Bo tilẹ jẹ pe o ṣẹṣẹ pe oṣẹ kan ti Alaaji Yekinni Oyedele tọpọ mọ si Baba Lẹgba jade laye, ajalu mii in tun ti ṣẹlẹ lagbo awọn oṣere tiata, ọkan lara awọn agba oṣere yii, Oloye Jimọh Aliu la gbọ pe o ti dagbere faye.
Gẹgẹ bi a ṣẹ gbọ, lọsan an yii ni wọn ni iku pa oju Baba naa de, ti wọn si sọ faye pe o digboṣe.
Iwadii fi ye wa pe laipẹ yii ni wọn ṣẹṣẹ pari lokeṣan fiimu kan, eyi ti wọn pinnu lati fi ṣe ayẹyẹ ọjọọbi ọdun karundinlaadọrin, nibẹ gan-an ni wọn sọ pe ara wọn ko ti ya, ti wọn ni wọn ko le sọrọ daadaa.
Ṣugbọn awọn to sunmọ wọn to ba wa sọrọ sọ pe ara wọn ti n balẹ, ko to di pe ọrọ naa yiwọ, to si mu ẹmi agba oṣere ọhun lọ. Ọpọ awọn oṣere tiata ti wọn jọ wa ni lokeṣan ni ọrọ iku yii si n jẹ kayefi fun pe ṣe iṣẹ aṣegbẹyin ti Baba naa fẹẹ ṣe reee.
Ọla, ọjọ Abamẹta, ni wọn yoo sinku Oloye Jimọh Aliu si Okemẹsi gẹgẹ bi ilana ti Oloogbe naa ti la silẹ ko to ku pe ẹgbẹ Baba oun ni ki wọn sin oun si, bẹẹ la gbọ pe adura ọjọ mẹjọ yoo waye ni Ado-Ekiti.
Ẹkunrẹrẹ itan igbesi aye Baba naa n bọ laipẹ
No comments:
Post a Comment