Idi ti mo fi pada sidi iṣẹ agbẹ-Salvador - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 28 September 2020

Idi ti mo fi pada sidi iṣẹ agbẹ-Salvador



 Agba oṣelu ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko ni Ọnarebu Moshood Adegoke Salvador, o ti figba kan jẹ Ọnarebu nile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja, bẹẹ oun si ni oludasilẹ ileeṣẹ agbẹ, Salvador Farm. Laipẹ yii lo gba wal alejo, nibi to ti ba wa sọ nipa bi nnkan ṣe n lọ si lagbo oṣelu ati idi to fi da iṣẹ agbẹ silẹ. Ohun to ba wa sọ niyii.

Ẹkọ taa ri kọ ninu ibo to waye nipinlẹ Ẹdo

Ibo to waye nipinlẹ Edo lọsẹ meji sẹyin ti jẹ ka mọ ninu ọrọ ti Aarẹ Buhari sọ mu kawọn eeyan dibo, to si han gbangba pe ifẹ inu awọn eeyan ni wọn dibo fun.

O si jẹ ka tun mọ pe a tun le ṣe ju bẹẹ lọ ju bi a ti n ṣe tẹlẹ lọ.  A o ri pe ko si ẹri pe wahala bẹ silẹ lakooko ibo naa, ti gbogbo ẹ si lọ bo ṣe yẹ ko lọ.

Loootọ mi o bawọn lọ si Edo, bẹẹ ni mi o ki i ṣe oṣiṣe ajọ eleto idibo, mi o fi Eko ti mo wa silẹ rara. Ṣugbọn gbogbo iroyin taa gbọ ni pe ibo naa lọ ni mẹlọmẹlọ.

Ohun ti mo tun ri ni pe ibo naa ki i ṣe pe iṣipo agbara, tabi gbigba oṣelu, nnkan ti mo kan ro ni pe  awọn eeyan ko fẹran ẹni ti APC fa kalẹ ni wọn ṣe dibo fẹni tọkan wọn n fẹ. Eyi yoo jẹ ki APC ṣiṣẹ lori awọn aṣiṣe wọn.

Igbesẹ to yẹ ki APC gbe nipinlẹ Ondo fun ibo to n bọ

Ẹni to jin si koto, o kọ ara yooku lọgbọn,ohun to ṣẹlẹ ni Edo gbọdọ jẹ arikọgbọn fawọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC, ki wọn le tun ile wọn ṣe. Bi wọn ba ṣee daadaa wọn yoo ba, bi wọn ko si ṣe daadaa bakan naa wọn yoo ba pẹlu.Eeyan ki i gbin alubọsa ko ka ẹfọ, ohun teeyan ba gbin ni yoo ka.

Bi ẹgbẹ oṣelu APC ba fẹẹ wọle nipinlẹ Ondo ninu ibo to n bọ ninu oṣu kẹwaa yii, wọn gbọdọ mu awọn eeyan ni pataki, ki wọn ṣe nnkan tawọn eeyan n fẹ, ko to di pe wọn gba ibo lọwọ wọn.

Fun ẹni to wa lori ipo, o gbọdọ jẹ kawọn araalu mọ awọn nnkan to ti ṣe lakooko ijọba akọkọ ẹ fun wọn. O ṣeeṣe fẹni ti ko si lori ipo ko ṣeleri pe toun ba dori ipo oun yoo ṣe bayii amọ fẹni to ti wa nibẹ, wọn a fẹẹ beeere nnkan to ṣeleri to muṣẹ tẹlẹ.

Nitori ẹ lo ṣe ṣeeṣe fẹni to wa lori ipo ko lo awọn nnkan to ti ṣe faraalu lati fi gba ibo lọwọ wọn lẹẹkeji. Yoruba sọ pe omi to  ba wọn ni wọn la n rẹ ila si, ko ṣeeṣe lati sọ pe awọn fẹẹ yi ibo.

O gbọdọ maa gba imọran awọn eeyan, bi imọran wọn ko ba tiẹ nitumọ, iwọ gẹgẹ bi aṣaaju, o le lo ofin lati ṣatunṣe, nipa imọ to ni ti ko nii da wahala silẹ.

Ko yẹ ki aṣaaju sọ pe nitori ipo toun wa ko wa lo le wọn lori, ko yẹ ko ri bẹ. Gbogbo nnkan ti Yoruba ni lo ni lati lo lati fi fa oju wọn mọra.

 

Ọrọ ti Aṣiwaju Bọla Ahmed sọ lori ibo Edo kọ lo mu ijakulẹ wa

Awọn to sọ pe ohun ti olori APC, Bọla Ahmed sọ lo mu ijakulẹ bawọn ninu ibo to waye ni Edo,ko ri sọ rara, ẹ ẹ ba mi beeere lọwọ wọn pe tawọn ba jẹ olori ẹgbẹ kin ni nnkan ti wọn fẹẹ sọ.

