Ko si wahala mọ ninu ẹgbẹ awakọ NURTW nipinlẹ Ogun, a ti bẹrẹ iṣẹ bayii- Yaro - BO SE RI

Breaking

Saturday, 17 October 2020

Ko si wahala mọ ninu ẹgbẹ awakọ NURTW nipinlẹ Ogun, a ti bẹrẹ iṣẹ bayii- Yaro

 Alaaji Mustapha Ismael Adewale, tọpọ mọ si Yaro, alaga fẹgbẹ awọn awakọ NURTW nipinlẹ Ogun, ti sọ pe ko si wahala kankan mọ ninu ẹgbẹ naa ati pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹu.

Ọkunrin yii sọrọ yii lakooko to n bawọn oniroyin fọrọ jomitoro ọrọ nibi ipade ẹgbẹ wọn akọkọ, lẹyin ti wọn ti ṣi ọfiisi wọn ti wọn ti ti pa tẹlẹ, ni nnkan bi oṣu meloo kan sẹyin.

O lawọn dupẹ lọwọ Ọlọrun pe pẹlu gbogbo bi iji ṣe ja to, awọn dupẹ pe awọn tun pada si ọfiisi naa. O ni ninu oṣu kejila ni wahala naa ti bẹrẹ lẹyin tawọn dibo ninu ẹgbẹ wọn.

Yaro ni lẹyin ibo naa lawọn ti ko dun mọ ninu awọn lọ si kootu, pẹlu ẹ naa ni ijọba ipinlẹ Ogun, tun fofinde ẹgbẹ naa, nigbẹyin gbẹyin aṣẹ ile-ẹjọ awọn pada sipo naa. O wa dupẹ lọwọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa paapaa awọn agbaagba fun aduroti wọn.

O fikun ọrọ ẹ pe ọpọ awọn nnkan to wulo ni ọfiisi ẹgbẹ ọhun ni wọn ti ko lo, to si parọwa si awọn ti nnkan ẹgbẹ ba wa lọwọ ẹ lati tete daa pada ati pe awọn ti n gbe igbesẹ lati rii pe awọn gba awọn nnkan naa pada.

Bẹẹ ni Yaro tun fikun ọrọ ẹ pe iṣẹ akọkọ to wa niwaju wọn ni lati rii pe awọn pada di ọkan ninu ẹgbẹ to ko si ni si wahala mọ ati pe gbogbo awọn to le yanju ẹ lawọn ti n ke si.

O wa tun lo akoko naa lati dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Ogun fawọn akitiyan wọn lati ri pe alaafia jọba laaarin ẹgbẹ awakọ nipinlẹ Ogun.

 

 

 

 

 

No comments:

Post a comment

Pages