Lati ana,Ojọbọ, Tọsidee, ti iroyin ti gba igboro pe awọn kan lọ ja ile-igbimọ aṣofin, ti wọn si ji ọpa aṣẹ wọn gbe lo ti n ṣe awọn eeyan ni kayefi, ti wọn si n beeere lọwọ ara wọn pe bawo ni awọn ẹni-ibi naa ṣe raye rapala ji kinni ọhun gbe, ṣe ko si awọn alaabo to n sọ ibẹ ni?
Ile-
igbimọ aṣofin naa ti ko jinna pupọ si ofiisi gomina ni Oke-Mọsan, niluu
Abẹokuta ni wọn sọ pe won ti ji ọpa aṣẹ tawọn igbimọ maa n gbe saarin lakooko
ti wọn ba jokoo ipade wọn.
Ipa ti ọpa
aṣẹ naa n ko ki i ṣe kekere laaarin awọn aṣofin, ti ko ba si ti si kinni yii
nibẹ, ko si nnkan to n jẹ ofin, bi igba ti wọn ba jokoo lasan, ti wọn kan
fakoko ṣofo ni.
Ọpa yii ni
wọn sọ pe wọn ji gbe, ti ko si sẹni to le sọ pato bi nnkan ọhun ṣe ṣẹlẹ titi di
akoko yii, atawọn ti wọn wa ja, ati pe bi wọn ṣe ni wọn gori aja fi wọnu ọfiisi
olori ile igbimọ aṣofin, nibi ti wọn lo wa.
Bo tilẹ jẹ
pẹ ọpọ awọn aṣofin ti wọn kọkọ beeere ọrọ lẹnu wo ni wọn ko fẹ sọ pato pe loootọ
ni afigba tileeṣẹ awọn ọlọpaa nipinlẹ Ogun to jẹri si pe loootọ niṣẹlẹ naa waye
ati pe awọn ti n igbe igbesẹ lori ẹ.
Nigba naa
ni Kunle Oluọmọ, to jẹ olori ile- igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun, to wa jẹri si pe
wọn ja ọfiisi oun, wọn ji ọpa aṣẹ ọhun, ṣugbon o ni awọn ti ri ori ọpa naa
tawọn si wa yooku ẹ.
Ṣugbọn
iwadii wa labẹlẹ fi ye wa pe o dabi ẹni pe wahala n ṣẹlẹ laaarin awọn aṣofin
naa ati olori wọn. Bi kii ba ṣi ṣe pe wọn ko fẹ ko ara wọn sita bi ọjọ mẹjọ,
ariwo ko ba ti maa lọ nigboro.
Ohun taa
tun gbọ ni pe pẹlu nnkan to ṣẹlẹ a jẹ pe abo to peye ko si nile igbimọ naa,
nitori ka ni awọn ti wọn n ṣọ ibẹ ba mọ iṣẹ wọn niṣẹ ko si bawọn ọdaran ọhun
yoo ṣe wọ ọfiisi olori ile- igbimọ aṣofin, ki ẹnikẹni wọn maa mọ nipa ẹ.
Wọn ni afaimọ ko ma jẹ pe ejo lọwọ nu nnkan
to ṣẹlẹ yii ati pe aimọye nnkan to n waye amọ ti wọn ko fẹẹ sita, bi nnkan ṣe n
lọọ yii ko ma ṣe pe olori ile igbimọ aṣofin wọn gan an ni wọn fẹ maa ko sinu
wahala.
No comments:
Post a Comment