Ere Asalatu ni ki Makinde gbawọn Ibarapa/Oke-Ogun lọwọ awọn Fulani darandaran - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 22 January 2021

Ere Asalatu ni ki Makinde gbawọn Ibarapa/Oke-Ogun lọwọ awọn Fulani darandaranGbajumọ olorin ẹsin Islam nni, Alaaji Abdul-Kabir Bukọla Alayande tọpọ awọn eeyan mọ si Ere Asalatu, ti rọ Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde, lati gbawọn eeyan Ibarapa si Oke-Ogun to wa labẹ ipinlẹ ọhun, lọwọ bawọn Fulani darandaran ṣe doju ija kọ wọn, ti wọn si n pawọn nipakupa ti wọn tun ji wọn gbe pẹlu..

 Ọkunrin naa sọrọ yii ninu atẹjade kan to fọwọ si, lo tun rọ Gomina yii lati ma ṣe jẹ kawọn Fulani naa, ti wọn ti n kọwọ iwa ibi wọn bọlẹ latigba ti Sunday Igboho ti fun wọn lọjọ meje lati fi agbegbe ọhun silẹ lori awọn iṣe ibi wọn, sọ ilẹ Ibarapa/Oke-Ogun dahoro tan, nitori inu fu, aya fu lawọn eeyan yii gbe titi di akoko yii.

 Ọkunrin olorin Islam ọhun to tun jẹ ọmọ bibi ilu Isẹyin tun fi ye wa pe lẹyin ti Sunday Igboho, ti fawọn Fulani darandaran ọhun ni lọjọ meje lati palẹ ẹru wọn mọ ni agbegbe yii ni ko ti dun mọ ijọba ipinlẹ Ogun.

 O ni Sunday Igboho, to jẹ ọkan lara ọmọ Igboho lara ilu to wa labẹ Ibarapa/Oke-Ogun nijọba ibilẹ Oorelope, o ni ṣe ko ni agbara lati ṣe bẹẹ ni, to fi jẹ pe titi di akoko yii ni awyewuye fi n waye laaarin awọn mẹjẹji.

 Alayande wa  ni gẹgẹ boun ṣe jẹ ọmọ bibi ilu Isẹyin labẹ Ibarapa/Oke-Ogun, oun rọ Gomina Makinde lati gbawọn eeyan lọwọ idojukọ awọn darandaran yii.

O tun ṣalaye pe gẹgẹ bi ọkan to ni mọlẹbi ti wọn n gbe niIbarapa/Oke-Ogun, ko tii ju to n ba rawọ ẹbẹ si Gomina lati gbawọn eeyan kuro ninu ewu, ni gbogbo ọna to ba yẹ.

 O wa pari ọrọ ẹ pe ko sẹn tinu ẹ yoo dun, bi wọn ba ji tabi pa ọmọ, tabi ẹ ẹbi kan sọwọ awọn darandaran yii, o tun ni ta ni inu ẹ yoo dun bi wọn ba ba ere oko e ẹ jẹ. nitori ẹ lawọn ṣe bẹ Makinde lati tete wa nnkan ṣe sọrọ yii.

 

 

No comments:

Post a Comment

Pages