiọla ku si, nitori ijọba dẹmọkireesi ni, oun laa si n jẹ di oni yii.

Ki lo wa de toun joye aarẹ to n sa fogun, to ni ti igbalode loun jẹ.ko ba ma ti gboye yẹn, ki wọn gbe fẹni to tọ.Aarẹ ona kankafo kii sọrọ ka kan jokoo ka pe awọn oniroyin jọ, ka maa parọ oriṣiriṣii.

Ohun ti Yoruba sọ ni pe ẹ sinmi ariwo ti ko nitumọ, ẹ bọ soju ogun ki ẹ jagun, gbogbo awọn to yẹ ki wọn yi yin ka, lo ti fẹnu ba jẹ, to ti fẹnu ṣaata wọn.

Lọjọ ori ọpọ wa lo ju ẹ lọ, ṣugbọn nigba ti wọn ti fi ẹ di Aarẹ ọna kankafo,o yẹ ko pe gbogbo wa jọ, ka pe gbogbo awọn agbaagba, ka gbagbe ikusinu,, ka kọju mọ nnkan to n ṣẹlẹ.

Ẹni ba jẹ ọmọ ale ninu wa, a bogun lọ ni ko nii wale.Eeyan kii wa nipo ootọ ko ku sipo ika lailai.Ki Gani sinmi ọtẹ, ko sinmi afemi, afemi, ibi to ba ti n sọ pe afemi, ẹlomii in, a dide.

Ọlọrun lo gbe Sunday Igboho dide, nitori gbogbo nnkan taa n fọgbọn ṣe, oun lo kuku laa mọlẹ. Eyi tawọn aṣaaju wa sọ pe ko kan awọn ti wọn pariwo 2023, boya awọn la kọkọ maa fi paroko si Buhari.

Kawọn funra wọn ranti pe ile lati n ko ẹsọ rode, ki wọn ranti pe ti wọn ba kuro ni Abuja, ile ni wọn n pada bọ.Nigba tẹẹ ba da nile bawo lẹ ṣe fẹẹ ri ni Aso –Rock.

 

Idi taa fi da OPC New Era silẹ.

Awọn alagbada nigba naa, lakooko yẹn OPC ko satilẹyin fun wọn, nitori a n roo pe oko ẹru naa ni, awa roo pe ki lo de ti wọn ko jẹ ka jokoo, ki wọn satunto ọrọ Naijiria nigba naa, ki ọlọmu le gbọmu iya ẹ, ohun taa duro le lori nigba naa niyẹn.

Awa ri pe olori wa nigba naa lọhun Fredrick Fasheun, wọn faramọ oṣelu, wọn ko fẹ tẹle ilana wa mọ,,idi niyii ta fi ni ki Gani Adams ṣaaju wa, lati jẹ ki Baba mọ pe awa o fẹ nnkan ti wọn ṣe.

Idi niyii tawa kan fi pinya lẹyin Fasheun. Gani Adams ni alakoso nigba naa, ọjọ ori kọ la n wo, bo ba ṣe kọkọ wọnu ẹgbẹ si ni.A tun rii pe oun tun sunmọ Baba ju awa lọ.

O tiẹ sọ pe ẹmi oun ko gbe awa la fi lọkanbalẹ pe ko ṣewu, awa lẹyin ẹ. Nigba to di 2015, taa ri ọwọ ti Gani gbe, nitootọ awọn agba Yoruba pe wa jọ, wọn jẹ ka mọ pe ọmọ wa ni igbakeji aarẹ Yẹmi Oṣinbajo, ki lo de  taa fun ni oore-ọfẹ fun gbogbo nnkan taa ba beere fun, awọn yoo fun wa.

Ki lo wa de to jẹ pe PDP ni Gani Adams maa gba lọ, awa roo pe ẹni ti wọn fa kalẹ nibẹ, ẹni to jẹ aarẹ wọn Fulani ni, igbakeji ẹ Ibo ni, nibo wa ni Yoruba fẹẹ duro le lori.

Awọn agbaagba ni ka fun Ọṣinbajo ni tikẹẹti, awa sọ fun Gani pe Fulani to ni ka tẹle, a ko le ri nnkankan gba, lo ba sọ pe rara ko si nnkan to jọ, awa rii pe owo to n gba latọdọ wọn lo dii loju.

Ara idi tawa kan fi piya niyẹn, nitori a rii pe o fẹẹ ta wa ni. Nigba taa fẹẹ ri aridaju ọrọ wa, a ni ki Gani ko wa sagbatẹru iwọde ni ọjọ kẹrindinlogun, osu kẹta, ọdun 2015, lati fi satilẹyin fun ipinlẹ Eko.

Awa rii pe gbogbo nnkan taa fẹ fi ṣatilẹyin lọjọ naa ni Gani Adams bajẹ. Ohun lo faa tawa kan fi gbe atẹjade kan sita pe awa ko nigbagbọ ninu ẹ mọ titi di akoko yii.

