Rẹmi Bakare ki i ṣe olori ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ogun, o kere si nọmba- Bamgboṣe - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 25 November 2020

Rẹmi Bakare ki i ṣe olori ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ogun, o kere si nọmba- Bamgboṣe

 

 


Laipẹ yii ni iroyin gba igboro pe awọn kan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Ogun, ti ọdọ Oloogbe Buruji Kashamu, ti da Alagba Bamgboṣe Samson Olukayọde, alaga ẹgbẹ naa atawọn mẹfa mii in duro, ti wọn si darukọ Rẹmi Bakare, gẹgẹ bi olori ẹgbẹ naa tuntun.

Idi niyii taa fi wa alaga naa kan lati sọ bọrọ ṣe jẹ, Ọkunrin naa sọ pe titi di akoko yii oun si ni alaga ẹgbẹ  naa. Ẹ gbọ awọn ohun to tun ba wa sọ.

Emi ṣi ni alaga PDP nipinlẹ Ogun.

Mo fẹẹ fi da yin loju pe orukọ ti  mo n jẹ lọwọlọwọ ko tii pe, mo ṣẹṣẹ fẹ jẹ ki orukọ yẹn pe ni, nitori ti mi o ba fi eyi to ṣe pataki nibẹ si, ko tii pe iyẹn ni alaga PDP, nipinlẹ Ogun.

Lọwọlọwọ yii alaga PDP ko pe meji nipinlẹ Ogun,ọba kii pe meji laafin, ijoye le pe mẹta, ki Buruji to ku, ọga mi daadaa ni ki Ọlọrun ba mi fi ọrun kẹ, alaga ko pe meji ọkan ṣoṣo naa ni.

Ẹni to n ṣalaga mọ pe alaga loun, ẹni ti ko si ṣee, to n pe ara ẹ naa mọ pe oun kii salaga.Ki Buruji to ku, Bayọ Dayọ ni alaga wa tẹlẹ,nigba to ku diẹ ti yoo ku, lo kuro nibẹ, ti emi Bamgboṣe Oluwakayọde Samson jẹ alaga.

Iṣẹ si n lọ, a n dupẹ lọwọ Ọlọrun, a si nigbagbọ pe gbogbo awọn araalu fẹ ki awa PDP papọ, nitori iya yii n pọju.ki a yanju aawọ wa, ki a mọ nnkan taa n ṣe, labẹ isakoso Baba wa Gbenga Daniel.

Bi ẹ ba wa woo lọjọ taa bura fun mi ọrọ ti mo kọkọ sọ lọjọ naa ni pe lori temi yii ni gbogbo hilahilo ẹgbẹ oṣelu PDP yoo wọlẹ bamu.Ẹnu ẹ la wa yii, o ti n wọlẹ o, aa wọlẹ, ẹ o si ni gburo ẹ mọ.

Ọga wa sọ fun emi alaga ko to ku pe gbọ o, tawọn yooku ba wa ba ẹ fun ajọṣepọ, ẹẹ jokoo lati gbọ nnkan ti wọn fẹ sọ.Tọrọ yin ba ti n ye ara yin, ẹ jọ ṣe aṣepọ, o ti to gẹ.

Ohun to fi silẹ niyẹn ko to lọ, ki ẹnikan ba wa tun wa ifasẹyin to n sọ isọkusọ, irọ ni wọn n pa, nigba ti iku si ti muu lọ, a n wo ara wa ni, onikaluku ba iṣẹ ẹ lọ.

Ko pẹ ko jinna lọrọ aa ṣe olori, a o ṣe olori ba bẹrẹ,ọrọ yẹn le debi pe ẹ pe emi alaga pe ọrọ olori ẹgbẹ lo delẹ yii o, ki n pe ipade awọn oloye mi, ki n wa fa ọwọ soke pe lagbaja bayii ni olori ẹgbẹ tuntun.