Ṣe wọn fẹ sọrọ tako ẹgbẹ wọn ni tabi kin ni ohun ti wọn fẹẹ sọ, ki ẹgbẹ naa ma daa, ko ma ra, ko ma ṣedin, ẹ ma fẹnu fẹ lọfinda si ni., ẹ ma fẹnu tun ṣe ni, iwọnba ohun tiyẹn ṣe niyẹn.Ọmọ ẹni ko ni ṣedi bẹbẹ rẹ, ka wa filẹkẹ sidi ọmọ ẹlomii in.

Ọmọ ẹgbẹ kan ko le ṣe di bẹbẹ rẹ, ki wọn wa sọ pe ko lọ so si tẹlomii in. Ohun to ṣẹlẹ ni apa ibẹ niyẹn.Awọn to sọ pe nnkan to sọ ku diẹ kaato, nibo lawọn wa ti wọn ko le ṣatunṣe

Mi o wa lati gbe lẹyin ẹnikẹni bi ẹ ṣe n wo mi yii, mi o si nile fun gbogbo yẹn. Emi kan maa sootọ temi, mo kuro nibẹ, temi niyẹn. Iṣẹ tiẹ lo n ṣe.

Lori pe APC ṣiṣẹ tako ara wọn.

Apẹẹrẹ niyẹn pe ki wọn ma maa ro pe ẹru ni ọmọ ẹgbẹ.Ki wọn ma le ro pe ẹru lawọn eeyan tabi agbara kan wa lọwọ awọn ju awọn to gbe wọn sibẹ lọ, eeyan lo gbe wọn sibẹ. A ni mo n sọ, mo tun n tun sọ pe ko si olori orileede, gomina tabi awọn oloṣelu to le sọ pe mo de iwaju ohun gba owo ri.

Mi o wa iṣẹ de iwaju wọn ri, mi o wa ipo de iwaju wọn ri, awọn ọmọ ẹgbẹ to n tẹle mi taa n pe ni Conscience Forun, awọn lawa n ja fun pe ki wọn fun niṣẹ. Ebi o pa mi, iya o jẹ mi ki wa ni nnkan ti mo n ba ka.

Ero ọkan awọn eeyan ni pe gbogbo oloṣelu ni ole

Ẹ ṣe, mo dupẹ, gbogbo ero ọkan awọn eeyan ni pe gbogbo awọn to ba ti depo oṣelu ni ole, ṣugbọn mo le fi gbogbo ẹnu sọ pe temi yatọ, mo fẹẹ ki ẹ lọ beeere kaakiri, koda lakooko ti mo jẹ Ọnarebu nile igbimọ aṣoju-ṣofin, akọsilẹ mi wa nibẹ, mi o gba owo to jẹ yẹ ki n lo fun nnkan ki n wa da si apo mi, ko ṣẹlẹ ri.

Ohun gan an lo fun mi ni anfaani lati sọrọ nibi gbogbo ti mo ba de.Latigba ti mo si ti fipo ọnarebu yii silẹ, mi o tun ti gba ipo oṣelu ka nkan titi di akoko yii. Mo jẹ alaga fun ẹgbẹ oṣelu, to jẹ pe mo tun nawo mi fun wọn ni.

Ko si wahala laaarin emi ati Aṣiwaju Bọla Tinubu

Ko si nnkan to n jẹ pe wahala wa laaarin emi ati Aṣiwaju, ko si awuyewuye rara, emi ko raaye nitori mo ti jokoo sidi iṣẹ agbẹ, awọn naa ko si tun raaye, wọn ṣiṣẹ oṣelu wọn lọ. Ohun to fa wahala niyẹn. Aṣiwaju kọjumọ oṣelu, emi naa yara kọjumọ iṣẹ agbẹ.

Nitori iṣẹlẹ to kọja yii beeyan ko ba sọra yoo sọ di alaisan. Nnkan to le mu ki ara mi jafafa, ti yoo tun ṣiṣẹ fun ilu, lo mu mi gba oko lọ, ẹ jẹ ki onikaluku maa ṣiṣẹ lọ, bo ba ṣe yẹ.

Idi ti mo ṣe pada si iṣẹ agbẹ

Oṣelu ti ko ba niṣẹ oṣeranu ni, bẹẹ lo si jẹ oṣeọlẹ.Oṣeranu, Oṣe-ọlẹ si ree ko le ṣe oṣelu ko mu abajade gidi wa. Nitori ọpọ awọn to wa nidii oṣelu ole ni wọn n ja.  

Ohun tẹgbẹ Conscious Forun taa da silẹ wa fun.

