Ẹgbẹ oṣelu PDP, tipinlẹ Ogun, ti sọ pe o jẹ ohun iyalẹnu ati nnkan ti ko dara to bi wọn ṣe ni Gomina Dapọ Abiọdun, ṣe fi atilẹyin ẹ han lori bijọba apapọ ṣe safikun owo ina, owo ori, owo ti banki yọ ati owo epo pẹtiroolu gẹgẹ bi eyi to buru ju, to si lodi si ifẹ araalu.
Wọn sọrọ yii ninu atẹjade tẹgbẹ oṣelu ọhun fi sita loni-in, eyi ti Ọgbẹni Bankọle Akinloye JP, fọwọ si lorukọ alaga ẹgbẹ naa, Sikirulai Ogundele. Wọn ni ko yẹ ki Gomina le tete sare ṣatilẹyin fun iru nnkan bẹẹ ati pe bigba ti ọkunrin naa ko nifẹẹ awọn araalu ẹ.
Atẹjade naa tun sọ pe lakọkọ naa ki i ṣe iru akoko ti nnkan ko lọ bo ṣe n lọ, tọrọ aje n fa sẹyin lo yẹ ki ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari gbe iru igbesẹ ti wọn gbe naa.
Ẹgbẹ oṣelu PDP tun ṣalaye pe fifọwọsi afikun awọn nnkan wọnyi ti ṣapejuwe iru ijọba to wa lode yii, ti wọn ṣeleri nigba ti wọn fẹẹ ṣejọba, pẹlu awọn nnkan rere ṣugbọn ti wọn ko muṣẹ lati ọdun marun un ti wọn ti gbakoso.
O ni awọn gẹgẹ bi oloṣelu, iru fifọwọsi igbesẹ yii o jẹ eyi to tako erongba awọn araalu, ati pe oun tawọn duro lori ni pe iṣejọba ẹgbẹ oṣelu APC ko mu anfaani rere kan jade, bi ko se inira nla.
Bankọle wa sọ pe ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun lodi patapata si iwa ti Gomina Dapọ Abiọdun hu, ẹni tawọn ro pe o yẹ ko kọkọ gbe igbesẹ lati tako.
O ni eyi ko le jẹ ko dun awọn mọ lori ijakulẹ ijọba Dapọ Abiọdun lati fawọn eeyan lẹbun ounjẹ lakooko korona fairọọsi, ti wọn ko si fawọn araalu ni nnkan to tọ si wọn.
PDP ipinlẹ Ogun tun ṣalaye pe bi wọn ṣe ṣafikun owo epo pẹtiroolu atawọn nnkan mii in ko dara to iwa ọdaju lawọn si tun kaa si, ko si wa dara to ki ẹni kan wa jade lati tẹwọgba, o buru jai.
Wọn wa lo akoko naa lati rọ awọn araalu lati lodi safikun gbogbo nnkan tijọba kede yii paapaa julọ owo epo, ki wọn si dide tako ẹnikẹni to ba fọwọ si iru igbesẹ bẹẹ.
No comments:
Post a Comment