Haa, wọn kii ṣe bẹẹ Ọlọrun lo ma yan olori,kii ṣe pe ẹnikan lo n yan olori. Ọlọrun maa n yan an ni, ko sẹni to fa ọwọ Buruji soke gẹgẹ bi olori, Ọlọrun lo yan an, awa bẹrẹ si ni ri akitiyan iṣẹ ọwọ ẹ.

Iṣẹ ọwọ ẹni lo n sọ ẹni di olori, mo jẹ ki wọn mọ pe emi Kayọde ko le bawọn ṣe iyẹn laye, iyẹn ni ipinlẹsẹ awuyewuye yẹn, ṣe ẹ si mọ ajura wa lọ ijakadi kọ, awọn kan wa ti wọn ba halẹ mọ wọn, wọn a maa gbọn.

Awọn kan wa to jẹ pe mi o gba, mi o gba ni, to ba ti jẹ ọna otiitọ.Wọn wa n wa ibi ti wọn fẹẹ so mọ lọtun losi, ko pẹ ẹ la bẹrẹ si ni gbọ, ni wọn ni wọn ti sọ fun wa pe awọn ti wọn ko ba jẹ tọdọ wa, bi a ba pade wọn nita, a o gbọdọ ki wọn. A o gbọdọ bawọn sọrọ paapaa awọn ti Ladi Adebutu.

Emi wa jẹ ki wọn mọ pe ọrọ ti oloogbe sọ pe tawọn eeyan yii ba wa ba wa, ka gbọ nnkan ti wọn ba fẹ sọ, nitori a ko le da ṣee, awọn naa ko le ṣee.

Awọn yẹn si ranṣẹ pada si wọn pe awa wa nile, ki wọn maa bọ. Ko pẹ ko jinna laaarọ kutu ni mo gbọ pe wọn ni wọn lọ ṣe ipade pọ pẹlu lọya, nigba to maa di irọlẹ ni wọn sọ abajade ipade wọn pe ki awọn oloye meje ninu awa mẹrinla taa n ṣe akoso ẹgbẹ pe ka lọ jokoo nile fun igba diẹ.

Ninu meje, emi wa nibẹ, igbakeji mi naa wa nibẹ,alaga gbogbo Ijẹbu, Ẹgba ati Yewa wa nibẹ, akapo ati oluṣiro owo naa wa nibẹ. Awọn ti wa gbagbe pe ni nnkan bi ọsẹ meji sẹyin, ni ẹsun wọn ti jade si awa lọwọ.

Bii ka pe ipade ki wọn ma wa, beeyan ko ba si wa ipade lẹẹmẹta, wọn ti lufin.  Ṣugbọn awa ro pe oloṣelu ni awa, a faye pe a le yanju ẹ laarin ara wa silẹ.

A tun ti jẹ ki wọn mọ pe ẹgbẹ ti wa ni ofin, ipade wọn nibẹ, ofo ni, ko ja si nnkankan. Ṣe ni wọn kan n fi ara wọn ṣe ẹlẹya kaakiri, lawa ba n wo wọn niran.

Awa mọ pe wọn n ta tẹtẹ ni amọ lọwọlọwọ yii awọn naa mọ pe oju awọn ti ja. Eto to wa nibẹ lati fi oju aje kan onisọ si n bọ laipẹ.

 

Nipa Sẹkiteriaati tawọn ti Ladi Adebutu gba l’Abẹokuta.

Ọlọrun a ran wa lọwọ lakọọkọ, ṣe ẹ ri Naijiria taa wa yii, Ọlọrun ko ni jẹ ko di Naijiria mọ wa lọwọ, emi kuro lọfiisi lọjọ ni kinni yẹn ṣẹlẹ, awọn ọmọ lo pe mi pe awọn ọlọpaa wa, mo ni ki wọn ma bawọn fa wahala, iyẹn kii ṣe tuntun iru ẹ ti waye bi ẹẹmeji ri.

Nigba to di ọjọ keji, a lọ bawọn, wọn lawọn ti pe wa lẹẹmeji pe ka wa, mo ni irọ ni, awa wa ni Ibadan, a si ni ki lọya wa kan wa pe ki lo de, wọn ni awọn kan kọ lẹta pe awọn ẹya keji lo yẹ ko wa ni ọfiisi, a ni rara o.

