Wọn ni Ọnarebu Adewumi Ijaya n lo awọn kan lati ba aṣa jẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 15 September 2020

Wọn ni Ọnarebu Adewumi Ijaya n lo awọn kan lati ba aṣa jẹ


 


Lẹyin taa gbe iroyin kan jade lana an lori bawọn ara ilu Makun, ni Ṣagamu, ṣe ke gbajare sita pe awọn ko fẹ ki wọn fi Ọnarebu Adewumi Ọnanuga tọpọ mọ si Ijaya, to jẹ aṣoju wọn nile igbimọ aṣoju-ṣofin jẹ oye Yeye ọba, lawọn aṣiri mii in tun jade lori bi wọn lo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn kan lati ba aṣa jẹ.

 

  Gẹgẹ bi atẹjade ti wọn fi sọwọ si wa ni wọn ti sọ pe owo nla lawọn gbọ pe obinrin naa gbe fun Lisa Makun, Losi Makun, Awabat, Baba Kay, Akoje ati S.K Onafowokan lati rii pe oye naa ko bọ mọ oun lọwọ.

 

Wọn lawọn eeyan ti wọn fẹsun kan pe wọn gbowo naa ni wọn sọ pe wọn ti ṣeleri pe awọn yoo ṣiṣẹ owo ti wọn gba yii lati ri pe oye ọhun ko bọ mọ Ijaya lọwọ.

 

Oye ọhun taa gbọ pe yoo waye lọjọ Aiku, Sannde, Ogunjọ, oṣu yii ni wọn sọ pe wọn tun sun sẹyin si Ọjọbọ, Tosidee, ọsẹ yii ti wọn si sọ pe wọn ti bẹrc igbesẹ ẹ bayii.

 

Iyalẹnu ni wọb lo jẹ fawọn pe awọn agba to yẹ ki wọn maa gbe aṣa ga, lo wa jẹ pe awọn naa lo n ba aṣa jẹ, ti wọn ni wọn ti fẹ tori owo da nnkan ru, ni eyi ti ko tọna.

 

 Atẹjade naa tun sọ pe awọn tẹnumọ pe obinrin ti wọn fẹẹ fi joye naa kere sipo yii nitori awọn agbalagba obinrin lo le Iya Ewusi, nitori awọn iriri ti wọn ti ni.

                                                                                     

Wọn wa lo akoko naa lati ke si Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun, ati gbogbo ọmọ bibi ilẹ Ṣagamu lati pe awọn eeyan ọhun ki wọn ma tori ijẹkujẹ ba aṣa ati iṣe ilu jẹ. Bẹẹ ni wọn tun ke si  Ọba Timothy Oyeṣọla Akinsanya, Ewusi tiluu Makun lati ma ṣe jẹ ki wọn fi miliọnu mẹẹdogun ti wọn ni wọn pin ba ọjọ iwaju ilu naa jẹ.

 

Gbogbo akitiyan wa lati ba awọn ti wọn fẹsun kan naa ati obinrin to lọrọ naa sọrọ lati gbọ tẹnu ẹ lo ja si pabo, ṣugbọn bi wọn ba ti sọ tẹnu wọn naa la o gbe jade.

 

No comments:

Post a Comment

Pages