Gbogbo awọn to wa nibi ayẹyẹ ọjọ mẹjọ Alaaji Yekinni Oyedele tọpọ mọ si Baba Lẹgba lo ya lẹnu nigba ti aarẹ ẹgbẹ oṣere tiata ANTP, Ọgbẹni Adewale Ẹlẹṣọ ati ti TAMPAN, Ọtunba Bọlaji Amuṣan tọpọ mọ si Mista Latin jọ de sibi ayẹyẹ adura ọhun.
Ṣe ni ariwo gba gbogbo ibi ti wọn ti n ṣeto naa, ko yẹ ko ma ri bẹ nitori pe latigba ti wahala ti wa laaarin awọn oṣere ọhun lawọn kan ti sọ pe wọn ko le bara wọn ṣe mọ.
Ṣugbọn pẹlu nnkan to ṣẹlẹ lọjọ Mọnde naa, o ti han gbangba pe ajọṣepọ to danmọran ti wa laaarin awọn mejeeji, ti wọn si ti n bara wọn ṣe pọ.Nibi ayẹyẹ adura ọhun to waye ni Ita-Imọ, niluu Abẹokuta ni imaamu agba ni Imọ, ti ko awọn Aafaa yooku ẹ sodi wa sibi eto adura ọhun.
Nibẹ ni wọn ti fadura ran awọn ẹbi Oloogbe Alaaji Yẹkinni Oyedele lọwọ, ati gbogbo awọn onitiata lapapọ. Ninu ọrọ Adewale Ẹlẹsọ lọjọ naa lo ti ṣapejuwe Baba Lẹgba, gẹgẹ bi ẹni to ni iwa rere, to si tun awọn eeyan mọra.
O sọ pe oun ti mọ Baba Lẹgba, tawọn mọ si Sunday Ikubọlajẹ, nigba ti wọn wa lọdọ Baba Sala Alawada. O ni wọn jẹ alawada eeyan, to jẹ pe ti wọn ba wa nibi kan, wọn maa n fẹ pa eeyan lẹrin ni.
Ati pe Baba Lẹgbẹ jẹ ẹnikan to si duro ti awọn ninu ẹgbẹ ANTP titi digba tiku fi muu lọ. O ni wọn jẹ oṣere to ko ẹbi ati ara jọ. Ẹkọ to ni oun ri kọ lara Baba naa ni pe wọn jẹ olootọ, nnkan ti wọn ba lo tọ ki wọn gba pe o tọ,ọmọluabi lo pe wọn.
Nigba toun sọrọ ni tiẹ, Ọtunba Bọlaji Amuṣan, tọpọ mọ si Mista Latin ṣapejuwe Baba Lẹgba, o ni Baba awọn oṣere ni tawọn ti n wo tipẹtipẹ ko to di pe awọn naa ni oore-ọfẹ lati bawọn ṣiṣẹ pọ.
O ni o ti le ni ọgbọn ọdun toun ti mọ wọn, ti wọn ko eeyan mọra, o wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ wọẹ si afẹfẹ rere. Awọn agba oṣere to tun wa nibẹ lọjọ naa ni Alagba Olowomojuọrẹ iyẹn Baba Gebu, Oodua, Owolabi Ajasa, gomina ẹgbẹ TAMPAN nipinlẹ Ogun, Gẹngẹnrẹn toun jẹ gomina ẹgbẹ ti ANTP, atawọn oloye wọn gbogbo.
No comments:
Post a Comment