Ijọba ipinlẹ Ogun fọwọ i atunṣe ọna Denrọ-Ishashi-Akute atawọn ọna meji mii in. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 23 September 2020

Ijọba ipinlẹ Ogun fọwọ i atunṣe ọna Denrọ-Ishashi-Akute atawọn ọna meji mii in.

 



Ijọba ipinlẹ Ogun ti fọwọ bi bẹrẹ iṣe lori awọn ọna mẹta kan ti wọn gba pe o ṣe pataki nipinlẹ naa. Eyi jẹ abajade abọ ipade wọn ti wọn ṣe.


Ninu ọrọ Ade Adesanya, to jẹ kọmiṣanna fọrọ iṣẹ atawọn ohun amayedẹrun ṣe wi, awọn ọna to ka silẹ ọhn ni ninu eyi ti wọn ti pati wa ni ninu rẹ ni Kilomita Denro-Isashi-Akute, Kilomita Oluṣẹgun Ọsọba-Toyin ni Agbado, nijọba ibilẹ Ifọ atiKilomita Mọlipa-Erinlu eyi ti wọn lo so pọ mọ Ijebu Ode, Odogbolu ati ijọba ibilẹ ijẹbu North East LGs, ni ẹkun  Ogun East .

Nigba to n ṣapejuwe awọn ọna bi ohun imayedẹrun lo ti ni ipa ti wọn n ko lori ero ọrọ aje kii ṣe kekere fohun idagbasoke, kọmiṣanna wa ṣakiyesi pe ọna Denro-Ishashi-Akute ti di pipati lati nnkan bi dun meloo sẹyin, to si n fa ẹdun ọkan fawọn olugbe to n gbe nibẹ.

Akinsanya tun ṣalaye pe awọn ọna mejeeji ti wọn fẹ ṣe nijọba bilẹ Ifọ yii lo ṣe pataki ti ko ṣe fojudi rara nitori awọn lo so ipinlẹ Eko ati Ogun papọ.

O ni ijọba to wa lode yii si foju sun awọn eto ọrọ aje lagbegbe ọhun. O ṣeleri  pe laipẹ yii ni ọna igbalode ti yoo so mejeeji pọ yoo waye.


O mu dawọn eeyan loju pe ti atunṣe awọn ọna yii ba pari, ohun gbogbo ati ọrọ aje yoo pada bọ sipo.


Nigba to n sọrọ nipa awọn akanṣe ile ti wọn ṣe lọwọ, Ọnarebu Remmy Hassan, to jẹ oludamọran gomina nipa ibanisọrọ sọ pe oriṣiriṣi iṣe akanṣe nipa ọrọ ile lo n lọ lọwọ kaakiri ipinlẹ yii.


O sọ pe lara ẹ ni awọn eyi to n lọ lọwọ ni Idi-Aba, Abẹokuta, Kọbapẹ, Ṣagamu, Ijẹbu-Ode, Ọta, Ilaro atawọn ilu mii in nipinlẹ naa.

                                                                                

O ni awọn ile yii lo jẹ pe yoo wa fawọn ọmọ ipinlẹ yii ni owo ti ko ni pawọn lara.







 

No comments:

Post a Comment

Pages