|
Ọrọ yii jade ninu
ipade oniroyin to waye, nibi ti Onimọ-ẹrọ, Ade Akinsanya, to jẹ kọmiṣanna fọrọ
iṣẹ nipinlẹ naa ti sọ nipa igbesẹ tuntun ọhun, eyi toun ati akẹgbẹ Alaaji Waheed Oduṣile, jọ ṣe papọ.
Ninu ọrọ naa ni kọmiṣanna fọrọ iṣẹ ti mẹnuba awọn ibi ti
iṣẹ akanṣe naa yoo de, awọn ọna naa ni Ijẹbu Ode-Ẹpẹ si Ṣagamu-Ọrẹ
Interchange Flyover ni agbegbe Ijẹbu-Ode/Odogbolu. Ọna ọja Ilishan ni agbegbe
Ikenne. Ọna Itori si-ile epo ni Ewekoro.
Awọn ọna ti Kọmiṣanna tun mẹnuba ni Jọju ni Ado-Odo Ọta, Olomore si Sanni
nijọba ibilẹ Abeokuta North.Ọna Ṣagamu si Ipẹru ni agbegbe Ṣagamu/Ikẹnnẹ. Ọna Ipẹru
si Roundabout-Ode ni agbegbe Ikenne. Ọna Agọ- Iwoye si Oru-Ijẹbu Igbo ni
Ijebu North..
Bakan naa lo tun sọ pe akanṣẹ iṣẹ ọna yoo tun de ba Ṣomorin-Kemta, ni Idi-Aba lagbegbe
Ọdẹda. Ọna Ilashe-Koko-Alari lagbegbe Ipokia. Ọna Orile Oko ni Rẹmọ North ati Ọna Obafemi Awolowo, Mada si Takete in Rẹmọ
North.
O ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe iṣẹ
ti duro lawọn ibi kan nitori wahala iwọde to n lọ lọwọ nigboro, nitori bo ṣe ni
wọn doju ija kọ awọn oṣiṣẹ ọhun lẹnu iṣẹ, ṣugbọn o ṣe ileri pe laipẹ ni wọn yoo
pada sẹnu iṣẹ ti wọn ba ti yanju iwọde ọhun.
Onimọ ẹrọ Akin Akinsanya, tun
fikun ọrọ ẹ pe o ni apero si n lọ lọwọ laaarin ijọba ipinlẹ Ogun ati ijọba apapọ
lati gbakoso awọn akanṣe ọna ni Eko si Abẹokuta-si Sango-Ọta si Atan -Owode si Idiroko, ki iṣoro to n
dojukọ awọn eeyan to n gba agbegbe naa le dinku.
Ninu ọrọ ti Kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ Ogun, Alaaji
Waheed Oduṣile, nibi ipade oniroyin naa lo ti sọ di mimọ pe ijọba fọwọ si awọn
akanṣe ọna ni latari bawọn araalu ṣe bẹbẹ fun un.
O sọ pe inu ijọba ko
dun sipo tawọn ipo ti ọna naa wa lakooko yii atawọn nnkan ti awọn eeyan n
dojukọ lori ọna yii, o wa ṣeleri pe ọpọ awọn agbegbe ni yoo jẹri si awọn
idagbasoke tijọba yii ni lọkan fun wọn.
Bẹẹ lo tun fi kun ọrọ
ẹ pẹlu idaniloju fawọn eeyan agbegbe Ọta, Akute, Alagbole pe ayọ ni yoo gbẹyin
fun wọn lẹyin tijọba ba pari awọn akanṣe iṣẹ ọna yii. Ti wọn yoo si jẹ anfaani
mudunmudun ijọba awarawa.
A o ranti pe lẹnu ọjọ
meloo kan kan sẹyin nijọba ipinlẹ Ogun fọwọ si awọn akanṣe ọna tuntun kan,
awọn naa ni ọna Akute si Denro si Ishasi lagbegbe Ifọ. Ọna Oluṣẹgun Ọsọba Toyin Street ni Ifọ ati
oju ọna marosẹ Mọlipa ni Ijẹbu Ode.
No comments:
Post a Comment