Ọga agba fun ileeṣe alaabo So-Safe Corps nipinlẹ Ogun, Ṣọji Ganzallo, ti gboriyin fawọn eeyan ẹ to wa ni agbegbe Ọdẹda fawọn aṣeyọri ti wọn ti ṣe nipa eto abo fawọn ara agbegbe naa.
O sọrọ yii nibi ayẹyẹ agbekalẹ ẹkun tuntun fun ileeṣẹ naa
ti ẹka ijọba ibilẹ Ọdẹda ati fi fawọn ọmọọṣẹ alaabo naa ni igbega lati ipo kan
bọ si keji.
Ọga agba ajọ naa sọ pe ohun iwuri lawọn ọmọ to wa labẹ
yii ṣe, eyi si tumọ si pe wọn tun le ṣe ju bẹẹ lọ. O ni iṣẹ kekere kọ ni wọn ṣe
lori wahala tawọn Fulani ṣaaba maa n da silẹ lagbegbe ọhun, eyi to ni o ti n
walẹ diẹdiẹ
O ṣalaye pe gbogbo awọn oniwa ibi tọwọ ba tẹ lawọn eeyan
ohun yii maa n fa le awọn ọlọpaa lọwọ gẹgẹ bi ilana ati ofin tawọn n tẹle. O ni
ifilọlẹ tawọn ṣe lọjọ naa ki i ṣe pe o ṣẹṣẹ bẹrẹ, o ni ipinnu ẹ ti wa nilẹ tipẹtipẹ
pẹlu idaniloju pe laipẹ yii wọn yo kọ ọfiisi naa tan, fun iwulo ajọ alaabo ọhun.
O ni nnkan tawọn n ṣe ni lati jẹ ki eto abo sunmọ awọn
araalu pẹkipẹki, nitori bi Ọdẹda ṣe di ẹkun bayii, yoo tun fi iwa ọdaran wọlẹ,
o iwa ọdaran ko fi bẹẹ pọ bi ko ṣe tawọn Fulani, to fẹran jẹ oko.
O ni awọn iwa ọdaran yooku ko fi bẹẹ pọ ṣugbọn awọn ko le
maa woran lati jẹ ko gbilẹ. Ninu ọrọ Bọde Kusimọ, to jẹ ọga agba fun ti ajọ So-Safe
Corps ni ẹkun Ọdẹda, o dupẹ lọwọ Ọlọrun fun pe o jẹ kiru ọjọ oni ṣoju wọn.
O wa ṣeleri pe gbogbo akitiyan oun loun yoo sa lati rii
pe eto abo peleke si ni agbegbe ijọba ibilẹ Ọdeda. O ni awọn ko ni maa woran
lati gba awọn oniwabajẹ laaye lati fidi jokoo ni ayika awọn.
Nigba toun naa sọrọ, Alaaji Musibau Amọdu to jẹ igbakeji ọga
agba So Safe ni agbegbe ọhun lawọn ti setan lati fi tọkantọkan pese abo fawọn
araalu, nitori nnkan akọkọ to jẹ awọn logun julọ niyẹn.
Lẹyin eyi ni wọn fawọn mejidinlọgbọn ni igbega lati ipo
kan bọ si eekejI. Lara awọn to pejupesẹ nibẹ lọjọ naa ni awọn Baalẹ agbegbe
naa, aṣoju awọn ọlọpaa atawọn eeyan jakanjakan mii in.
No comments:
Post a Comment