Awọn eeyan Makun lawọn ko fẹ Ijaya nipo Yeye Ọba Makun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 14 September 2020

Awọn eeyan Makun lawọn ko fẹ Ijaya nipo Yeye Ọba Makun

 

 

Afaimọ ki wahala ma bẹ silẹ niluu Makun, Ṣagamu, nitori bawọn eeyan ilu ṣe yari pe awọn ko fẹ Onarebu Ọtunba Adewumi Oriyọmi, tọpọ awọn tiẹ mọ si Ijaya, to jẹ ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin to ṣoju ẹkun agbegbe Rẹmọ niluu Abuja nipo Yeye Ọba, ti wọn ni awọn nnkan gbero lati fi jẹ.

 

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita, eyi to tẹ wa lọwọ ni wọn ti sọ pe obinrin naa ko tọ lẹni to yẹ ki wọn fun nipo ọhun, nitori bi wọn ṣe lo ti n ja awọn eeyan kulẹ latigba to ti di olori ninu oṣelu.

 

  Wọn ni bo tilẹ jẹ pe ko si nnkan to kan awọn eeyan nibẹ lati fi ẹnikẹni sori oye naa ṣugbọn bi wọn ba ni kawọn wo awọn nnkan to yi ipinnu ti wọn fẹẹ fi obinrin naa joye, ko yẹ ko nii ṣe pẹlu oṣelu rara, ati pe Ijaya gan-an kuna lati ṣe ẹtọ ẹ lori ipo to wa fawọn eeyan.

 

Wọn ni nnkan to yẹ ko jẹ Ọnarebu yii logun ni lati rii pe awọn eeyan abẹ ẹ jẹ mudunmudun ijọba awarawa ṣugbọn ti wọn ni ko gbaju mọ, to jẹ pe ọrọ oye yii lo kọju mọ.

 

 

Niwọngba ti wọn sọ pe o kuna lati ṣe nnkan tawọn eeyan ẹ n fẹ, ti ko si le sọ pato awọn iṣẹ gidi to ṣe fawọn eeyan ẹ, ko yẹ kawọn kan wa tori atẹnujẹ ba ọjọ iwaju wọn jẹ lati fi joye dandan le awọn araalu Makun lori

 

  Awọn araalu sọ pe gẹgẹ bi awọn ṣe mọ ẹnikẹni ti wọn ba fẹẹ fi joye, o gbọdọ ni nnkan gidi ti wọn le tọka si pe o ṣe fawọn eeyan ati ni awujọ to ba wa ati pe awọn mọ pe oye Yeye Ọba Makun wa fun akinkanju obinrin to ni iriri lawujọ eyi ti wọn ni Ijaya ko ni

 

   Wọn lo tun gbọdọ jẹ ẹni Ọba Makun gbọdọ maa bọwọ fun ni, idi niyii to fi jẹ pe agbalagba to ti darugbo ni wọn naa fi joye naa, nitori ọmọ Ẹwusi ni wọn maa n ka si, ṣugbọn ti wọn ni Ọnarebu obinrin yii ko tii depo ẹ rara pẹlu. 

Pẹlu gbogbo eleyii, ni wọn fi pe gbogbo awọn tọrọ kan lati tete yi ipinnu wọn pada ti wọn ko ba fẹẹ ki wahala bẹ silẹ niluu.

 

 

No comments:

Post a Comment

Pages