A tun ti wa lorukọ taa n jẹ nigba naa, a tun wa pe awọn agbaagba ki wọn pe Gani Adams sakiyesi, ki a ma ba jẹ ọmọọya awusa. Boya  ṣee ṣe ti wọn ba baa sọrọ ko gbọrọ si wọn lẹnu.

Gani ni ki wọn fi wa silẹ, a ko ju meloo kan lọ, ti Jonathan ba ti wọle gbogbo wa ni wọn yoo ko satimọle, awa naa wa tẹwọ adura pe ohun ti o fọkan si ma jẹ ko ri bẹ o, ma jẹ ki Jonathan wọle o.

Ọlorun si gba fun wa, ka ni Jonathan lo wọle, oun gan an ko ni mọ pe 410 ni Gani Adams, ẹnu lo n ta fun Yoruba titi di oni, titi ti Ọlọrun fi ni akoko to, to fi gbe Sunday Igboho dide.

Yoruba meloo lo fun Sunday Igboho lowo, gbogbo eyi to n ṣe owo apo ẹ lo na. Ẹ beere lọwọ ẹ pe owo to n gba, nibo lo ko si, ki lo fowo naa ṣe.Gbogbo wa la mọ miliọnu to gba lọwọ Jonathan, a mọ iṣẹ akanṣe to gba, nibo lo ko si.

Ṣe o n reti pe ki Yoruba foun lowo, ko to mọ pe o yẹ koun ja fun Yoruba.Ara nnkan taa fi da OPC New Era silẹ niyẹn, gbogbo nnkan ti ko da ti Gani Adams n ṣe to n ba wa loju jẹ lawa ṣe atunṣe ẹ.

Awọn iṣẹ taa ti ṣe ni OPC New Era

A ti ṣiṣẹ to pọ, ni nnkan bii oṣu kan sẹyin, emi fun ara mi mo lọ si Oke-Ogun lati lọ bawọn sọrọ, inu mi dun pe wọn gbọrọ si mi lẹnu , mo bawọn OPC to wa nibẹ sọrọ lati ṣatilẹyin fun Sunday Igboho.

Ara nnkan to fi jẹ kawọn OPC tu jade nigba to fi lọ si Igangan niyẹn.Mo gbọ ti wọn ni Gani sọ pe Sunday Igboho ko ni awọn ọmọ kankan lẹyin, ẹni ti ko ba ni eeyan a wa lati fi ṣatilẹyin fun un.

Nnkan to yẹ kawa ṣe ta o ṣe, loun ṣe yẹn, a si kọmọ fun un lati satilẹyin fun un. Aye ṣi wa fun lati fi tun ọmọluabi ẹ ṣe ko huwa bi ojulowo ọmọ Yoruba.

Ọrọ to wa nilẹ ti n di itiju fun Gani Adams

Ọrọ to wa nilẹ ti n di itiju fun wọn, awọn naa si ti n wa ọna lati ṣe atunṣe. Mo ri abọ ipade ti wọn ṣe, ti wọn ni kawọn kan maa tako Sunday, kawọn kan si maa tako Rasak Arogundade.

Aarẹ ko yẹ ko ṣe bẹẹ, nigba temi sọ nipa ẹ, ohun to faa lo faa, awọn nnkan to yẹ ki n ti sọ tipẹtipẹ ni , wọn ni ti akoko ọrọ ko ba to, eeyan kii sọ, mo ro pe nnkan to yẹ ko ṣe ni pe ko pe awọn oniroyin, ko  sọrọ lori nnkan ti mo sọ, ko sọ iran ẹ,  bo ṣe ni Arigidi.

Nnkan temi sọ ni pe Aarẹ ọna kankafo,Gani Adams, iran meji niran ẹ to wa ni Arigidi, Baba baba ẹ to rin wa si Arigidi,ọmọ Nupe ni.o niluu to n gbe tẹlẹ, o ṣe aṣemaṣe wa siluu naa ni Ẹpeni, ẹ ẹ lọ sibẹ, ki ẹ lọ beeere itan ti mo n sọ yii.

Wọn wa le kuro nibẹ, ni ọba Zaki Arigidi, ọba ana ni, kii ṣe ọba ijẹta,kii ṣe itan to jin rara, ọba yẹn lo gba si agbegbe inu afin ẹ, ẹni to ba si n gbe bẹ ẹru ọba ni. Oun lo fẹ ọmọ ilu Arigidi fun Adamu, ni Adamu yẹn fi bi Lamidi, Lamidi wa bi Adamu. Ko ju bẹẹ lọ. To ba jẹ pe irọ ni ko sọrọ sita.

Awọn agbaagba ti ni ki n sinmi ki n ma sọrọ lori ẹ mọ, emi naa o si fẹẹ sọ nnkankan mọ, nitori ọrọ pọ lori ẹ rẹpẹtẹ.

Nitori toun ba roo pe oun le ba eeyan jẹ, ọmọ Isi-Ekiti ni emi, mo mọ ilu Baba ati iya mi. Ni Arigidi, ajeji lo n joye ọtunba nibẹ, ko tun lọ beere.

 

 

 

 

 

 

 

  

No comments:

Post a Comment

Pages