Lọjọ Ẹti, Furaidee, osẹ to kọja yii ni ẹgbẹ oṣelu PDP, tipinlẹ Ogun, ṣebura fawọn oloye ẹgbẹ wọn lati ijọba ibilẹ titi de wọọdu kaakiri. Eto naa to waye ni sẹkiteriati ẹgbẹ naa niluu Abẹokuta lawọn ọmọ ẹgbẹ ti peju pesẹ.
Ibura ọhun ko gba wọn ju wakati lọ ti wọn fi ṣetan nitori iroyin ti wọn gbọ pe awọn kan tinu wọn ko dun fẹẹ wa da eto naa ru, ti wọn ni wọn ti lọ sọ fawọn ọlọpaa pe awọn pejọ pọ.
Ninu ọrọ ẹ to ba wọn sọ lọjọ naa, Ọnarebu Sikirulai Ogundele, alaga ẹgbẹ oṣelu ọhun nipinlẹ Ogun, lo ti ki awọn oloye tuntun naa ku oriire to si rọ wọn lati jumọ ṣiṣẹ pọ ki wọn si wa ni isọkan.
O tun sọ fun wọn pe pataki nnkan to yẹ ko jẹ wọn lọkan ni bi ogo ẹgbẹ naa yoo ṣe pada bọ sipo ti wọn wa bayii, O tun rọ wọn ki onikaluku wọn pada sile lati forikori papọ ọna ti wọn yoo fi ṣe aseyọri lọdun 2023.
Ko to to akoko yii lawọn agba ẹgbẹ naa kan ti bawọn to wa nibẹ sọrọ lati ma ṣe bẹru, nitori Ọlọrun ti gba ogo ẹgbẹ yii, yoo si mu wọn de ebute rere.
Lara awọn to tun wa nibẹ lọjọ naa ni Ọnarebu Lẹyẹ Ọdunjọ, to jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, Bankọla Akinloye, alukoro ẹgbẹ,awọn oloye ẹgbẹ yooku atawọn agbaagba ẹgbẹ.
No comments:
Post a Comment