Ọga agba tuntun fajọ ẹṣọ aṣọbọde tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gbe wa si ipinlẹ Ogun,Peter Chado, ti kilọ fun gbogbo awọn to n kẹru ofin wọle taa mọ si fayawọ, pe ki wọn tete lọ jawọ nitori oun ko nii foju yẹpẹrẹ mu wọn tọwọ ba tẹ wọn.
Ọkunrin yii
sọrọ naa lakooko ti ẹni to ti jẹ ọga agba tẹlẹ nibẹ tẹlẹ Michael Agbara, gbe
akoso ileeṣẹ naa lee lọwọ, eyi to waye ni
ileeṣẹ wọn to wa ni ldiroko, nipinlẹ Ogun
O tun ṣalaye pe pẹlu
gbogbo awọn nnkan toun ti gbọ ati akitiyan ẹni to jẹ ọga agba naa tẹlẹ, oun yoo
ri pe awọn tẹsiwaju lati gbogun tawọn onifayawọ yii, ki wọn si lọ wa iṣẹ mii in
ṣe.
Peter Chado wa rọ awon ajọ ẹṣọ asọbode to wa lagbegbe naa lati
rii pe wọn jara mọsẹ wọn, ki wọn si fapẹẹrẹ
rere lelẹ, ki wọn si tun wa ni isọkan lọna ti wọn yoo fi bori awọn idojukọ ti
wọn koju lati ọdọ awọn onifayawọ.
O ni pẹlu eleyii awọn yoo ni akọsilẹ rere ju ti atẹyinwa lọ. Bẹẹ
lo tun ran wọn leti pe wọn gbọdọ maa pa ofin ati ilana ti wọn fi da ajọ naa
silẹ.
Ọga agba tuntun naa wa kesi awọn olori ẹka kọọkan atawọn
agbofinro to ku lati fọwọsowọpọ pẹlu oun koun le ṣaṣeyọri bi ẹni to ṣẹṣẹ fipo
naa silẹ.
O sọ pe “Gbogbo ẹyin tẹẹ wa lẹnu-odi orileede Naijiria,
ni nipinlẹ Ogun, to jẹ pe ẹ ko niṣẹ mii in ju fayawọ atawọn iṣẹ mii in ti ko ba
ofin mu ki ẹ tete lọ jawọ, nitori mi o ni faye gba yin rara''
Ninu ọrọ ti Michael Agbara, ẹni to ṣẹṣẹ
fipo naa silẹ nipinlẹ Ogun, dupẹ lọwọ gbogbo awọn ajọ ẹṣọ asọbode
ati gbogbo awọn agbofinro to wa lagbegbe naa to fi mọ awọn olori agbegbe fun
lfọwọsowọpọ wọn lasiko toun wa gẹgẹ bi ọga agba ajọ naa. O tun wa rọ wọn lati fọwọsowọpọ
pẹlu Peter Chado Kolo, to gbaṣẹ lọwọ ẹ ju bi wọn ṣe ṣe foun lọ.
No comments:
Post a Comment