Lawọn ọlọpaa ba ni pe kin ni awa fẹẹ fi ṣe idaniloju pe wọn ko lẹtọọ, ni a ba ko gbogbo iwe idajọ to ki wa laya pe awa ni ofin sọ, ni a ba ko fun wọn.

Ṣe lawọn ọlọpaa ba ni ka jọ ka fawọn lọjọ marun un, wọn si kọ ọrọ le lori pe loootọ, loootọ, awọn ti yẹ iwe wa wo, awa ni ofin gba laye o, ṣugbọn awọn ko le sọ pe ki wọn daa pada nitori ọdọ ọga wọn ni Abuja laṣẹ ti wa.

Emi naa lọ si ọfiisi ọga wọn ni Abuja, a o bawọn nile, igba yẹn ọrọ korona n ṣẹlẹ, awọn ọlọpaa wa rọ wa ka ṣe suuru, awọn yoo kọ lẹta si ọga wọn ni Abẹokuta. Ṣugbọn to bẹẹ ju bẹẹ lọ awa tun wa roo pe wọn tun le maa fi falẹ lawa naa tun ṣe gbe igbesẹ, taa tun pada sile-ẹjọ.

Kii ṣe pe Buruji ku ni wahala ṣe n bẹ silẹ

Rara o ko ri bẹẹ rara, gbogbo nnkan nile aye yii awa jagun ni,Oloogbe funra ẹ latilẹ jagunjagun ni, bi ẹ ba wo Ọlọrun ọba taa n sin jagunjagun ni. Ti ko ba ru, kii lo, tawọn eeyan ko ba ta si mi, ti mo n ṣe rodorodo, inu mi n dun, mi ko tii di alaga, o  digba ti wọn ba ta lu mi, ti wọn ti mi, ti mi o ti, ti wọn le mi, ti wọn ko ba mi igba yẹn ni mo to mọ pe mo di alaga.

O daa ki wọn maa ti eeyan wo, amọ ki Ọlọrun ṣa ti wa lẹyin eeyan, nibi idaamu yẹn o ma wa dupẹ patapata ni ko si wahala kankan lẹyin iku ẹ.

Igbesẹ tawọn ti Ladi n gbe lọdọ wa.

Lọsẹ to kọja yii, wọn lọ bawọn alaṣẹ wa ti wọn ṣe ipade pẹlu wọn. Ijẹbu ni wọn ti wa bawọn, emi kekere yii naa wa nibẹ. Ni Sannde, to kọja yii, gbogbo awọn oloye ẹgbẹ temi ni wọn wa ba wa ni Abẹokuta taa bara wa sọrọ, lori ajọsọ wa, iṣẹ ti n lọ lori ẹ. Mo si mọ pe lagbara Ọlọrun PDP ti di ẹyọ kan.

Lori Remi Bakare ti wọn loun ni olori ẹgbẹ PDP ipinlẹ Ogun.

Ha, ṣe ẹyin mọ pe Rẹmi Bakare loun fẹ ṣe olori ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun, nitori emi ko tii darukọ ẹ, bi ẹyin ṣe wa darukọ ya mi lẹnu, gẹgẹ bi nnkan tẹẹ sọ pe ẹ gbọ.

Onikaluku lo mọ boun ṣe to, bẹẹ lonikaluku mọ boun ko ṣe to, ninu ẹgbẹ PDP temi wa lonii, ti mo n ṣe alaga,Bakare kii ṣe olori ẹgbẹ,awa o mọ bẹẹ o.

Nigba ti Buruji ku, a ko ti fẹnikankan dipo ẹ, nigba to ba ya olori maa jade nipasẹ iṣẹ ọwọ ẹ. Akitiyan ati bo ṣe n ṣe ti ẹgbẹ fi n tẹsiwaju lo maa juwe ẹni to tọ si. Laipẹ yii oju onitọhun yoo yọ.

 

 

 

 

 

 

No comments:

Post a Comment

Pages