Kin ni kan ṣẹlẹ lọjọ Aje, Monde, ọjọ kejilelogun, oṣu keji, ọdun yii, iyẹn ọsẹ to kọja, to si jẹ kayefi fun gbogbo awọn to n gbe ni Ilupeju, niluu Ọja- Odan, nijọba ibilẹ Yewa North, nipinlẹ Ogun, to si jẹ kayefi fawọn to wa nibẹ, ti wọn si n woju ara wọn pe ko dara keeyan maa kọwọ to n jẹ niya bọ aṣọ.
Lojiji nijọba ipinlẹ Ogun ṣadeede wọlu naa ti wọn si sare ṣe ifilọlẹ kikọ ileewe tuntun sagbegbe naa, eyi to n jẹ ileewe alakọbẹrẹ Community lagbegbe naa lati fi dipo abẹ atibaba tawọn ọmọ naa ti n kawe tẹlẹ lati bi ọdun meloo sẹyin, ti ko si si ijọba to ya si wọn ri.
Ẹyin naa ti mọ bawọn oloṣelu ṣe maa n ṣe, ṣe ni wọn sọ pe ki wọn ko awọn araalu jọ, ki wọn gba ilu, ki wọn le sọ pe ijọba to wa lode yii ṣe nnkan tẹnikan ko ṣee ri.
Loootọ lawọn eeyan ọhun ṣe bi wọn ṣe ni ki wọn ṣe, ṣugbọn lẹyin ti wọn lọ tan lawọn araalu yii wa tu kẹkẹ ọrọ bijọba ko ṣe kọbiara si wọn ni Yewa Awori paapaa julọ nipa eto ẹkọ ti wọn si ti dawọn nu.
Lọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ to kọla lọhun, ni tẹlifiṣan BBC tu aṣiri kan sita nipa ileewe alakọbẹrẹ Community to wa ni Ilupeju, ni Ọja-Ọdan naa, nibi ti ọga ileewe ọhun, Ifẹyọmi G O, ti sọ ipo tileewe naa wa ti ko bojumu, bibi tawọn ọmọleewe to le ni Ọọdunrun ti n kawe labẹ atibaba, ti ko si yara ikawe bẹẹ naa ni ko si ọfiisi kankan nibẹ.
Bi iroyin naa ṣe tan kaakiri nijọba ipinlẹ Ogun ti sọ pe ki lo ṣubu tẹ awọn yii, kilẹ ọjọ keji to mọ, wọn ti paṣẹ pe ki wọn wa wo awọn atiba ọhun, kawọn oniroyin yooku ma ba tun baa. Iyẹn nikan kọ, wọn tun ti sare ko eepẹ ati bulọọku wọnu ileewe naa, nitori ibi tiroyin ọhun ba lara wọn ko dara to.
Idi ẹ lo ṣe jẹ pe aarọ ọjọ Aje, Monde, to kọja yii ni Dokita Fẹmi Majẹkodunmi, ọga agba igbimọ to n ri ọrọ ẹkọ iyẹn SUPEB ati Ronkẹ Ṣomẹfun, oludamọran pataki fun gomina Dapọ Abiọdun lori eto ẹkọ ti ṣaaju awọn oṣiṣẹ wọn lọ sibẹ lati lọ bẹrẹ iṣẹ ki okiki ko tun to kan ju bayii lọ.
Ọpọ iwadii oniroyin wa lakooko to ṣabẹwo sawọn ileewe to wa ni ayika Ọja- Ọdan yii ni pe wọn ti dẹnukọlẹ, ibi kan tiẹ wa nileewe kan ti wọn pe ni Yewa North local Government, School 1, to jẹ pe inu ibẹru bojo lawọn ọmọleewe naa ti n kẹkọọ, igbakigba si ni awọn yara ikawe meji lara yara ikawe naa le wo lulẹ.
