Ẹgbẹ oṣelu PDP ti lawọn duro gbọingbọin pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Ogun lori iyanṣẹlodi ikilọ ti wọn bẹrẹ, amọ ki wọn ṣe suuru, ki wọn si pa ofin mọ lakooko naa.
Ninu atẹjade ti olupolongo ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, Bankọle Akinloye fi sita lo ti sọ pe awọn fi atilẹyin wọn han si igbesẹ ọhun, nitori bi Dapọ Abiọdun to jẹ gomina ṣe kọ lati ṣe nnkan tawọn oṣiṣẹ yii n fẹ.
O sọ pe pẹlu igbesẹ awọn oṣiṣẹ lori ihuwasi ẹgbẹ oselu APC ti fihan pe awọn to n dari ẹgbẹ yii jẹ olufọkantan, ati pe igbagbọ awọn ni pe ijọba yoo tete wa ọna abayọri si lakooko iyanṣẹlodi ikilọ wọn to n lọ lọwọ
Bẹẹ lẹgbẹ oṣelu PDP tun lawọn nigbagbọ pe iyanṣẹlodi onikilọ yii ko ni di nnkan tawọn oṣiṣẹ yoo fi yari patapata lati da iṣẹ naa silẹ patapata, tijọba ko ba tete ṣe nnkan ti wọn n ja fun lasiko. Ki wọn si wa bi idẹrun yoo ṣe de bawọn ki idagbasoke fi le tẹsiwaju nipinlẹ naa.
Olupolongo naa tun ṣalaye siwaju pe ẹgbẹ oṣelu PDP mu igbe aye awọn oṣiṣẹ lọkunkundun, to si tun jẹ awọn logun, idi niyii tawọn fi gbe atẹjade kan sita ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin lati fi ke si ijọba pe ki wọn dide aanu sawọn oṣiṣẹ nipa fifọwọ si afikun owo oṣu wọn, ki wọn si san gbogbo awọn owo ajẹmọnu ti wọn ti jẹ wọn tẹlẹ.
Wọn lo ti di gbogbo igba Gomina Abiọdun lati ma kọ eti ikun sawọn ikilọ tabi amọran ti wọn ba gba ijọba ẹ, to si jẹ pe ifẹ inu wọn ni wọn n ṣe, eyi ti ko si yẹ ko ri bẹ.
Iyalẹnu ni wọn sọ pe o jẹ lori iroyin kan tawọn gbọ pe ijọba ipinlẹ Ogun ti da awọn owo to yẹ si ti eto idibo to fẹẹ waye nipinlẹ Ondo ati Edo, ẹdun ọkan nla lo ni o jẹ fawọn.
O ni gẹgẹ bi erongba tawọn nigbagbọ ninu ẹ ko yẹ ki iya maa jẹ oṣiṣẹ kankan, idi niyii tawọn fi dide atilẹyin fun wọn lati le fopin si iwa ọdaju tijọba to wa lode yii n hu, pẹlu gbogbo igbesẹ tawọn aṣaaju awọn oṣiṣẹ ti gbe, ti wọn ko jẹ ko yọ ri si rere.
Bankọle wa pari ọrọ ẹ pe pẹlu awọn igbesẹ akọ ti wọn n gbe yii, awọn tun rọ wọn ki wọn fi suuru si, ki wọn ma ṣe ṣe nnkan ti ko bofinmu, titi ti nnkan ti wọn n ja fun yoo fi tẹ wọn lọwọ.
No comments:
Post a Comment