Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko ti wọn n ṣi ibi ẹrọ igbalode ọhun,
to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ana, nileeṣẹ wọn to wa labule Owu Dekudu, Kọbapẹ,
nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ Ogun, bakan naa ni wọn tun lo anfaani yii
lati fawọn oṣiṣẹ ọọdunrun ni igbega lati ipo kan si omii in.
Ọga agba ọhun ṣalaye idi ti
wọn fi gbe ẹkọ tuntun naa kalẹ lati tun le lo ọgbọn atinuda lọna igbalode lati
maa fi tu aṣiri iwa ọdaran lawujọ.
O sọ pe pẹlu akọsilẹ
tawọn ni ida ọgọrin (80%) to jẹ ọdaran lo
jẹ pe ori foonu lo ti n waye, ti wọn fi n lu awọn araalu ni jibiti. O wa ni ẹka
ti wọn ṣi lọjọ naa lo ti ṣetan lati maa lo imọ ẹrọ lati ṣewadii awọn nọmba
to ba hu iwa buruku ọhun lawujọ.
O wa mu dawọn eeyan loju pẹlu ileri pe ẹni
tọwọ ba tẹ lori ẹsun yii lawọn yoo fi jofin. Nitori pe ko sibi ti imọ ẹrọ
igbalode naa ko de kaakiri orileede yii ati oke okun ni.
Nibi eto ọhun naa ni wọn tun ti fi ami ẹyẹ
dawọn kan lọla, lara wọn ni Gomina Dapọ Abiọdun, ẹni ti akọwe ijọba Tokunbọ
Talabi, ṣoju fun.Edward Ajogun, toun jẹ kọmisanna fawọn ọlọpaa nipinlẹ Ogun,
atawọn eeyan mii in.
Nigba to n sọrọ lorukọ Gomina nibi eto ọhun, Ọgbẹni Tokunbọ
Talabi, fi idunnu ẹ han lori agbekalẹ imọ ẹrọ ti wọn ṣi lọjọ naa, eyi to ṣapejuwe
gẹgẹ bi ọna ti yoo mu iwa ọdaran dinku lawujọ,
O wa gba ajọ siifu nimọran
lati tan iru imọlẹ yii si awọn ẹka alaabo yooku to wa nipinlẹ Ogun, nitori iṣẹ ọpọlọ
ni. O wa gbadura ki Ọlọrun maa tubọ ran wọn lọwọ.
No comments:
Post a Comment