Wọn ni wọn fẹẹ ko janduku lọ bawọn ọdọ to n ṣe iwọde n’Ijẹbu Igbo lori bi tirela Dangote ṣe n pawọn nipakupa. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 10 January 2021

Wọn ni wọn fẹẹ ko janduku lọ bawọn ọdọ to n ṣe iwọde n’Ijẹbu Igbo lori bi tirela Dangote ṣe n pawọn nipakupa.

 

 


Lati ọjọ Ẹti, Furaide, lawọn ọdọ niluu Ijẹbu Igbo, nipinlẹ Ogun, ti tu sita ti wọn n fi ehonu wọn han lori bi wọn ṣẹ ni tirela Dangote ṣe n pa awọn eeyan wọn nipakupa.

Agbegbe kan ti wọn pe ni Alaafia, Sọpin, lọna Ọsun lawọn ọdọ naa ti ko rawọn jọ, ti wọn si sọ faraye pe iwa ọdaju ti Ileeṣẹ Dangote hu sawọn ti to gẹ, awọn fẹẹ ki wọn wa tọwọ bọwe adehun mii in, nitori eyi ti wọn ṣe pẹlu wọn tẹlẹ, ko mu idagbasoke ba ilu naa lapapọ.

Bo tilẹ jẹ pe nnkan taa n gbọ bayii ni pe wọn lawọn alagbara kan ti fẹẹ ko awọn tọọgi lati lọ le awọn ọdọ naa kuro nibi iwọde wọrọwọ ti wọn n ṣe ọhun.

Wọn ni inu awọn eeyan yii ko dun si iwọde ti wọn lawọn ọdọ  naa n ṣe, nitori owo ti wọn ni wọn gba loṣooṣu lọwọ ileeṣẹ Dangote, inu ifoya si nu wọn sọ pe awọn to n ṣe iwọde naa wa bayii.

Ninu ọrọ  Adesanya Arowolo Ṣakirudeen, to jẹ aarẹ apapọ ọdọ Ijẹbu Igbo, taa mọ si Congress of Ijẹbu Igbo Youth. O ni pataki ehonu tawọn n ṣe ni lati jẹ karaye mọ bi Ileeṣẹ Dangote, ṣe n pa awọn eeyan wọn nipakupa. Ati  pe ọna ti wọn gba fi ṣiṣẹ nijẹbu Igbo, ko ba ofin mu.

O ni ‘’Loootọ ni wọn niwe adehun ti wọn pe ni MOU wa ti wọn ṣe. Ṣugbọn awọn ti wọn ṣe pẹlu ẹ jẹ awọn kan ti wọn ko ara wọn jọ ni ọna to jẹ pe apo ara wọn nikan ni, ti ko ni anfaani ọmọ Ijebu Igbo kankan nibẹ, wọn ko sọrọ nipa bawo ni ọna ti wọn gba lọ ṣiṣẹ wọn, ti wọn gba ni gbogbo igba, bawo ni wọn yoo ṣe ṣe ti yoo fi wa lọna to tọ ati eyi to yẹ’’.

O ni osu karun un, ọdun yii lọdun marun un, ti wọn kọwọ bọwe yoo to pari, awọn si mọ pe wọn yoo ti maa mura silẹ lati ṣe ọdun marun un keji. O ni eyi ti wọn ṣe lọdun marun un akọkọ yẹn, ibanujẹ lo jẹ fun gbogbo ọmọ ijẹbu Igbo.

Nitori o ni ko si nnkankan to wa ninu iwe adehun yẹn to sọ nipa idagbasoke Ijẹbu-Igbo, bẹẹ ni ko sọ nipa ọna, ilera awọn eeyan, gbogbo idọti tawọn eeyan jẹ lojoojumọ, laduugbo gbogbo lawọn mọ pe ko dara.

O tun ṣalaye pe “Wọn ko ni agbekalẹ kankan lori aarun tawọn eeyan n ko nipasẹ idọti naa. O jẹ ọna akọkọ taa mọ pe iwe adehun naa ko ni nnkan ṣe pẹlu awa araalu.

‘’Ọna taa  n lo lati aye Baba Awolọwọ, taa n maneji, awọn tirela Dangote ti ba ọna naa jẹ.Gbogbo awọn eeyan wa ni Ijẹbu Igbo ti wọn jẹ agbẹ, nitori iṣẹ yii la yan laayo ni Ijẹbu Igbo lo jẹ pe eruku ni lọna, ti wọn ba n lọ, ti wọn ba n bọ.

‘’Ko si ohun idagbasoke kankan nibi, ko si ọsibitu, awọn agbalagba laarin wọn, arun ti ko to nnkan lo n pa wọn, ọdọ ilera wọn ko pe,iyẹn ko tẹ wa lọrun’’.

O ni awọn fẹẹ jẹ ki wọn wa tun adehun naa ṣe, ki gbogbo awọn to jẹ alẹnulọrọ, ti wọn ni ifẹ ilu naa, ki wọn jọ jokoo, lati jọ jiroro lati ni iwe apilẹkọ MOU, eyi ti yoo kapa gbogbo nnkan ti wọn sọ yii.

Bakan naa lo ni awọn ti gbe awọn igbesẹ kan ko to di pe awọn bẹrẹ ehonu naa lara ẹ ni lẹta to ni awọn ti ko ni aimọye igba, bẹẹ lawọn tun ti jọ ṣe ipade pọ, to jẹ pe gbogbo nnkan tawọn ba jọ sọ kuna, wọn ko nii ṣe nnkankan lee lori.

O fikun ọrọ ẹ pe awọn ṣe ipade kan pẹlu wọn ninu oṣu kẹjọ ọdun to kọja, to jẹ pe gbogbo awọn agbaagba wa lo wa nibẹ atawọn aṣoju wọn. Gbogbo adehun tawọn jọ ṣe pẹlu wọn, o ni wọn kan n fẹnu sọọ ni, wọn ko muu sẹ.

O wa pari ọrọ ẹ pe nnkan tawọn fẹẹ ni pe ki Dangote tabi awọn eeyan ẹ wa jokoo pẹlu awọn eeyan wa, kawọn jọ tun gbogbo ẹ ṣe lọna ti ko nii pa ilu tabi ileeṣẹ naa lara.

Ninu ọrọ ti Ọnarebu Sẹfiu Ogunlẹyẹ, o sọ pe ohun to n ṣẹlẹ yii awọn ti n reti ẹ tipẹ, nitori awọn aṣaaju wọn ti ja wọn kulẹ ninu ilu naa. Awon wa ro pe tawọn ko ba tete gbe igbesẹ, iya yii yoo tubọ maa jẹ awọn ọdọ n bọ lọjọ iwaju ni.

O ni ero ọkan wọn ni pe tileeṣẹ kan ba wa sinu ilu, ilu naa maa n dun ni. Awọn gba ileeṣẹ Dangote laaye, ni ero pe ilu yii yoo maa tẹsiwaju ni ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe gbogbo nnkan tawọn reti, ijakulẹ lawọn baa pade nibẹ.

Arabinrin Ọmọlọla Ọnasanya, sọ ni tiẹ pe “Gbogbo nnkan tawọn ileeṣẹ Dangote ṣe fun wa ko dun mọ wa ninu. Nitori gbogbo igba ni wọn ti fi tirela wọn paayan nibi, ti wọn ko ri nnkankan ṣe sii.Ti wọn ko ba ti fọwọ si nnkan taa n fẹ, awa naa ko fẹ wọn ni Ijẹbu Igbo mọ’’.

 

 

 

 

 

 

 

 

No comments:

Post a Comment

Pages