Alaafia awọn ero taa n gbe lo jẹ wa logun- Yayiagbara alaga kẹkẹ Marwa,TORAN nipinlẹ Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 9 October 2020

Alaafia awọn ero taa n gbe lo jẹ wa logun- Yayiagbara alaga kẹkẹ Marwa,TORAN nipinlẹ Ogun

 

Ọmọọba Agunbiade Abdulwasil ni alaga fẹgbẹ awọn ọlọkada kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta tawọn kan tun pe ni kẹkẹ Marwa, nipinlẹ Ogun,loju ẹsẹ to ti depo naa lo ti bẹrẹ iṣẹ lati mu ayedẹrun fawọn ọmọ ẹgbẹ ẹ, laipẹ yii lo ba oniroyin wa sọrọ nipa kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta, atawọn aṣeyọri wọn.


Orukọ mi ni Ọmọọba Agunbiade AbdulWasil ti wọn mọ si Yayi Àgbàrá tawọn kan tun pe ni Yayi Agbára. Àtàgbárá ati agbára gẹgẹ bi mo ṣe maa n sọ ọkan naa ni. Emi ni alaga awọn olura ati oluwa kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta,taa n pe ni Kẹkẹ NAPEP tabi Marwa, iyẹn TORAN.

Ẹgbẹ yii jẹ eyi to wa ni ẹka, ẹka ki wọn to sọ ọ di ẹyọ kan.Ko to di pe o gba ominira lati di ẹyọ kan lati ile igbimọ aṣofin, ẹgbẹ bii mẹrin-un lo wa ti wọn ṣiṣẹ lọtọọtọ, ko to di pe ijọba paapọ di ẹyọ kan.

Awọn to ti jẹ alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ

Emi kọ ni alaga akọkọ ninu ẹgbẹ kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta yii, ẹni akọkọ ni ọga wa Alaaji Kamọrudeen Busari to jẹ alaga lẹyin ti jọba fi ontẹ ma ba iṣẹ lọ fun wa lọdun 2011 si 2015.

Ko to di pe ẹni ti mo gba ipo lọwọ ẹ, Alaaji Moruf  Ajani, tinagijẹ wọn jẹ ẹṣẹ Murphy, awọn lo wa nibẹ lati 2015 si 2019, ko to di pe Dapọ Abiọdun fagile ẹgbẹ awọn onimọto ati onikẹkẹ. Inu oṣu keji ọdun yii ni wọn gbẹsẹ kuro lori ofin naa.Ohun lo jẹ ki awa gbale, ọdun mẹrin lawa yoo fi ṣe e.

  Eko ni kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta ti bẹrẹ

Ni ipilẹ, bi ẹ ba wo bi NAPEP ṣe wọ ipinlẹ Ogun,Eko gan –an ni wọn ti wa, ko to di pe wọn de ipinlẹ yii. Igba yẹn ni wọn n pe ni kẹkẹ Marwa, lakooko ti Marwa ṣe gomina ipinlẹ Eko ni kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta de Nigeria, to si de si Eko.

Awọn ilu to sunmọ Eko, iwọnba lo n wọle nigba yẹn, awọn ibi to maa n de ni Agbara, Agbado, Ifọ, Sango awọn ilu to sunmọ Eko, awọn ibẹ mi kẹkẹ kọkọ n wọ.

Wọn ko ti gba ominira lati maa ṣiṣẹ,  gbogbo wa la mọ pe lai ti di ominira a o le ṣiṣẹ. O ni lati wa ọna ti yoo ma gba owo wọle, idi niyii taa fi wa labẹ ẹgbẹ onimọto tẹlẹ. Ki awọn aṣaaju wa to ṣiṣẹ kaa to da duro.

Ajọṣepọ to wa laaarin awa ati onimọto pẹlu ọlọkada nipinlẹ Ogun.

Adupẹ fun ijọba Gomina Dapọ Abiọdun, lẹnugba ti wọn de bẹ ti wọn gbẹsẹ kuro lori ofin ti wọn fi de wa, ti wọn si yanju ẹ, ẹ ẹ o ri pe mọto ni alaga meji, ọkada naa ni mẹta,tawa ọlọkada Marwa naa ni mẹta.

Nigba to ti ri bayii, la sọ pe a ko le jokoo, ki a maa sọrọ lọtọọtọ, to si jẹ pe abẹ ijọba kan  naa lati n sọrọ, lawa ko ara wa jọ,la fi sọ ara wa di ọkan, ẹni taa wa fi ṣe alaga awọn alaga ni Alaaji Titilayọ Akibu tinagijẹ n jẹ Efele, toun jẹ alaga roodu nipinlẹ Ogun.

 Ohun ni ko jẹ ki wahala wa mọ, ti irẹpọ fi wa laaarin wa, gbogbo ẹ lati mu kuro.

Ọsọọsẹ lawa oni kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta pin iṣẹ laarin wa.

Nipinlẹ Ogun awa kii ṣiṣẹ ojoojumọ, ọsọọsẹ la maa n pin, awa naa ni ẹgbẹ taa jọ n ṣe nnkankan naa, TULAR, ojoojumọ la n ṣiṣẹ, awọn ọjọ yẹn la fi n ba ijọba taja. Nnkan ta fi pin lọsọọsẹ ni pe gbogbo wa la fẹẹ fi taja fun ijọba.

Ọkada TURAN kii ṣe alatako wa

TURAN kii ṣe alatako wa rara, Ọgbẹni Azeez ni alaga ti wọn ọrẹ mi ni, awọn wa ni Ijẹbu Ode lọhun.

Ọna taa n gba daboobo awọn ero wa, gbogbo nnkan taa ba n ṣe letoleto tori wọn ni, nitori ọwọ wọn lati n gbowo.Alaafia wọn jẹ wa logun, talaafia wọn ba wa daadaa, a maa riṣẹ wa ṣe daadaa.

Ohun taa n ṣe ni pe a maa n jẹ kawọn to n wa kẹkẹ wa ni ilera to pe, ki wọn wa ni alaafia.  Wọn ko gbọdọ muti ti wọn ba n wa ọkọ, bi wọn ba wa ọkọ, wọn ko gbọdọ muti. Ki wọn ba le gbero wọn debi to yẹ ki wọn gbe wọn de.

Gbogbo awọn nnkan to le fa ironu fun wọn ti wọn ba n wa ọkada la maa n wọna lati ma jẹ ko waye. A si jẹ ki kẹkẹ wọn duro daadaa, ki wọn to gbe wọn sita.

Ko sibi ti ayederu tikẹẹti ko si

A fi ki Ọlọrun ṣaanu wa, ko ma sibi ti ayederu tikẹẹti ko si.a fi ẹni to ba sọ pe tiẹ yatọ lo ku, ko sibi ti iṣe ko si. Akọkọ ijiya fẹni to ba ṣe bẹẹ, nitori bigba teeyan ja ijọba lole ni.Ẹni taa ba mu, a kọkọ maa sọ pe a o mọ lọmọ ẹgbẹ wa. A o wa gbe lọ sile-ẹjọ, kijọba le fọwọ ofin muu.

 

 

 

Awọn ero lo kangun si wa

 

 

 

No comments:

Post a Comment

Pages