Ọkan awọn araalu Okun-Ọwa ko balẹ o, lori bawọn Fulani darandaran ṣe pa ọlọdẹ meji. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 17 March 2021

Ọkan awọn araalu Okun-Ọwa ko balẹ o, lori bawọn Fulani darandaran ṣe pa ọlọdẹ meji.

 


Inu ibẹru bojo lawọn eeyan ilu Okun-Ọwa, nipinlẹ Ogun, wa bayii nitori bi wọn ṣe lawọn  Fulani darandaran ṣe pa ọlọdẹ meji, ti wọn si tun fẹsun ijinigbe kan wọn.

Gẹgẹ bi Balogun Olumuyiwa Oduwọle to jẹ adele ọba ilu naa ṣe wi,o ni lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii lawọn eeyan ilu naa to mọ pe awọn Fulani darandaran yii pawọn ọlọdẹ meji ọhun sinu oko Agerige, to wa niluu naa.

Awọn ọlọdẹ meji ti wọn ṣagbako iku awọn darandaran yii ni Dele Martin ati Lazarus Lobe, ẹni ti wọn sọ pe iyawo ẹ bimọ ni nnkan bi oṣu marun-un sẹyin.

Wọn ni awọn mejeeji lọ ṣiṣẹ ọdẹ lọjọ  Fraide, ọjọ karun un, oṣu kẹta, nigba tawọn ẹbi wọn ko ri wọn ki wọn pada dele lo ni wọn gbe awọn kan dide lati tọpa sẹ wọn, ẹdun ọkan lo si jẹ pe oku wọn ni wọn ri.

Balogun Oduwọle tun fi kun ọrọ ẹ pe wọn ri apa ibọn lara awọn eeyan yii, bẹẹ ni wọn ri igbẹ maalu ati ipasẹ awọn maalu yii nibi ti wọn pa wọn si, eyi lo mu kawọn fura pe awọn darandaran lo wa ṣiṣẹ yii.

O ni loju ẹsẹ lawọn fọrọ naa to awọn ọlọpaa  Ọkun- Ọwa leti tawọn naa si ke si ẹkun wọn to wa ni Ijẹbu-Ode, awọn lo si waa gbe oku lọ si mọṣuari.

Ọkunrin yii tun ṣalaye pe o tipẹ tawọn Fulani darandaran ti ni ibugbe ti wọn gbe ninu oko ilu ọhun, ṣugbọn to ni wọn maa n kọja aye wọn, bi  ọdun mẹta sẹyin lo ni wahala fẹẹ bẹ silẹ laaarin atawọn agbẹ, nitori wọn ko awọn maalu wọn lọ si oko oloko, ti wọn si ba ọgbin jẹ.

O ni idi eyi lo mu ki Aṣiwaju Ṣina Ogunbambọ, fi kọ lẹta si ijọba ipinlẹ Ogun lati tete dide si abo awọn araalu naa, nitori ki nnkan ko ma ba buru ju bayii lọ.

Bẹẹ la tun gbọ pe eto abo ilu naa ko rinlẹ to, eyi to si n mu idaamu bawọn eeyan, idi niyii tawọn olori ilu ọhun fi gbe igbesẹ lati rii pe wọn ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn alaabo ilu.

Nigba to n sọrọ nipa iṣẹlẹ naa, Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ agbẹnusọ fawọn ọlọpaa nipinlẹ Ogun fidi ẹ mulẹ pe loootọ niṣẹlẹ naa waye ati pe awọn ti mu awọn afurasi kan lori ẹ ti iwadii si ti bẹrẹ.

No comments:

Post a Comment

Pages