Wọn ti sin oku Baba Lẹgba agba oṣere onitiata - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 8 September 2020

Wọn ti sin oku Baba Lẹgba agba oṣere onitiata

 

Ni irọlẹ ọjọ Aje, Monde, ana, ni wọn si agba oṣere onitiata nni, Alaaji Kaṣimawo Yẹkinni Oyedele, tọpọ awọn ololufẹ ẹ mọ si Baba Lẹgba, nile ẹ to wa ni Itoku, niluu Abẹokuta.

Ọkunrin naa to jade laye lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ni wọn si ni ilana musulumi nibi tawọn ẹbi, ara ati ọrẹ, paapaa awọn ẹgbẹ oṣere tiata ti peju pesẹ lati bọwọ ikẹyin fun agba oṣere tiata ọhun.

Lẹyin ti wọn si Baba Lẹgba tan, ni awọn musulumi ṣe waasi, ti wọn si gbadura pe ki Ọlọrun tẹ baba naa safẹfẹ rere. Odu ni Alaaji Yẹkinni Oyedele lagbo oṣere tiata nigba to wa laye kii ṣe aimọ foloko.

Ọkan lara awọn agba oṣere ti wọn gbẹ kanga omi tawọn onitiata n mu lakooko yii ni. Latọdọ Oloogbe Akin Ogungbe ni ọkunrin naa ti bẹrẹ iṣẹ tiata nigba to kuro nibẹ lo darapọ mọ ẹgbẹ alawada lọdọ Oloogbe Mosses Ọlaiya, tọpọ mọ si Baba Sala.

Nigba to lo ọpọ ọdun lọdọ ọga ẹ yii, lo pada si Abẹokuta, to si n tẹsiwaju nidii iṣẹ ọhun ko to di pe ẹlẹmi gbaa. Ọkan lara awọn to fi ere ori itage bẹrẹ ni, ko si sibi ti ere ori itage yii ko tii gbe de.

 


Lẹyin naa ni wọn tun kopa ninu awọn ere ori redio, tẹlifiṣan ati Atọka, ko to di pe fiimu bẹrẹ si nii jade, nigba ti fiimu si ti bẹrẹ ni Baba Lẹgba ko ti gbẹyin, bakan naa nigba to di agbelewo, o tun kopa ti jọju ninu awọn fiimu yii.

Ohun to jẹ kawọn eeyan fi maa n kan sara si Baba Lẹgba nigba to wa laye ni pe pẹlu bi wahala ṣe bẹ silẹ ninu ẹgbẹ oṣere ANTP, tawọn kan yapa lati kuro nibẹ lọ da ẹgbẹ mii in silẹ.


 

Baba Lẹgba wa lara awọn agba ti ko fẹgbẹ naa silẹ, pẹlu gbogbo bawọn to yapa naa ṣe foju wọn ri mabo, ṣe lọkunrin naa yari pe oun ko le fẹgbẹ tawọn agba, ti wọn jẹ ọga oun bii Hubert Ogunde, Akin Ogungbe, Baba Sala atawọn mii in da silẹ lọ darapọ mọ ẹgbẹ mii in.

Ori ipinnu yii ni agba oṣere yii duro le lori titi ti ẹlẹmi yoo fi gba. Ọpọ awọn to si wa nibi isinku Baba Lẹgba ni wọn kan sara sii gẹgẹ bi akọni ẹda to fẹran ọmọde ati agba, to si tun ko eeyan mọra. 


 

Lara awọn oṣere to wa nibẹ ni Ọtunba Bọla Ogunlabi, tọpọ awọn eeyan mọ si Gẹngẹnrin, to jẹ gomina ẹgbẹ oṣere ANTP, nipinlẹ Ogun, to tun ṣoju Aarẹ ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Adewale Ẹlẹsọ nibi isinku ọhun, Ogbẹni Rasak Ọyadiran tọpọ mọ si Baroka, Owolabi Ajasa, toun jẹ gomina fẹgbẹ oṣere TAMPAN, Seyi Crown, Iya Ṣapọn, Ẹba, Bashir Sanni, Kafila Bada, Jare Ademiregun, Dele Ogunmuyiwa atawọn oṣere mii in.

 


Bawọn ANTP ṣe wa nibẹ lọjọ naa bẹẹ lawọn TAMPAN naa ko gbẹyin. Ọdun mejilelọgọrin ni Baba naa lo laye. Iyawo, ọmọ, ati ọmọ ọmọ lo fi silẹ saye lọ.   

 




No comments:

Post a Comment

Pages