Lalẹ, ana, ni Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun, fofin de awọn ọlọkada lati ma ṣe ṣiṣẹ fọjọ, nitori iwọde lati fopin si awọn ọlọpaa kogbregbe, iyẹn EndSars, to n lọ lọwọ, ṣugbọn iyalẹnu ni pe awọn ọlọkada naa ko gbọrọ sijọba lẹnu nitori titi di akoko yii ni wọn ṣi n ba iṣẹ wọn lọ nigboro.
Nibi ipade
ti Gomina bawọn oniroyin ṣe ọhun lo tun ti paṣẹ pe ki wọn ti gbogbo ileewe pa
lati oni Ọjọruu, Wẹsidee titi di ọjọ Aje Monde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii.
O sọ pe
gbogbo ọna nijọba n wa lati rii pe iwọde tawọn ọdọ n ṣe ko mu itajẹsilẹ dani
ṣugbọn bi nnkan ṣe n lọ yii bawọn ko ba tete gbe igbesẹ yoo di nnkan tagbara ko
ni ka mọ.
O tun
ṣalaye pe ko to di pe oun bawọn oniroyin sọrọ loun ti ṣe ipade pọ pẹlu awọn
eleto abo nipinlẹ yii nibi tawọn ti jọ fori kori lati wa ọna abayọ. O ni awọn ko fẹẹ ki konile-o-gbele waye idi
niyii tawọn fi kọkọ gbe awọn igbesẹ naa.
Dapọ
Abiọdun tun ṣalaye pe oun fẹẹ kawọn akẹkọọ forikori lati yan aṣaaju ki wọn jọ
jokoo papọ sọrọ lati wa ọna abayọ, nitori awọn ko fẹẹ wahala ṣugbọn iroyin
tawọn n gbọ ati bi wọn ṣe pa ẹṣọ aṣọbode lana-an mu ibanujẹ ọkan wa.
O ni ijọba
yoo wo igbesẹ naa laaarin wakati mẹrinlelogun, ki wọn to gbe igbesẹ mii in.
Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe awọn ọlọkada ko pa ofin naa mọ, ti wọn si sọọ di ko kan
mi.
No comments:
Post a Comment