Awọn araalu Abalabi ni Ewekoro sọ pe Biobaku Bakare Taofeek ki i ṣe ọba awọn. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 28 August 2020

Awọn araalu Abalabi ni Ewekoro sọ pe Biobaku Bakare Taofeek ki i ṣe ọba awọn.

 


Wahala nla kan lo ti bẹrẹ bayii niluu Abalabi nijọba ibilẹ Ewekoro, nipinlẹ Ogun, lori bi wọn ṣe nijọba ṣe fi Biobaku Bakare Taofeek jọba niluu naa, eyi tawọn araalu sọ pe inu awọn ko dun si ati pe ẹni naa ko tọ sipo ti wọn fi si naa.

 

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii la gbọ pe kọmissanna fọrọ ijọba ibilẹ atawọn eeyan ẹ  lo fi ọkunrin naa jọba, eyi taa gbọ pe awuyewuye ti wa lori ẹ, ko to di pe wọn joye ọhun,

 

Bawọn araalu ṣe n naka aleebu sijọba ipinlẹ Ogun lori igbesẹ ti wọn sọ pe o le da wahala silẹ yii bẹẹ naa ni wọn tun bu ẹnu atẹ lu Olowu tiluu Owu, Ọba Adegboyega Dosunmu lori bo ṣe fọkunrin naa jọba lọna aitọ.

 

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lati Abalabi ni wọn ti rọ Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun, lati ma ṣe fọwọ si bi ileeṣe to n ri si ọrọ oye jijẹ ṣe fọwọ si Biobaku Taofeek, gẹgẹ bi ọba ilu ọhun, nitori ti wọn sọ pe o lọwọ eeru ninu.

 

Idi abajọ ni pe ẹni ti wọn ni Olowu fa kalẹ yii kii ṣe ọmọ idile Aramokala ti ọba kan gẹgẹ bi liana ifọbajẹ, ati pe o ti to ọdun meji sẹyin ti wọn ti wa lẹnu ẹ.

 

Lẹta ọhun ti Ọmọọba Benjamin Oluwapẹlumi, to jẹ ọkan lara awọn ti baba wọn tijọba niluu naa fi sita lati Abalabi, ni wọn ti ṣalaye pe awọn ko mọ Biobaku Bakare Taofeek, tijọba fijọba yii nitori  nnkan tawọn mọ ni pe Gbagura  lo ti wa.

 

O ni nnkan tawọn idile Aromọkala fẹnu ko lori nibi ipade ti wọn ṣe lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun to kọja ni  agboole Aramokala pe  Ọmọọba Babatunde Akinwunmi Badejoko, lawọn faa kalẹ lati di ọba, ti gbogbo awọn si fọwọ si.

 

 

O ṣalaye pe lọjọ kọkanlelogun, oṣu karun-un, ọdun yii lawọn tun ṣafihan ọkunrin yii  nileeṣẹ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ lati fọwọ si pẹlu lẹta lati ọdọ lọya ẹbi wọn.

 

 

Ninu lẹta Joseph Tadema, to jẹ agbẹjọro lati ileesẹ agbẹjọro ti wọn kọ sileesẹ to n ri ọrọ oye jijẹ ti wọn ṣoju fun awọn igbimọ agba niluu Abalabi, n Ewekoro, lawọn naa ti sọ pe inu ipade to waye ninu oṣu kẹsan an ni wọn ti fa Badejoko kalẹ, eyi ti gbogbo idile atawọn   araalu wa nibẹ.

 

Nibẹ lo tun ti sọ pe alatako kan soso ti wọn ni fọrọ ọba ọhun niTaofik Biobaku Bakare Oshunrinde, to wa lati Gbagura, ti wọn lo jẹ  Loṣi  Gbagura.

Lọdun to kọja ni Taofeek Biobaku dije oye Balogun tiluu Gbagura pẹlu Oloye Yusuf Ewenjẹ, ẹni to wa nipo naa bayii.

    

Awọn araalu naa atawọn ẹbi tọrọ naa kan ti wa rọ Afọlabi Afuwapẹ, to jẹ kọmissanna fọrọ oye jijẹ lati fa sẹyin lori gbogbo igbesẹ ti wọn ti gbe nitori Taofik Biobaku Bakare Oshunrinade kii ṣe itẹwọgba awọn Abalabi.


 

 

No comments:

Post a Comment

Pages