Ohun ti ẹgbẹ naa wa fun ni ki a maa da awọn ọmọ kekekee lẹkọọ lati mọ aṣa oṣelu to dara. Eyi to maa ṣe ilu ni anfaani, koko ibẹ ni ifẹ, ifọkansi,ati ifinutan.

Ọgọta ọdun ti orileede yii pe

Ni aye ilu ọgọta ọdun bi ọmọ oṣu meji ni, ni igbesi aye ilu,ori apẹẹrẹ pe ilu yii yoo si dara, olori, olori ni yoo sọ bi ilu yoo ṣe ri, ti olori ba jẹ ole, gbogbo yin naa ni yoo maa ja ole.

Bi olori ba si jẹ ẹni to ni ibẹru Ọlọrun gbogbo yin naa lo maa ni, nitori ẹ ni wọn ṣe ni ki wọn ṣekilọ fun wọn, ki wọn to dibo Edo, nitori ẹ lo ṣe jẹ pe ko si ninu akọsilẹ pe wọn huwakiwa tabi ajọ eleto idibo da nnkan ru, ko si si pe awọn ọlọpaa naa tun da wahala silẹ.

Ko ṣẹlẹ bi a ṣe maa n gbọ ni gbogbo igba, awọn naa mọ ọna lati ṣe daadaa.

Lori wahala oṣelu laaarin Fayẹmi atawọn eeyan ni Ekiti.

Bi wọn ba le bawọn sọrọ, ṣebi a ti bawọn sọ tipẹ, Bilbeli naa sọ pe igberaga lo n ṣiwaju iparun.Bi wọn ba ti fi olori fun olori, ki wọn fọwọ sibi tọwọ n gbe,nnkan to nṣẹlẹ yii naa ni yoo maa ṣẹlẹ.

Ka ni wọn ni olori nibẹ ni, wọn yoo ti pe wọn bawọn sọrọ, ko le to gbogbo nnkan ti wọn sọ pe awọn n fa yẹn. Gbogbo awọn nnkan ti mo n ṣe ninu ẹgbẹ PDP, nigba ti mo fi jẹ alaga wọn, ṣugbọn nigba ti mo rii pe wọn ti n paayan lakooko ti mo n ṣe ipade kaakiri lo mu fopin si. Kin ni mo fẹẹ fipo ṣe, mo ya fẹgbẹ wọn silẹ fun wọn. Emi nawo mi si ni, ki i ṣe pe wọn fun mi lowo nibẹ. Mo fẹẹ kemi maa nawo ki ile aye mẹkunnu dara, ki wọn maa rile gbe, ju ko wa mu ẹmi lọ.

Awọn ole ati oloju kokoro ni ko fẹẹ jẹ ki Yoruba di ominira.

Ẹ ẹ ma jẹ ka tan ara wa, lara iyanju iṣoro awa Yotuba gan-an niyẹn.Pataki aṣa ni ede, idi niyii ti mo fi ro pe nnkan ti wọn n ja fun ero daadaa ni.

Yoruba wa kaakiri, ki i ṣe ni Naijiria nikan. Ẹyin  ẹ jẹ ko di nnkan to ṣee ṣe tan, ti Ọlọrun fọwọ si, ẹ o ma ri bawọn eeyan yoo ṣe maa pada wa sile.

Ṣe ẹ ri lori awọn ti ko fọwọ si, gbogbo wa ko le sun ka kọri sibi kan naa., ẹni ti ko ba pe to ti mọ pe oun ko nii ri jẹ nibẹ, ẹni to n wa lati jẹ ninu mọdaru, wọn ko le fọwọ si, ẹni to ba ri nnkan to n lọ lọwọ, to n rowo ji, ko le fọwọ si. Wọn fi ede ko wa lẹru, awa fi ede ti wa, a a sọnu. Inu mi maa n bajẹ ni.

Ẹ jọwọ, ẹ ba wa pariwo taa ba ri ọmọ Yoruba to n wọṣọ Chinnese, epe ni ki wọn maa gbe wọn ṣẹ. Ṣe ẹ mọ pe awọn ede taa mọ itumọ ẹ lawọn China yii maa n kọ sinu iwe adehun wa, ohun to jẹ ka ko si wọn lọwọ niyẹn.

Ẹni ti Ọlọrun ba gba fun ni yoo wọle nipinlẹ Eko lọdun 2023

Ṣe bi gbogbo ọmọ ni Jagun loju iya ẹ, ko si ẹgbẹ kan to maa sọ pe nnkan to dara ko wu ohun, ẹ jẹ ki PDP lọ ṣiṣẹ, ẹni ti Ọlọrun ba gba fun ni.

 

No comments:

Post a Comment

Pages