Eyi lo mu ki Dokita Fẹmi Majẹkodunmi, ṣe sọ fun ọga ileewe ọhun pe ti wọ ba ti ri ami pe o ti fẹẹ wo, ki wọn ko awọn ọmọleew jade, nitori awọn ko ti le le awọn to n kawe naa jade, ibeere wa ni pe to ba jẹ akoko tawọn ọmọleewe yii kawe lọwọ lo da wolẹ n kọ, wahala nla ni.
Ohun to tun jẹ kayeefi ninu ọrọ naa ni iwa ti ẹni ti wọn pe ni olori awọn ọga ileewe nijọba ibilẹ naa hu lọjọ naa, nibi ti ọga agba ileewe alakọbẹrẹ Community to tu aṣiri sita, G O Ifẹyọmi ti n ba wa sọrọ lo ti wa baa pe ki lo de to fi n ba oniroyin sọrọ, ṣebi awọn ti kilọ fun un pe ko ma ba oniroyin kankan sọrọ mọ, ka ni aye gbaa lọjọ naa, boya ni ko ni na baba agbalagba ọga ileewe naa.
Bo tilẹ je ọga ileewe naa ti fẹ ma yi ohun pada si nnkan to bawọn oniroyin BBC sọ pada pe wọn fi tipa mu oun ni, wọn fi ọrọ soun lẹnu ni ṣugbọn nigba taa sọ fun pe ko fọkanbalẹ ko sewu, to fẹẹ maa sọ ootọ nnkan to ṣẹlẹ lọkunrin yii wa ba. Iwadii fi ye wa pe idaamu ti wọn ti ko ba ọga ileewe ọhun lori aṣiri to tu sita yii kii ṣe kekere.
Ṣugbọn wọn ti gbagbe pe ka ni ọkunrin yii ko sọrọ ni ipo tawọn ileewe tijọba ṣẹṣẹ ṣe ileri pe awọn yoo tun ṣe. Pẹlu ọrọ tawọn araalu ba wa sọ lẹyin tawọn ijọba kuto nibẹ ni pe ṣe lo dabi pe ijọba ko nifẹẹ awọn to wa ni Yewa Awori yii nitori wọn ko jẹ kawọn gbe igbe aye irọrun.
Ohun taa gbọ ni pe ka ni igba ti wọn ti pariwo iwa tawọn Fulani darandaran hu lawọn agbegbe naa ni wọn ti bawọn gbe igbesẹ ni o ṣee ṣe ki wọn ti ki ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ.
Ọpọ lara awọn to n gbe lawọn agbegbe naa ni wọn ti sa kuro ti wọn ti sa lọ si ilu odikeji to paala pẹlu ilẹ wa. Bakan naa lo jẹ pe ṣe ni ọna to wọnu ilu naa tun buru jai, irinajo to yẹ ki wọn rin laaarin iṣẹju mẹwaa, wọn fi wakati kan rin.
Ti eto ẹkọ lo wa buru ju, idi niyii to fi jẹ pe wọn ṣe lawọn ọmọ mii in kii yọju sileewe ayafi ti wọn ba fẹẹ ṣe idanwo. A tun gbọ pe kii ṣe pe ko sawọn olukọ lawọn ileeewe, koda ẹni ti imọ ẹ kere ju ni awọn to jade nileewe awọn olukọni iyẹn NCE.
Ṣugbọn ẹdun ọkan lo jẹ pe ọpọ awọn tisa naa ni wọn ko ni ọfiisi bawo tiẹ ṣe ni wọn fẹẹ ni nigba to jẹ ko si yara ikawe to bojumu. Amọ sa o, Dokita Fẹmi Majẹkodunmi, alaga igbimọ to n ri ọrọ ẹkọ SUPEB.ti sọ pe nigba tawọn gbọ iroyin nipa ileewe ọhun, o bawọn lẹru.
O ni ọjọ naa loun ti ran awọn eeyan lati ṣe iwadii nnkan to ṣẹlẹ,idi ẹ lawọn ṣe wa, inu igbo Ilupeju lawọn ara agbegbe naa fawọn bayii lati kọ ileewe tuntun si, eyi tumọ si pe wọn yoo kuro nibi ti wọn wa ko wa sibi lẹyin ti wọn ba kọọ tan.
No comments:
Post a Comment