Awọn alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nilẹ Yoruba yari mọ Gomina Makinde lọwọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 10 September 2020

Awọn alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nilẹ Yoruba yari mọ Gomina Makinde lọwọ

 


 

Awọn alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nilẹ Yoruba ti yari mọ Gomina Seyi Makinde, tipinlẹ Ọyọ lọwọ lori ihuwasi ẹ lori ibo ẹkun ti ẹgbẹ ọhun to fẹẹ waye, ti wọn si tun ti fi atilẹyin wọn han si Dokita Eddy Ọlafẹsọ, gẹgẹ bi alaga tuntun ti wọn yoo dibo yan.

 

Eyi waye ninu atẹjade abọ ipade ẹgbẹ naa, ti Onimọ-ẹrọ Deji Doherty, to jẹ alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Eko, ka lorukọ awọn alaga yooku nibi ipade wọn to ṣẹlẹ niluu Abẹokuta, lọjọruu, Wẹsidee.

 

Awọn alaga yooku to wa nibẹ ni Sikirullahi Ogundele, lati ipinlẹ Ogun, to jẹ olugbalejo, Sunday Ọlatunde Akanfẹ, toun jẹ tipinlẹ Ọsun ati Bisi Kọlawọle, alaga PDP ni Ekiti.

 

Ninu atẹjade ti Doherty ka lo ti sọ pe ipo aṣaaju ti Gomina Ṣeyi Makinde, ninu ẹgbẹ ọhun ko fẹẹ ye awọn mọ ati pe awọn fẹẹ ko mọ pe gbogbo ipinlẹ lo ni aṣaaju nidii oṣelu, ti wọn si gbọdọ bọwọ fun un, ko si ipinlẹ kan to n ṣejọba ipinlẹ mii in.

 

O ni o si ti wa ninu akọsilẹ ati ipinnu pe bi wọn ṣe sagbekalẹ pinpin ipo ẹlẹkunjẹkun ẹgbẹ oṣelu ki i ṣe nnkan ti wọn le fọwọkan. O ni ohun tawọn duro le lori ni pe gbogbo aba ti le fẹẹ gbe wọle ni PDP ilẹ Yoruba, awọn ko nii gba wọle.

 

Dohery tun ṣalaye siwaju pe “ A lo anfaani yii lati jẹ kawọn oloye ẹgbẹ lapapọ mọ pe nnkan tawọn n fẹ ni pe ibo to fẹẹ waye yii gbọdọ lọ nirọwọ rọsẹ, ko si gbọdọ si itajẹsilẹ rara. A si ti ṣetan lati gba abajade ibo ọhun, bo ba ṣe waye.

 

 

Ọkunrin naa tun sọ pe ijọba Eddy Ọlafẹsọ, to ti wa nibẹ, to lo ọdun meji lati inu oṣu kọkanla, ọdun 2017 ni ki wọn fun laye lati pari saa akoko ẹ, ko si tẹsiwaju awọn iṣẹ rere to ti n ṣe ninu ẹgbẹ naa lọ.

 

O ni "A ko gba aṣaaju Kankan laye ti ko ba bọwọ fun ofin ijọba tiwa-n-tiwa. Gbogbo wa ni ẹtọ lati jẹ ki wọn maa mọ labẹ ofin. Ohun taa sọ ni pe ki wọn fun alaafia laye lati jọba ninu ẹgbẹ PDP, nilẹ Yoruba.

 

Ninu ọrọ Ọnarebu Ladi Adebutu, toun naa jẹ agba oṣelu ninu ẹgbẹ yii nipinlẹ Ogun, lo ti kọkọ dupẹ lọwọ Ọlọrun, bi wọn ṣe tun ṣe pada si ile ipade ẹgbẹ wọn yii lẹyin aimọye ọdun ti wọn fi wa ninu wahala.

 

O sọ pe pẹlu ipo ti wọn fawọn ninu ibo ẹkun ilẹ Yoruba PDP yii, lawọn faramọ toun ṣi ṣeleri pe pẹlu ida marun-din-laadọrun tawọn  ni nipinlẹ Ogun lawọn fi ṣatilẹyin fun Ọlafẹsọ lati di alaga.

 

Ṣugbọn Ayọ Fayọṣe, Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ekiti, ti wa fi oko ọrọ ranṣẹ si Gomina Ṣeyi Makinde pe oun ti ṣetan lati gbena oju wo ẹnikẹni to ba fẹẹ gba akoso PDP, tipinlẹ rẹ mọ oun lọwọ.

 

O ni bigba ti eeyan ba n kọja aye ẹ ni Makinde n hu lati maa da si ẹgbẹ oṣelu PDP abẹle tipinlẹ Ekiti, iru eyi to sọ pe o fẹẹ maa ṣe nilẹ Yoruba, o ni ẹṣin abomu lọkunrin naa fẹẹ maa gun.

 

O ni nnkan to yẹ ki ọkunrin naa maa ṣe gẹgẹ bi aṣaaju nilẹ Yoruba ni lati gba ki ipinlẹ maa ṣe akoso ara ẹ. O ni gbogbo igba loun yoo maa bọwọ fun nitori oun  nifẹẹ.

 

O wa ni ko wa yẹ ko jẹ pe o jẹ aṣaaju, ko wa lo maa ṣayọjuran sawọn ipinlẹ mi in, o ni ko bojumu

 Lara awọn to wa nibẹ lọjọ naa ni Oloye Bayo Dayọ to jẹ alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ, awọn oloye ẹgbẹ tuntun nipinlẹ Ogun fẹgbẹ oṣelu PDP, atawọn agbaagba ẹgbẹ, to fi mọ awọn aṣoju.

No comments:

Post a Comment

Pages