Sẹnetọ Tolu Ọdẹbiyi,
to n ṣoju Ogun West nile igbimọ aṣofin niluu Abuja ti gboriyin fun ajọ to n ri
si ọgbin igbalode iyẹn National Centre for Agricultural Mechanisation (NCAM)
lori igbiyanju wọn lati da ileeṣẹ ọgbin igbalode ti yoo maa gbe irẹsi jade ni
Igbogila, nijọba ibilẹ Yewa North..
Ninu atẹjade ti wọn fi
sọwọ si wa ni wọn ti sọ pe ibi idasilẹ tuntun yii nireti wa pe awọn agbẹ ti wọn
jẹ ọdọ tabi awọn ti wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ iṣẹ agbẹ yoo ti ni anfaani lati maa kọ wọn
lori ọna bi wọn ṣe n gbin irẹsi lọna igbalode.
Bẹẹ naa lo tun gboṣuba
fun ẹka ijọba apapọ lori bi wọn ṣe forikori ti wọn si gbe akanṣe iṣẹ nla naa wa
si agbegbe ẹ. O wa fi da wọn loju pe Igbogila ti wọn gbe e wa yii kii ṣe ibi ti
wọn ti le kabamọ rara, nitori agbegbe naa dara pupọ fun nnkan ti wọn fẹẹ ṣe
naa, Bẹẹ si ni awọn ilẹ to si wa nibẹ jẹ afojusun to yoo mu eṣo rere jade.
Aṣofin Tolu Ọdẹbiyi,
to tun jẹ ọkan lara ọmọ igbimọ nipa eto ọgbin lawọn idagbasoke igberiko nile
igbimọ aṣofin, tun ṣalaye pe ẹkọṣẹ naa yoo tun pese iṣẹ fawọn to ba jẹ anfaani
naa.
Eyi to ni wọn yoo maa lo ọgbọn ti wọn ba ri kọ lakooko
naa lati maa pese irẹsi ilẹ, ti yoo si jẹ ki iṣoro to n koju ọrọ aje wa ko dinku
lawọn ipinlẹ ati lorileede yii lapapọ.
No comments:
Post a Comment