Ọgbẹni Tunde Ọladunjoye, akọwe oluponlongo fẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun,to tun jẹ alaga igbimọ alaṣẹ fun ileeṣẹ tẹlifiṣan OGTV, ti rọ gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Eko, Lagos East, lati fi ibo wọn gbe Ọgbeni Tokunbọ Abiru, wọle gẹgẹ bi sẹnetọ fun ẹkun naa.
O sọrọ yii lakooko to n bawọn oniroyin fọrọjomitoro
ọrọ niluu Ikorodu, nipinlẹ Eko, nigba to lọ sabẹwo atilẹyin ẹ han fun ọkunrin
naa, o ni ki gbogbo awọn eeyan naa jade sita lọjọ Abamẹta, Satide, yii ki wọn
si dibo wọn fun oludije wọn ọhun labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.
O ni nnkan to da oun loju ni pe Abiru ni ẹni naa to
kun oju oṣuwọn ju ninu gbogbo awọn oludije to jade fun ipo naa, oun si mọ pe ko
le ja awọn eeyan ẹ si tan an mọ to ba wọle.
Ọladunjoye tun fikun ọrọ ẹ pe eeyan ko le okunkun we
imọlẹ lailai bẹẹ ni wọn ko si le ṣafiwe oloju kan si oloju meji, ati pe wọn ko
tun le fi ẹni to nimọ iwe ju ẹni to sa kuro nileewe ti ko duro pari ẹkọ ẹ.
O ni ọlọpọlọ pipe ni Tokunbọ Abiru, yatọ gedegbe fawọn ti
wọn jẹwọ ara wọn pe awọn ko ṣetan
nileewe yunifasiti ki wọn to sa kuro nibẹ,nitori idi eyi lo ṣe rọ awọn oludibo
lati ma ṣe sọ ibo wọn ni lọjọ Abamẹta, Satide, to n bọ yii.
Ọkunrin naa tun sọ pe ‘’
Oludije ti saaju lati se agbedide lati ofo di nnkan to ni ere nipa ọrọ aje wa
nigba to n ṣiṣẹ ni banki Polaris, ti wọn si ni ere bii biliọnu mejilelogun
laarin oṣu mẹrinlelogun’’
O ni ẹkun Lagos East jẹ opo kan pataki fun ilọsiwaju, bẹẹ lo si
jẹ pe olidije wọn Abiru naa jẹ ogbontarigi ọmọ ẹgbẹ ilọsiwaju gẹgẹ bi baba ẹ
naa ṣe jẹ.
Ọladunjoye
wa sọ pe oun ko siyemeji rara ati o da oun loju pe ninu ibo to n bọ yii ẹgbẹ
oṣelu APC, ni yoo jawe olubori Ati pe Abiru to ti sa ipa loriṣiriṣi ni riro
awọn ọdọ atawọn obinrin lagbara ni yoo jawe olubori.
Alaga igbimọ fun ileeṣẹ tẹlifiṣan OGTV wa pari ọrọ ẹ pe lorukọ gbogbo eeyan ipinlẹ Ogun
labẹ Gomina Dapọ Abiọdun, atawọn oloye ẹgbẹ APC lapapọ loun mu ọrọ itunu naa
wa pẹlu adura pe nigba ti yoo ba fi di alẹ ọjọ Abamẹta, orin ọpẹ ni yoo gba ẹnu
wọn.
No comments:
Post a Comment