Beeyan ba jẹ ori ahun, ko si ki omi maa bọ loju ẹ to ba de adugbo kan ti wọn n pe ni Ayedade, Rounder lọna igbo-ọra, niluu Abẹokuta ki omi maa bọ loju ẹ to ba debi tawọn ẹṣọ aṣọbode ti wọn pe ni kọsitọọmu yinbọn pa ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Rashhed Kọlawọle.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii niṣẹlẹ
naa waye lakooko ti Rasheed ati aburo ẹ kan tiyẹn n jẹ Mohammed Ramon wa lori ọkada,
ti wọn n bọ lati lọ gbowo iṣẹ alajapa ti wọn n ṣe.
Ninu ọrọ Mohammed to ba oniroyin wa sọ, o ni ni nnkan bi
aago mẹjọ alẹ niṣẹlẹ ọhun waye, o ni Rasheed lo pe oun pe koun wa ba oun ni
Ayedade ni nnkan bi aago meje kọja ni alẹ ọjọ naa.
O fikun ọrọ ẹ pe ọkunrin ti wọn pa yii ni mọto kan to n
fi ṣe ajapa, mọto ọhun lo wa sibi kan, o ni awọn fẹ jọ de Igbo-ọra. O ọkada
loun lo ni toun tawọn si jọ maa n kaakiri, lẹyin tawọn lọ gba owo tawọn fẹẹ lọ
gba tan, tawọn n pada bọ.
O ni bawọn ṣe de iyana onigangan, lawọn ri ọkada Bajaj, o
lonitohun lo ibomu, ko pẹ ni moto Kamri alawọ ewe naa jade pẹlu ẹ.
Ọkunrin tun sọ pe “ Ko pẹ la tun ri mọto Hilọọsi alawọ
dudu, ti wọn kọ ileeṣẹ kọsitọọmu si lara, tawọn oṣiṣẹ wọn ṣi wa ninu ẹ. Ṣe ni wọn
kọja lara wa, bi a ṣe de ibikan ti wọn n pe ni Yewa Central College, lati fẹẹ
de Rounder, ni wọn fi mọto wa de wa lọna, nigba taa ṣi ṣe nnkan buburu.
O ni aṣọ iṣẹ wọn ni wọn wọ lọjọ naa, bi wọn ṣe da wọn
duro lojiji ni Rasheed fo bọlẹ nitori ijaya, ọkan ninu wọn to ṣilẹkun, yọ ibọn
lojiji, to si bẹrẹ si ni yin in.
Mohammed ni ṣe lawọn kọsitọọmu yii ko beṣubẹgba ti wọn
tun sare tẹle Rasheed.Nnkan toun tun maa ri ni pe ṣe ni ọkan lara wọn tun wa ba
oun, ti wọn ko igbaju igbamu ba oun, ti wọn lu oun nilukulu.
O ni ohun to tun ya oun lẹnu ni pe nigba ti wọn lu oun
tan, wọn tun gbe oun sinu mọto wọn, ti wọn wa oun lọ, sibẹ ni iro ibọn wọn ṣi
dun nibi ti wọn ti n le Rasheed.
O ni ko to akoko yii lẹnikan ninu wọn ti sọ ninu mọto pe
awọn tawọn mu yii ko mọ nnkankan nipa iya tawọn fi jẹ wọn,o ni ko pẹ ni wọn gba
ipe, ti wọn le oun jade.
O ni bi wọn ṣe ri pe awọn ti paayan ni wọn ti wọna lati
sa lọ,o meje lawọn eeyan naa ti wọn wa ṣiṣẹ naa, boun ṣe raye jade loun pe awọn
toun mọ pe nnkan bayii ṣẹlẹ.
Gbogbo igba naa awọn ko ri Rasheed, nigba to di ọjọ keji,
awọn lọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ti wọn si gbs igbesẹ, ṣugbọn alẹ Ọjọbọ Tọsidee,
ni ẹnikan pe wọn pe awọn roku kan ninu igbo loju ọna Igbo-ọra, nigba ti wọn yoo
si fi de bẹ, o di Rasheed ti wọn n wa.
Aarọ ọjọ Ẹti, ni wọn to gbe oku ẹ jade kuro ninu koto to ṣubu
ṣi, tawọn ọlọpaa si tẹle wọn lọ si ile igboku si to wa ni Ijaye, niluu Abẹokuta,
nibi ti wọn ti kọkọ yọ ọta ara ẹ kuro, ko to di pe wọn sin.
Iwadii tun fi ye wa pe wọn ni awọn kọsitọọmu to maa n wa
lọnọ Ṣiun, ni wọn wa ṣiṣẹ naa, ati pe wọn ni ootẹli kan ti wọn maa n sun.
Awọn ara agbegbe ọhun ti wọn fi ehonu wọn han sọ pe nnkan
tawọn ọlọpaa n foju awọn ri lagbegbe naa kii ṣe kekere, ti ẹmi awọn eeyan ko si
jọ wọn loju.
A tiẹ tun gbọ pe lakooko ti wọn gbe oku ẹ jade ninu koto,
wọn ba ẹgbẹrun lọna aadọfa naira lara ẹ, ti wọn si ko fun aburo ẹ. Ọdun mọkandinlogoji
ni wọn pe e iyawo meji atọmọ marun un lo fi silẹ saye.
capt
No comments:
Post a Comment