Oloṣelu to ba ti ko owo araalu jẹ, o yẹ ki wọn ma gbagbe ẹ sẹwọn ni- Ọnarebu Salvador. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 26 January 2021

Oloṣelu to ba ti ko owo araalu jẹ, o yẹ ki wọn ma gbagbe ẹ sẹwọn ni- Ọnarebu Salvador.

 


Ọnarebu Moshood Adegoke Salvador, to jẹ agba oṣelu ninu ẹgbẹ APC, nipinlẹ Eko, ti sọ pe akoko ti to  fawọn eyikeyi jẹgudu-jẹra ninu oṣelu tọwọ ba tẹ lati maa jiya lori iwa ibajẹ ṣiṣe owo ilu baṣubasu lakooko ti wọn ṣejọba.

Ọkunrin naa sọrọ yii nibi apilẹkọ  to ka nibi idanilẹkọọ kan to waye, eyi tawọn akọrọyin Federated Chapel, sagbatẹru ẹ, eyi to waye ni gbọngan Oluṣẹgun Ọbasanjọ, niluu Abẹokuta.

Agba oṣelu ọhun ṣalaye pe ẹdun ọkan lo n jẹ bawọn jẹgudu jẹra ninu oṣelu ṣe n ṣowo ilu ti pa orileede yii to si jẹ pe ẹni tọwọ ba tẹ pe o kowo araalu jẹ to ba ti foju  bale ẹjọ, ko yẹ ki wọn maa fun un laye lati gba oniduro kankan bi bẹẹ kọ, ọgba ẹwọn lo yẹ ki wọn maa gbagbe iru wọn si.

O wa fikun ọrọ ẹ pe ko yẹ kijọba maa fọwọ yẹpẹrẹ mu iru awọn eeyan bẹẹ nitori idọti niri awọn eeyan bẹẹ mu ba wa lorileede yii. Bakan ni ọkunrin yii tun tako aba ijọba apapọ lorileede yii lori bi wọn ṣe n gbidanwo lati na owo to to biliọnu meje naira lati fi ṣe atẹgun ida ẹmi pada sawọn aye mejidinlogoji kaakiri orileede yii.

Salvador to ṣapejuwe owo ida ẹmi pada naa gẹgẹ bi owo nla ti wọn ba fi we ti orileede Amẹrika, o ni kii ṣe tọrọ ẹnu orileede wa ko lagbara ẹ lakooko yii ti ọrọ aje wa n dẹnukọlẹ,.O ni kii ṣe akoko yii lo yẹ ka maa na inakuna, nitori gbogbo nnkan lo ti n dẹnukọlẹ.

Bẹẹ lọkunrin tawọn akọrọyin naa tun fi jẹ Baba Isalẹ wọn patapata tun sọ pe ti wọn ba pin owo to to biliọnu mẹjo ti wọn fẹẹ naa sawọn agbegbe mejidinlogoji ti wọn sọ yii, iye kọọkan ti wọn kọ yoo fẹẹ to milionu lọna ọgọjọ naia, eyi to sọ pe o kọja tilẹ Amẹrika ati London.

O ni pẹlu iwadii tawọn ti ṣe o ni miliọnu mẹtalelogun nilẹ Amẹrika naa nigba ti ti London jẹ miliọnu mtindinlọgbon, ati ẹgbẹrun meje naira. O wa rọ ijọba apapọ ki wọn mọ bi wọn yoo ṣe sọ owo na.

Nibi idanilẹkoo naa ni wọn tun ti fawọn eeyan lami ẹyẹ, lara wọn, Olori ile igbimọ aṣofin ni Eko, Mudaṣiru Ọbasa, Alaaji Tiwalade Akigbade, to jẹ akọwe fẹgbẹ awọn roodu nipinlẹ Ogun, Oloye Sunday Adeyẹmọ, tọpọ mo si Sunday Igboho atawọn eeyan pataki mii in.

No comments:

Post a Comment

Pages